Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Àwọn Amerind Ìgbàanì Kan
IBI yòówù kí o lọ láyé, ìwọ yóò rí i pé ibì kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn nǹkan ìṣẹ́ ọnà ìṣẹ̀m̀báyé tirẹ̀. A lè rí àwọn àwòrán, ère gbígbẹ́, igi gbígbẹ́, iṣẹ́ ìkòkò mímọ, tàbí àwọn nǹkan mìíràn ní ìsọ̀ tí a ti ń ta àwọn nǹkan ẹ̀bùn àti àwọn ìsọ̀ tí a ti ń ta àwọn nǹkan iyebíye. Ìwọ ha ti ra èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí láti fi ṣe ilé rẹ lọ́ṣọ̀ọ́ rí bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èé ṣe tí o kò fi ṣàyẹ̀wò, kí ó lè rí ibi tí wọ́n ti ń ṣe nǹkan náà gan-an. Má ṣe jẹ́ kí ẹnú yà ọ́ bí o bá rí i pé orílẹ̀-èdè míràn ni wọ́n ti ṣe é.
Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, àwọn oníṣẹ́ ọnà ti máa ń fín orúkọ wọn sídìí ohun tí wọ́n bá ṣe láti fi ẹni tí ó ṣe é hàn. Bí ó ti wù kí ó rí, lónìí, ó ṣeé ṣe kí o rí ìwé pélébé tí a lẹ̀ mọ́ ara rẹ̀, tàbí orúkọ tí a tẹ̀ mọ́ ọn lára, èyí tí ń fi hàn pé, ẹ̀rọ ni a fi ṣe nǹkan náà, kì í ṣe ọwọ́ ni a fi ṣe é. Àwọn àdàmọ̀dì tí a fi ẹ̀rọ ṣe yìí ti wá ń di èyí tí ó gbajúmọ̀ sí i, àwọn nǹkan iṣẹ́ ọnà tí wọ́n sì jẹ́ àfọwọ́ṣe ṣòro láti rí. Bí ó ti wù kí ó rí, ǹjẹ́ a ṣì lè rí àwọn ti ìṣẹ̀m̀báyé, tí à ń ṣe ní àwọn àdúgbò kan bí?
Ṣíṣèbẹ̀wò sí Agbègbè Àdágbé Àwọn Amerind
Nígbà tí a lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ wa bíi mélòó kan tí wọ́n jẹ́ Amerind, tí wọ́n ṣì ń ṣe iṣẹ́ ọnà ìṣẹ̀m̀báyé wọn lọ síbẹ̀, a ṣàwárí pé a lè rí i dáadáa. Wọ́n jẹ́ ara ẹ̀yà àwọn Amerind tí a mọ̀ sí Santa Clara Pueblo, tí a mọ̀ ní pàtàkì mọ iṣẹ́ mímọ ìkòkò dúdú dídán gbinrin—ọ̀kan lára iṣẹ́ ìkòkò mímọ tí ó dára jù lọ lágbàáyé. Àwọn nǹkan ọnà tiwọn yàtọ̀ pátápátá sí àwọn nǹkan tí à ń fi ẹ̀rọ ṣe, tí a máa ń rí ní ọ̀pọ̀ àwọn ilé ìtajà ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn United States.
Àwọn ọ̀rẹ́ wa, Joe àti Anita, ti ń mọ ìkòkò ìṣẹ̀m̀báyé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Anita bẹ̀rẹ̀ ìkòkò mímọ pẹ̀lú ìyá rẹ̀ nígbà tí ó ṣì wà ní ọmọ ọdún mẹ́fà. Ọ̀kan lára àwọn ìkòkò tí Anita mọ wà ní Ẹ̀ka Ìtọ́jú Nǹkan Òníyebíye ti àjọ Smithsonian tí ó wà ní Washington, D.C., níbi tí wọ́n ti ń pàtẹ àwọn Iṣẹ́ Ọnà Àwọn Amerind.
Ìgbà tí Joe àti Anita ń múra láti bẹ̀rẹ̀ mímọ ọ̀wọ́ ìkòkò tuntun kan gan-an gẹ́lẹ́ ni a dé ibẹ̀. Nítorí náà, a lè rí i fúnra wa bí wọ́n ṣe ń ṣe é nísinsìnyí. Àwa fúnra wa náà ti mọ ìkòkò rí. Ṣùgbọ́n ọ̀nà ti òde òní ni a lò, pẹ̀lú ìkòkò kan tí a gbé tẹ́lẹ̀, amọ̀ tí a gún kúnná, àti ààrò. Ohun tí a fẹ́ wò nísinsìnyí jẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe é ní ìgbàanì, èyí tí wọ́n tàtaré láti ìran kan sí ìran mìíràn. Kò sí ohun tí ó jọ ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní nínú ọ̀nà yìí. Gbogbo rẹ̀ ni wọn ń ṣe láti ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀.
