Báwo La Ṣe Lè Pèsè Àwọn Àfikún Gbọ̀ngàn Ìjọba Tí A Nílò?
1 Látìgbà tí ìjọ Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀ làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti máa ń pé jọ pa pọ̀ kí Jèhófà lè kọ́ wọn. Lọ́jọ́ àwọn àpọ́sítélì, inú àwọn ilé àdáni ni àwọn Kristẹni ti máa ń ṣe ìpàdé lọ́pọ̀ ìgbà. Láwọn ibì kan, wọ́n sọ̀rọ̀ nínú sínágọ́gù àwọn Júù. Ní Éfésù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ àwọn àsọyé fún ọdún méjì ní gbọ̀ngàn ilé ẹ̀kọ́. (Ìṣe 19:8-10; 1 Kọ́r. 16:19; Fílém. 1, 2) Bákan náà lónìí, ní Nàìjíríà àti níbòmíràn, àwọn ìjọ máa ń ṣe ìpàdé ní àwọn ilé àdáni, ní àgbàlá, àní lábẹ́ àtíbàbà pàápàá. Ní tòótọ́, bóyá a ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí a kò ní, a kò gbàgbé pé pípàdé pọ̀ déédéé ṣe pàtàkì.—Héb. 10:24, 25.
2 Àwọn ìjọ kan ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó sì ṣe kedere pé Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí a sì ń tọ́jú dáadáa máa ń fa àwọn olùfìfẹ́hàn mọ́ra. Ní apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé, irú àwọn gbọ̀ngàn bẹ́ẹ̀ ń fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìtara fún ìjọsìn mímọ́. Ìdí nìyí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ gidigidi sí kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba ní àgbègbè wa. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, a nílò ẹgbẹẹgbẹ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Láfikún sí i, lójoojúmọ́ ni a ń dá ìjọ tó ju mẹ́fà sílẹ̀ jákèjádò ayé. Ní Nàìjíríà, ó yẹ kí á kọ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀sán [1,800] Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kí ló ń jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba gan-an? Báwo la ṣe ń kọ́ ọ? Ibo ni owó tí a fi ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ti ń wá? Báwo la sì ṣe lè pèsè èyí?
Kí Ló Ń Jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba?
3 Gbólóhùn náà, “Gbọ̀ngàn Ìjọba” ni a lò fún ìgbà àkọ́kọ́ fún ilé kan tí a kọ́ ní Hawaii lọ́dún 1935 nínú èyí tí ìjọ kan ti ń ṣe ìpàdé. Orúkọ yẹn bá a mu nítorí ète gan-an tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà fún ni láti ṣètìlẹ́yìn fún kíkéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Látọdún 1935 yẹn, a ti kọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba jákèjádò ayé. Àmọ́ ṣá o, bí a ṣe ní láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan máa ń wà ní ìbámu pẹ̀lú apá ibi tó wà láyé, orílẹ̀-èdè tó wà, àti àdúgbò ibi tí a bá kọ́ ọ sí. Síbẹ̀, gbogbo gbọ̀ngàn wọ̀nyẹn gbọ́dọ̀ ní àwọn ohun tí wọ́n fi jọra. Wọ́n gbọ́dọ̀ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, a gbọ́dọ̀ kọ́ wọn dáadáa, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣeé lò fún pípàdé pọ̀ ní àlàáfíà láti tẹ́tí sí àwọn ẹ̀kọ́ Ọlọ́run. Kò pọndandan pé kí ó jẹ́ ilé ajé-kú-ìkàlẹ̀.—1 Jòh. 2:16.
