Àpótí Ìbéèrè
◼ Nínú ọ̀ràn kan tó jẹ́ pé wọn kò yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́ nítorí pé ó fi ojúlówó ìrònúpìwàdà hàn, síbẹ̀ ǹjẹ́ ó bá a mu lábẹ́ àwọn ipò kan láti ká a lọ́wọ́ kò kí ó má ṣe kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù?
Nígbà tí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ bá bá ẹnì kan wí, a ní láti ká ẹni náà lọ́wọ́ kò láwọn ọ̀nà kan. Lára rẹ̀ ni pé ẹni náà kò ní lè dáhùn ní àwọn ìpàdé, kò ní lè ṣe iṣẹ́ tàbí àṣefihàn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò ní lè ṣáájú ìjọ nínú àdúrà. Níwọ̀n bí ìwà àìtọ́ tó hù ti jẹ́ ẹ̀rí pé ó jẹ́ aláìlera nípa tẹ̀mí, kíka a lọ́wọ́ kò jẹ́ inú rere tó mú kí ẹrù iṣẹ́ tó ní dín kù. Yóò wá ní àkókò púpọ̀ sí i fún àwọn nǹkan tẹ̀mí, irú bí ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò.
Kò yẹ kí a ká a lọ́wọ́ kò pé kí ó má ṣe kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù àti ríròyìn iṣẹ́ rẹ̀. (Róòmù 10:9, 10) Ńṣe ni iṣẹ́ ìwàásù ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbàgbọ́ wa ró. Nítorí náà, olúkúlùkù Kristẹni gbọ́dọ̀ máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, kí ó sì máa tipa bẹ́ẹ̀ fi ìgbàgbọ́ tí ó wà nínú rẹ̀ hàn nípa iṣẹ́.
Bó bá jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ nípa ìwà àìtọ́ tó hù ńkọ́? Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kí ó kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, ó kéré tán, fún àwọn àkókò kan, ní apá kan ìpínlẹ̀ náà tí àwọn èèyàn kò ti fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ìṣòro yẹn. Ó dára láti fi sọ́kàn pé iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ apá pàtàkì nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run, gbogbo èèyàn Jèhófà ló sì gbọ́dọ̀ máa kópa nínú rẹ̀.—Mát. 24:14; 28:18-20.
Ẹni tí wọ́n wá gbà padà lẹ́yìn tí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ ńkọ́? Ṣé ó yẹ kí wọ́n jẹ́ kí ó bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lójú ẹsẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a sọ lókè, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ó bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lẹ́yìn tí a bá ti gbà á padà. Ní ti àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn mìíràn tó ní í ṣe pẹ̀lú èyí, díẹ̀díẹ̀ ni ìgbìmọ̀ onídàájọ́ yóò máa dá èyí padà bí wọ́n bá ti ń rí ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí ẹni náà.