Kíkó Àwọn Èròjà Jọ
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Joe àti Anita yóò kó àwọn èròjà jọ. Gbogbo wá jìjọ gbé ọkọ̀ kékeré akẹ́rù wọn lọ sí ibi òkè kan níbi tí wọ́n ti ń rí amọ̀. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ní agbègbè àdágbé náà ló wà, kìkì àwọn ara ẹ̀yà náà, tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 2,400 ní Santa Clara Pueblo nìkan ló lè bu amọ̀ yìí lò. Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn máa ń lo ọ̀nà ìmọ̀kòkò ìṣẹ̀m̀báyé irú èyí tí wọ́n ń mọ ní nǹkan bí àwọn ọdún 1500. Bí a ṣe dé ibi òkè náà, Joe gbé jígà rẹ̀, ó sì dorí kọ ihò àpáta tí amọ̀ wà.
Ihò àpáta náà là lọ tóóró ní ìsàlẹ̀ òkè náà. Ó di pé kí Joe fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ kí ó sì máa bu amọ̀ jáde láti inú ihò àpáta náà, ó ń bù ìṣù amọ̀ tí kò tóbi ju bíríkì lọ. Èyí léwu, nítorí pé bí ènìyàn bá ti ń jinlẹ̀ lọ tó, bẹ́ẹ̀ ní ìṣeéṣe kí òkè ya lulẹ̀ ti ga tó. Nígbà tí Joe ti parí bíbu amọ̀ tí ó tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí ojúlówó tí ó tó nǹkan bí 60 sí 70 kìlógíràámù, a gbéra láti máa lọ. Ṣùgbọ́n, n kò lè mú un mọ́ra mọ́ débi tí mo fi béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ìdí tí kò fi bu amọ̀ tí ó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, kí ó má baà tún máa padà wá mọ́. Anita sọ fún wa pé: “Àwọn Amerind kì í ṣe nǹkan tiwọn bẹ́ẹ̀ yẹn.” Ohun tí wọ́n bá nílò lẹ́ẹ̀kan ni wọ́n máa ń mú nínú ilẹ̀. Ènìyàn lè fi ọ̀pọ̀ amọ̀ ṣòfò bí ènìyàn bá kó o sílẹ̀ kí ó máa ráre títí tí yóò fi gan.
Lẹ́yìn ìyẹn, ó di pé kí a gba ibi òkè míràn lọ láti wá yanrìn funfun. Èyí rọrùn ju ti àkọ́kọ́ lọ—kò ju kí ènìyàn kàn wa yanrìn korobá kan tàbí méjì lọ. Lẹ́yìn ìyẹn ni a darí sílé.
Bí Wọ́n Ṣe Ń Ṣe É
Wọn yóò kọ́kọ́ rẹ amọ̀ náà sínú omi fún ọjọ́ bíi mélòó kan. Lẹ́yìn náà ni wọn yóò jọ̀ ọ́ lẹ́ẹ̀mẹta tàbí lẹ́ẹ̀mẹ́ẹ̀rin. Wọn yóò tún jọ yanrìn náà nígbà bíi mélòó kan. Lẹ́yìn ìyẹn, Joe yóò ro méjèèjì pa pọ̀ ní ìwọ̀n tí ó ṣe rẹ́gí gan-an. Kì í ṣe pé yóò wọn amọ̀ tàbí yanrìn náà. Ìrírí ló jà jù. Yanrìn tí ó tó ní láti wà nínú amọ̀ náà, kí ìkòkò náà má baà kẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń sun ún. Tí yanrìn náà bá pọ̀ jù tàbí tí ó bá kéré jù, ìkòkò náà yóò sán tàbí kí ó fọ́. Anita sọ fún wa pé nígbà tí òún kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkòkò mímọ fúnra òun, òun yóò gbé amọ̀ náà lọ sọ́dọ̀ ìyá òun kí ìyá òun baà lè fọwọ́ kàn án, kí ó sì sọ fún òun bí yanrìn inú rẹ̀ bá tó. Kò pẹ́ tí òun náà fúnra òun fi kọ́ láti mọ̀ bí ó bá tó.
