ÀWỌN OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ ÌRÒYÌN YÌÍ
Ọ̀SẸ̀ DECEMBER 31, 2018–JANUARY 6, 2019
Ọ̀SẸ̀ JANUARY 7-13, 2019
8 “Èmi Yóò Máa Rìn Nínú Òtítọ́ Rẹ”
Àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí máa jẹ́ ká mọyì bí òtítọ́ tí Jèhófà kọ́ wa ti ṣeyebíye tó. Àǹfààní tí òtítọ́ yìí ń ṣe wá kọjá ohunkóhun tá a yááfì ká lè sọ òtítọ́ di tiwa. Àwọn àpilẹ̀kọ yìí tún máa jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ mọyì òtítọ́ kó má sì bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́.
Ọ̀SẸ̀ JANUARY 14-20, 2019
13 Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Kó O Lè Wà Láàyè!
Ìwé Hábákúkù jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà ìṣòro. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí i pé kò sí bí àníyàn, ìṣòro tàbí wàhálà tá à ń kojú ti pọ̀ tó, Jèhófà máa gbà wá tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé e.
Ọ̀SẸ̀ JANUARY 21-27, 2019
Ọ̀SẸ̀ JANUARY 28, 2019–FEBRUARY 3, 2019
23 Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Nǹkan Ni Ìwọ Náà Fi Ń Wò Ó?
Bá a ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, a máa rí i pé èrò rẹ̀ ga fíìfíì ju tiwa lọ. Àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí ṣàlàyé ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe kó má bàa di pé èrò ayé lá máa darí wa àti bá a ṣe lè máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó.
28 Inú Rere—Ànímọ́ Kan Tó Yẹ Kó Hàn Nínú Ọ̀rọ̀ àti Ìṣe Wa