ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp21 No. 1 ojú ìwé 14-15
  • Bí Àdúrà Ṣe Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Àdúrà Ṣe Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àǹfààní Tó O Máa Rí Nínú Àdúrà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Àǹfààní Pàtàkì Ni Àdúrà Jẹ́
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Máa Gbàdúrà Kó O Lè Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
wp21 No. 1 ojú ìwé 14-15

Bí Àdúrà Ṣe Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́

Nígbà tí Pamela ń ṣàìsàn tó le, ó lọ wá ìtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn dókítà tó mọṣẹ́ dáadáa. Àmọ́, ó tún gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún òun lágbára láti fara da ìṣòro náà. Ṣé àdúrà ràn án lọ́wọ́?

Pamela sọ pé: “Nígbà tí mò ń gba ìtọ́jú nítorí àrùn jẹjẹrẹ tí mo ní, ẹ̀rù máa ń bà mí gan-an. Àmọ́ nígbà tí mo gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run, ọkàn mi balẹ̀, mo wá ní okun láti fara dà á. Mo ṣì máa ń ní ìrora tó pọ̀ gan-an, àmọ́ àdúrà ràn mí lọ́wọ́ láti mọ́kàn le. Nígbà táwọn èèyàn bá bi mí pé báwo lára ẹ ṣe rí? Màá ní, ‘Ara mi ò yá, ṣùgbọ́n mo láyọ̀!’”

Àmọ́ ṣá o, kò dìgbà tẹ̀mí èèyàn bá wà nínú ewu kéèyàn tó máa gbàdúrà. Gbogbo wa la ní ìṣòro tá à ń bá yí, bóyá ó kéré ni o tàbí ó tóbi, a sì ń fẹ́ ìrànwọ́ láti borí wọn. Ṣé àdúrà lè ràn wá lọ́wọ́?

Bíbélì sọ pé: “Ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà, yóò sì gbé ọ ró. Kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.” (Sáàmù 55:22) Ẹ ò rí i pé ìyẹn tuni nínú gan-an! Báwo ni àdúrà ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Tó o bá gbàdúrà sí Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́, ó máa fún ẹ ní ohun tó o nílò láti borí àwọn ìṣòro ẹ.​—Wo àpótí náà, “Àǹfààní Tó O Máa Rí Nínú Àdúrà.”

Àǹfààní Tó O Máa Rí Nínú Àdúrà

Ìbàlẹ̀ ọkàn

Ọkùnrin oníṣòwò tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ yẹn ń rẹ́rìn-ín, ọkàn ẹ sì balẹ̀ bó ṣe ń rìn lọ.

“Ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín àti agbára ìrònú yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Tó o bá sọ gbogbo ìdààmú ọkàn rẹ fún Ọlọ́run, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ọkàn rẹ lè balẹ̀ kó o sì lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.

Ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Obìnrin tó ń ka àdúrà látinú ìwé tẹ́lẹ̀ wà nínú ilé rẹ̀, ó ń ka Bíbélì.

“Tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì máa fún un, torí ó lawọ́ sí gbogbo èèyàn, kì í sì í pẹ̀gàn tó bá ń fúnni.” (Jémíìsì 1:5) Nígbà míì tí ìdààmú bá báni, ó lè mú kéèyàn ṣe ìpinnu tí kò dáa. Tó o bá béèrè ọgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ó máa rán ẹ létí àwọn ìlànà inú Bíbélì tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Agbára àti ìtùnú

Tọkọtaya tó wà nílé ìwòsàn tẹ́lẹ̀ jọ ń rìn nínú ọgbà ìtura kan. Ọkùnrin yẹn rọra di ìyàwó rẹ̀ mú bí ìyàwó rẹ̀ ṣe ń fi ọ̀pá rìn.

“Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.” (Fílípì 4:13) Torí pé Jèhófà Ọlọ́run ló lágbára jù láyé àtọ̀run, ó lè fún ẹ lágbára láti borí àwọn ìṣòro tàbí kó fún ẹ lókun kó o lè fara da àdánwò. (Àìsáyà 40:29) Bíbélì tún pe Jèhófà ní “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” Ó máa ń tù wá nínú “nínú gbogbo àdánwò wa.”​—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÀDÚRÀ SÚ Ẹ

Ohun tó dájú ni pé Jèhófà ò ní fipá mú ẹ láti gbàdúrà sí òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń fìfẹ́ rọ̀ ẹ́ pé kó o gbàdúrà sí òun. (Jeremáyà 29:11, 12) Àmọ́ tó o bá ti rò nígbà kan rí pé Ọlọ́run kò dáhùn àdúrà rẹ ńkọ́? Má sọ̀rètí nù. Òbí kan lè má fún ọmọ ẹ ní ohun tó fẹ́ gangan, ó sì lè má jẹ́ ìgbà tí ọmọ náà retí ló máa fún un, àmọ́ ìyẹn ò fi hàn pé òbí náà ò nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹ̀. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni òbí náà ní ohun tó dáa jù tó fẹ́ ṣe fún ọmọ yẹn. Àmọ́, ohun tó dájú ni pé àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́.

Jèhófà Ọlọ́run ni òbí wa àgbà tó nífẹ̀ẹ́ wa jù lọ, ó sì fẹ́ ran ìwọ náà lọ́wọ́. Tó o bá fara balẹ̀ wo àwọn ìlànà inú Bíbélì tá a ti sọ̀rọ̀ nípa wọn, tó o sì sapá gan-an láti lò wọ́n, Ọlọ́run máa dáhùn àwọn àdúrà rẹ lọ́nà tó dáa jù lọ!​—Sáàmù 34:15; Mátíù 7:7-11.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́