Joe lo àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ láti fi tẹ amọ̀ àti yanrìn náà pọ̀ títí tí ó fí rí i pé ó ti kúnná tó. Nísinsinyí, wọ́n ti ṣe tán láti mọ ìkòkò náà. Wọn kò ní lo ìkòkò míràn fi pilẹ̀ rẹ̀. Ọwọ́ ni wọ́n fi ń ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan, ọ̀kan kò sì pa pọ̀ mọ́kan. Anita máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí láti fi mọ ìkòkò rẹ̀ kí ó tó gbé e sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan láti gbẹ. Tí ó bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ tán, tí ó sì ti le díẹ̀ tó ohun tí wọ́n lè sọ pé ó le bí awọ, wọ́n lè tẹ àwọn bátànì tàbí ìlà sí i lára tàbí kí wọ́n fọwọ́ fín in sí i lára. Lẹ́yìn náà ni wọn yóò jẹ́ kí ó gbẹ pátápátá, èyí tí ó lè gbà tó ọ̀sẹ̀ kan, ó sinmi lórí bí ojú ọjọ́ bá ti lọ́rinrin tó. Ó ku kí wọ́n wá ha ara rẹ̀. Èyí máa ń dán amọ̀ náà, ó sì máa ń jẹ́ kí dídán ara ìkòkò náà rọrùn.
Ọwọ́ ni wọ́n máa ń fi ṣe iṣẹ́ dídán ara ìkòkò náà, pẹ̀lú òkúta bọ̀rọ́bọ̀rọ́ kan tí wọ́n mú nínú odò. Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe é dáadáa. Bí wọ́n bá dán an jù tàbí tí wọn kò bá dán an tó, ìkòkò náà kò ní máa dán lẹ́yìn tí wọ́n bá sun ún tán. Wọn kì í kùn ún. Iṣẹ́ dídán ara rẹ̀ ló máa ń jẹ́ kí ó dán bí ó ṣe máa ń dán bí eyín erin.
Iṣẹ́ Ìkòkò Sísun Tí Ó Ṣàrà Ọ̀tọ̀
Ó wá di orí ìgbésẹ̀ tí ó gbẹ̀yìn: sísun ìkòkò náà. Láti lè ṣe eléyìí, wọn yóò dá iná kan sí àgbàlá wọn. Wọn kì í lo ààrò níhìn-ín! Ohun tí wọ́n fi ń ṣe ààrò ni àwọn ẹ̀là igi tí wọ́n fi dólẹ̀, tí wọn sì kó àwọn igi sí i sórí àwọn tí ó wà lóòró náà, wọn yóò ṣe wọ́n bí ààrò kan tí ó ní ojú tí wọ́n lè máa ki ìkòkò náà wọlé. Nígbà tí ó bá yá, wọn yóò tanná ràn án. Nítorí ìrírí wọn, wọ́n mọ ìgbà tí iná náà bá ti gbóná tó láti ti ìkòkò náà bọ̀ ọ́.
Nígbà tí wọ́n bá sun ìkòkò náà, àwọ̀ tí ó máa ń ní gan-an ni pupa. Nígbà tí ó bá yá, ní àkókò tí ó yẹ gan-an, Joe yóò gbé ìgbésẹ̀ ṣíṣàrà ọ̀tọ̀ kan. Yóò da ìgbẹ́ ẹṣin sórí iná náà! Èyí ló máa ń sọ ìkòkò náà di dúdú. Nígbà tí afẹ́fẹ́ oxygen inú rẹ̀ bá ti dín kù, èròjà iron oxide pupa tí ó wà nínú amọ̀ náà yóò yí padà lọ́nà ìṣiṣẹ́ oníkẹ́míkà di èròjà iron oxide dúdú. Kí ènìyàn tilẹ̀ tóó sọ ọ́, tí o bá gbóòórùn rẹ̀ lásán, o lè sọ nígbàkígbà tí ẹnì kan bá ń sun ìkòkò dúdú ní agbègbè rẹ!
Ohun tí ń jáde láti inú gbogbo rẹ̀ jẹ́ ohun kan tí ènìyàn lè mú yangàn, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé sì máa ń fẹ́ràn ẹwà rẹ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, àwọn ohun èèlò ilé ni wọ́n máa ń lo irú ìkòkò bẹ́ẹ̀ fún, irú bíi fún kíkó onírúurú àwọn ohun èèlò ilé pa mọ́. Ní àwọn apá ibì kan ní àgbáyé, wọ́n ṣì ń lò ó lọ́nà yìí síbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwa yóò lo ìkòkò jíjojú ní gbèsè kan tí àwa rà láti fi ṣe ilé wa lọ́ṣọ̀ọ́, àti láti fi yangàn pé a ti ṣèbẹ̀wò sí Santa Clara Pueblo, níbi tí àwọn ènìyàn ṣì ti ń tẹ̀ lé àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn Amerind ìgbàanì síbẹ̀.—A kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Wọn ń wa àwọn ìṣù amọ̀ tí ó tóbi tó bíríkì jáde
Ọwọ́ ni wọ́n fi ń ṣu amọ̀ náà
Wọ́n ń sun ìkòkò náà nínú ààrò ìṣẹ̀m̀báyé kan