4 Nínú àkìbọnú yìí, a fi fọ́tò àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kan hàn tí a kọ́ ní Nàìjíríà lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí a ṣe kọ́ wọn yàtọ̀ síra, gbogbo wọn ló fani mọ́ra tí a sì kọ́ dáadáa. Láfikún sí i, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba bá àyíká mu, kí wọ́n mọ́ tónítóní, kí a sì máa tọ́jú wọn dáadáa. Ǹjẹ́ kò máa ń jẹ́ ohun àmúyangàn fún wa láti rí àkọlé náà “Kingdom Hall of Jehovah’s Witnesses” [Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] lára àwọn ilé wọ̀nyẹn?
5 Ta ló ni Gbọ̀ngàn Ìjọba? Bí a bá ti yọwọ́ ti ohun tí òfin ń béèrè kúrò, ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí àwùjọ kan nínú ìjọ kò gbọ́dọ̀ ronú láé pé àwọn ló “ni” Gbọ̀ngàn Ìjọba, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ìjọ èyíkéyìí ló “ni” ín. Jèhófà la yà á sí mímọ́ fún. Ìjọ tó bá kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí tó yá a lò wúlẹ̀ ní in gẹ́gẹ́ bí ohun tí a fi sí ìkáwọ́ wọn ni, ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ló sì ni ẹrù iṣẹ́ láti fọgbọ́n bójú tó lílo gbọ̀ngàn náà kí ó lè ṣiṣẹ́ fún ire Ìjọba náà lọ́nà tó dára jù lọ. Nígbà tí ìjọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ bá ń ṣèpàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, wọ́n lè jọ máa lo ohun èlò ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, aago, àwọn ohun èlò tí a fi ń ṣètọ́jú gbọ̀ngàn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí jẹ́ ẹ̀rí pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wà láàárín àwọn ìjọ náà. Àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ gbọ́dọ̀ máa bójú tó àwọn nǹkan tí wọ́n jọ ń lò yẹn kí wọ́n sì máa rántí pé èyí ń fi kún ire àwọn ará wa.—Mát. 7:12.
Báwo La Ṣe Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba?
6 Níwọ̀n bí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba ti yàtọ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn, ọ̀nà tí a ń gbà kọ́ wọn yàtọ̀ síra bákan náà. Jèhófà la ń ya àwọn ilé yìí sí mímọ́ fún, nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń láyọ̀ láti fínnúfíndọ̀ kópa nínú kíkọ́ wọn. Onísáàmù náà sọ pé: “Àwọn ènìyàn rẹ yóò fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn.”—Sáàmù 110:3.
7 Wọ́n mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa pé a máa ń fi ìtara àti ìmúratán ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Ìtẹ̀jáde kan sọ̀rọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní sísọ pé: “Yóò ṣòro láti rí àwọn mẹ́ńbà àwùjọ ìsìn mìíràn tí wọ́n máa ń fi taratara ṣiṣẹ́ nídìí ìjọsìn wọn bí àwọn Ẹlẹ́rìí ti ń ṣe.” Nínú àlàyé tí ìwé ìròyìn kan ṣe, ó ṣàyọlò ọ̀rọ̀ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹni tó ń bójú tó iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan, ó ní: “Nígbà mìíràn . . . a máa ń ní àwọn òṣìṣẹ́ níbí ju bí a ṣe nílò wọn.” Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, ìwé ìròyìn kan náà tún sọ nípa díákónì kan tó kédàárò pé agbára káká ni àwọn èèyàn fi yọjú fún iṣẹ́ kan tí “ọ̀pọ̀ ìjọ tó jẹ́ ti Pùròtẹ́sítáǹtì” ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀.
8 Ọ̀pọ̀ akéde ló ti lo ọ̀pọ̀ àkókò, owó, àti agbára wọn láti ṣèrànwọ́ ní kíkọ́ àwọn ibi tó yẹ fún ìjọsìn. Ní tòótọ́, ìrànwọ́ tí àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fínnúfíndọ̀ ṣe ti mú kí ó ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà pé, a kò wulẹ̀ gba lébìrà, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdí fún wa láti wá àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nígbà tí a bá ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Ńṣe làwọn tó yọ̀ǹda ara wọn máa ń wo irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtìlẹ́yìn fún ìtẹ̀síwájú ire Ìjọba náà, wọ́n máa ń wò ó bí wọ́n ṣe ń wo iṣẹ́ ìsìn pápá wọn. Wọ́n mọrírì àwọn ìbùkún tẹ̀mí tí kò ṣeé díye lé tí àwọn àtàwọn ẹlòmíràn yóò rí gbà látinú lílo irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, wọ́n máa ń fi ìlànà yìí sílò pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.”—Mátíù 10:8.
