ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w18 January ojú ìwé 32
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Àwọn Amerind Ìgbàanì Kan
    Jí!—1996
  • Wò ó! Ìránṣẹ́ Tí Jèhófà Tẹ́wọ́ Gbà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Òfin Jèhófà Pé”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • “Àyànfẹ́ Mi, Ẹni Tí Ọkàn Mi Tẹ́wọ́ Gbà!”
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
w18 January ojú ìwé 32

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ṣé lóòótọ́ ni wọ́n máa ń fi àwọn ìlànà inú Òfin Mósè yanjú èdèkòyédè ní Ísírẹ́lì àtijọ́?

BẸ́Ẹ̀ NI, wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ láwọn ìgbà míì. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Diutarónómì 24:​14, 15 sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lu lébìrà tí a gbà sí iṣẹ́, tí ó wà nínú ìdààmú, tí ó sì jẹ́ òtòṣì, ní jìbìtì, yálà lára àwọn arákùnrin rẹ tàbí lára àwọn àtìpó rẹ tí wọ́n wà ní ilẹ̀ rẹ . . . kí ó má bàa ké pe Jèhófà sí ọ, yóò sì di ẹ̀ṣẹ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ.”

Àfọ́kù ìkòkò

Àfọ́kù ìkòkò tí wọ́n kọ ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ agbaṣẹ́ṣe náà sí

Wọ́n rí àkọsílẹ̀ ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ tó fara jọ èyí nítòsí ìlú Áṣídódì, ó sì ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún keje Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ agbaṣẹ́ṣe kan tí wọ́n gbà sóko àmọ́ tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé kò kó gbogbo nǹkan tó kórè ránṣẹ́ ló wà nínú àkọsílẹ̀ náà. Ohun tí wọ́n kọ sára àfọ́kù ìkòkò kan ni pé: “Lẹ́yìn tí ìránṣẹ́ rẹ [ẹni tó ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀] ti kórè tán lọ́jọ́ mélòó kan sẹ́yìn, Hoshayahu ọmọkùnrin Shobay wá, ó sì mú ẹ̀wù ìránṣẹ́ rẹ lọ. . . . Gbogbo àwọn tá a jọ kórè nínú oòrùn lọ́jọ́ yẹn lè jẹ́rìí . . . pé òótọ́ ni mo sọ. Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí. . . . Mo bẹ̀ ọ́ gómìnà, ṣàánú ìránṣẹ́ rẹ, kódà bí kò bá tiẹ̀ jẹ́ ojúṣe rẹ láti bá ìránṣẹ́ rẹ gba ẹ̀wù rẹ̀ pa dà! Má ṣe dákẹ́ torí ìránṣẹ́ rẹ kò ní ẹ̀wù lọ́rùn.”

Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Simon Schama sọ pé: “Kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa bí agbaṣẹ́ṣe yẹn ṣe fẹ́ gba ẹ̀wù rẹ̀ pa dà nìkan la rí nínú àkọsílẹ̀ yẹn, ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé onítọ̀hún mọ̀ nípa Òfin Mósè, pàápàá àwọn òfin tó wà nínú ìwé Léfítíkù àti Diutarónómì tó sọ pé kí ẹnikẹ́ni má ṣe ni àwọn tálákà lára.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́