Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Ìrètí
ÀÌSÀN jẹjẹrẹ tó máa pa Joe dá a wólẹ̀. Kirsten tó jẹ́ ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mélòó kan tí wọ́n jókòó sétí bẹ́ẹ̀dì ń bá a sọ̀rọ̀. Kirsten yíjú sí ibi tí ọkọ rẹ̀ wà ó sì rí i pé omi ń dà lójú ẹ̀. Ó kọ́kọ́ rò pé ìrora ni. Ó ṣeé ṣe kó jẹ pé ara ló ń ro ó, àmọ́ ó sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé lọ́tẹ̀ yìí o, kì í ṣe ìrora yẹn ló ń pa òun nígbe.
Kirsten sọ pé: “Ní àkókò líle koko yìí, ńṣe làwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí wọ́n wá bá ọkọ mi kẹ́dùn rọ̀gbà yí i ká. Bákan náà, ó túbọ̀ wá dá a lójú ju ti ìgbàkígbà rí lọ báyìí pé ọwọ́ òun á tẹ ohun iyebíye tóun ti ń fojú sọ́nà fún, ó sì mọ̀ pé kò sẹ́ni tó lè gbà á mọ́ òun lọ́wọ́. Ó sọ pé ẹkún ayọ̀ lòun ń sun. Alẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an ló sì kú.”
Ìrètí wo ló fọkàn Joe balẹ̀ bí àìlera rẹ̀ ṣe ń gogò sí i? Ìlérí ìyè ayérayé tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe, nínú èyí tí èèyàn á ti máa gbé ní àlàáfíà ará nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé ni. (Sáàmù 37:10, 11, 29) Ìwé Ìṣípayá 21:3, 4 sọ pé: “Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé . . . Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ [tó fi mọ́ àwọn ìṣòro àkókò wa yìí] ti kọjá lọ.”
Àwọn Òkú Pàápàá Nírètí
Ní ti Joe, ọ̀nà tí ìrètí rẹ̀ yìí á gbà nímùúṣẹ ni pé ó máa jí dìde. Ohun tó ń tù ú nínú ni ìlérí tí Jésù ṣe pé “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí,” ìyẹn àwọn òkú tí wọ́n wà nínú ìrántí Ọlọ́run, ní wọ́n máa jí lójú oorun ikú. (Jòhánù 5:28, 29) Ṣé ikú ìbátan tàbí ikú ọ̀rẹ́ rẹ kan ń bà ọ́ nínú jẹ́? Fiyè dénú, ìrètí àjíǹde á mú kára ìwọ náà yá gágá. Lóòótọ́, ìrètí yìí ò ní kó má dùn wá wọra bí ẹni ara wa kan bá kú o. Jésù fúnra rẹ̀ “da omijé” lójú nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣàìsí. Àmọ́ ìrètí tá a ní ni kì í jẹ́ kó dùn wá jù.—Jòhánù 11:14, 34, 35; 1 Tẹsalóníkà 4:13.
Kirsten sọ pé: “Nígbà tí àrùn jẹjẹrẹ náà pàpà gbẹ̀mí Joe, ó ṣe mí bíi pé mi ò lè láyọ̀ gidi kan mọ́ láyé yìí. Ní báyìí pàápàá, lẹ́yìn ọdún mélòó kan tó ti kú, mo mọ̀ pé nǹkan ò lè rí bákan náà fún mi mọ́ nínú ètò nǹkan ìsinsìnyí. Kò sí ohun tó lè dípò Joe fún mi. Síbẹ̀, mo lè sọ tọkàntọkàn pé mo pàpà ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti ìtẹ́lọ́rùn.”
Ọ̀rọ̀ tí Kirsten sọ sílẹ̀ yìí ló rán wa létí pé nínú ètò ìsinsìnyí, ọjọ́ gbogbo ò lè máa dùn bí oyin. Ọjọ́ kíkan wà, ọjọ́ dídùn sì wà. Àwọn ìgbà míì sì wà tó yẹ ká banú jẹ́, tí kò ní bójú mu rárá pé ká yọ̀ ṣìnkìn. (Oníwàásù 3:1, 4; 7:2-4) Bákan náà, ìsoríkọ́ lè máa bá àwọn kan lára wa fà á. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì ń mú kí èyí rí bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀ náà, àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú Bíbélì máa ń fúnni ní ìtùnú ńláǹlà, ọgbọ́n tó ga jù lọ tá a lè rí nínú Bíbélì sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ọ̀pọ̀ ìṣòro tó lè mú kéèyàn máà láyọ̀. Ọlọ́run sọ pé: “Ní ti ẹni tí ń fetí sí mi, yóò máa gbé nínú ààbò, yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.”—Òwe 1:33.
Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ò fẹ́ kí aburú kankan ṣẹlẹ̀ sí wa. Ó fẹ́ ká máa láyọ̀, kì í ṣe ayọ̀ oréfèé o, ayọ̀ àtọkànwá tó jinlẹ̀ ni. Kì í sì í ṣe fún ìwọ̀nba ọdún díẹ̀, àmọ́ títí láé ni! Ìdí nìyẹn tí Ọmọ rẹ̀ fi sọ ọ̀rọ̀ tó máa ń fìgbà gbogbo jóòótọ́ yìí pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Bá a bá fi ohun tó sọ yìí sọ́kàn, a jẹ́ pé ọlọgbọ́n èèyàn ni wá.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ohun Mẹ́sàn-án Tó Lè Mú Kéèyàn Máa Láyọ̀
1. Kéèyàn jẹ́ kí ohun tẹ̀mí máa jẹ òun lọ́kàn.—Mátíù 5:3.
2. Kéèyàn máa ní ìtẹ́lọ́rùn, kó sì yẹra fún “ìfẹ́ owó.”—1 Tímótì 6:6-10.
3. Kéèyàn má sọ ìlépa ọrọ̀ di nǹkan bàbàrà.—2 Tímótì 3:1, 4.
4. Kéèyàn jẹ́ ọ̀làwọ́, kó sì máa ṣe ohun táá mú káwọn ẹlòmíì máa láyọ̀.—Ìṣe 20:35.
5. Kéèyàn máa dúpẹ́, kó sì máa ronú lórí àwọn ìbùkún tó ń rí gbà.—Kólósè 3:15.
6. Kéèyàn máa dárí jini.—Mátíù 6:14.
7. Kéèyàn máa mojú àwọn táá máa bá rìn.—Òwe 13:20.
8. Kéèyàn máa tọ́jú ara rẹ, kó má sì ṣe lọ́wọ́ sí ìwà tí ò dáa tó lè mọ́ ọn lára.—2 Kọ́ríńtì 7:1.
9. Kéèyàn “máa yọ̀ nínú ìrètí” tí Bíbélì mú kó ní.—Róòmù 12:12.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Ìrètí tí Bíbélì gbé ka iwájú wa pé a óò máa gbé nínú ayé tuntun máa ń tuni nínú gan-an ni