ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w18 July ojú ìwé 32
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹyin Alagba, Ẹ Fi Ododo Ṣe Idajọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ìjọ Wà ní Mímọ́ Kí Àlàáfíà sì Jọba
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àwọn Àgùntàn Jehofa Nílò Àbójútó Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
w18 July ojú ìwé 32

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Táwọn méjì tí kì í ṣe tọkọtaya bá sun inú ilé kan náà mọ́jú lábẹ́ ipò tó ń kọni lóminú, ǹjẹ́ a lè torí ẹ̀ gbé ìgbìmọ̀ onídàájọ́ dìde?

Wọ́n gbé mọ́tò méjì síwájú ilé kan lálẹ́

Bẹ́ẹ̀ ni, ti pé wọ́n sun inú ilé kan náà mọ́jú jẹ́ ẹ̀rí pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti ṣèṣekúṣe, èyí sì lè gba pé kí àwọn alàgbà gbé ìgbìmọ̀ onídàájọ́ dìde àyàfi tó bá jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé lábẹ́ àwọn ipò tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.​—1 Kọ́r. 6:18.

Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà máa ṣàyẹ̀wò ọ̀ràn náà dáadáa kí wọ́n tó lè gbé ìgbìmọ̀ onídàájọ́ dìde. Bí àpẹẹrẹ: Ṣé àwọn méjèèjì ń fẹ́ ara wọn sọ́nà? Ṣé àwọn alàgbà ti fún wọn nímọ̀ràn nípa bí wọ́n ṣe ń fìfẹ́ hàn síra wọn láwọn ìgbà kan? Kí ló fà á tí wọ́n fi ní láti sùn pa pọ̀ lálẹ́ ọjọ́ náà? Ṣé wọ́n ti ṣètò tẹ́lẹ̀ pé àwọn á jọ sun ibẹ̀ mọ́jú? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí wọ́n sùn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́jọ́ náà, àbí àwọn ipò àìròtẹ́lẹ̀ kan ló wáyé tó fi jẹ́ pé kò sóhun tí wọ́n lè ṣe ju pé kí wọ́n sùn pa pọ̀? (Oníw. 9:11) Ibo lẹnì kọ̀ọ̀kan wọ́n sùn sí? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ipò kọ̀ọ̀kan máa ń yàtọ̀ síra, àwọn nǹkan míì wà táwọn alàgbà tún máa gbé yẹ̀ wò.

Lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà bá ti gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò fínnífínní, wọ́n á pinnu bóyá ohun táwọn méjèèjì ṣe máa gba pé kí wọ́n gbé ìgbìmọ̀ onídàájọ́ dìde.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́