Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
3 Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú Ní Myanmar
Ọ̀SẸ̀ SEPTEMBER 3-9, 2018
Ọ̀pọ̀ lónìí ló ń wá ojúure lọ́dọ̀ àwọn èèyàn nínú ayé Sátánì. Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ pé ojúure Jèhófà ló yẹ ká máa wá àti bí Jèhófà ṣe máa ń fojúure hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. A tún máa jíròrò bí Jèhófà ṣe lè ṣojúure sí wa nígbà míì, kódà láwọn ọ̀nà tá ò lérò.
Ọ̀SẸ̀ SEPTEMBER 10-16, 2018
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìdí tí Mósè fi pàdánù àǹfààní tó ní láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. A sì máa rí ohun tó yẹ ká ṣe ká má bàa pàdánù àǹfààní táwa náà ní bíi ti Mósè.
Ọ̀SẸ̀ SEPTEMBER 17-23, 2018
17 “Ta Ni Ó Wà ní Ìhà Ọ̀dọ̀ Jèhófà?”
Ọ̀SẸ̀ SEPTEMBER 24-30, 2018
Jèhófà ló dá gbogbo èèyàn torí náà òun ló ni wá. Ìdí nìyẹn tó fi fẹ́ ká fi gbogbo ọkàn wa sin òun. Àmọ́ àwọn kan wà tí wọ́n sọ pé Ọlọ́run làwọn ń sìn, síbẹ̀ tí wọ́n ń ṣe ohun tó burú. Nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, a máa kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Kéènì, Sólómọ́nì, Mósè àti Áárónì. Nínú àpilẹ̀kọ kejì, a máa rí àwọn nǹkan tá a lè ṣe ká lè fi hàn pé a mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún wa láti jẹ́ èèyàn rẹ̀.
27 Máa Fàánú Hàn sí “Gbogbo Onírúurú Ènìyàn”
30 Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Gbádùn Mọ́ Ẹ Kó sì Ṣe Ẹ́ Láǹfààní