9 Bí a bá ké sí ọ pé kí o wá kópa nínú kíkọ́ ibi ìjọsìn kan fún Jèhófà nítorí pé o tóótun nípa tẹ̀mí tí o sì ní òye iṣẹ́, sa gbogbo agbára rẹ láti gba ìkésíni yìí. (Sm. 122:1) A ń rọ ẹ̀yin alàgbà pé kí ẹ fún àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni níṣìírí. Àwọn alàgbà lè fi hàn pé àwọn ń ti ìṣètò ìṣàkóso Ọlọ́run yìí lẹ́yìn ní kíkún nípa lílọ bá àwọn mẹ́ńbà ìjọ tí ó tóótun kí wọ́n sì fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n lo ẹ̀bùn àbínibí wọn láti fi sin àwọn arákùnrin wọn.—Gál. 6:10.
10 Kí a tó lè ṣàṣeyọrí nínú píparí iṣẹ́ kan, ó dájú pé yóò gba ọ̀pọ̀ wákàtí iṣẹ́ àṣekára; ṣùgbọ́n Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó bá ń fi tọkàntọkàn sìn ín. (Kól. 3:23, 24) Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè di dandan pé kí ìjọ kan sanwó fún àwọn òṣìṣẹ́ tí kì í ṣe ará láti wá bá wọn ṣiṣẹ́. Nínú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ìwé àdéhùn gbọ́dọ̀ wà láàárín àwọn òṣìṣẹ́ ọ̀hún àti ìjọ.—Wo Ilé-ìṣọ́nà, November 15, 1986, ojú ìwé 16.
Ibo Ni Owó Rẹ̀ Ti Ń Wá?
11 Láìdà bíi ti àwọn ìjọ inú Kirisẹ́ńdọ̀mù, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gbé igbá owó, a kì í tọrọ owó, bẹ́ẹ̀ ni a kì í san ìdámẹ́wàá. Nípa báyìí, ní ti àwọn ọrẹ wa, a máa ń fínnúfíndọ̀ mú un wá ni, ó sì máa ń jẹ́ látọkànwá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wí pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, . . . nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”—2 Kọ́r. 9:7.
12 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba jákèjádò ayé la ti fi ọrẹ àtinúwá yìí kọ́, a dúpẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ọkàn wọn ti sún wọn láti ṣètọrẹ tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí àwòrán wọn wà nínú àkìbọnú yìí nìyẹn, àti ti àwọn mìíràn tí a ń kọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Nàìjíríà. Àwọn kan wà láàárín àwọn èèyàn Jèhófà lónìí tí àwọn pẹ̀lú dà bí òtòṣì opó yẹn tí wọ́n ń fi “owó kéékèèké” tí wọ́n ní ṣètọrẹ. (Máàkù 12:42) Bákan náà, a ní àwọn kan lónìí tí wọ́n ń fi ẹ̀mí tí ó jọ ti Bánábà hàn. Lẹ́yìn tí Bánábà ta ilẹ̀ tó ní, ó “mú owó náà wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì.” (Ìṣe 4:37) Àmọ́ ṣá o, a kì í polongo rẹ̀ nígbà tí a bá ń fi ọrẹ ṣètìlẹyìn. (Mát. 6:3, 4) Inú wa dùn láti rí i pé àwọn ìjọ kan ti rí ilẹ̀ gbà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn lórí èyí tí wọ́n lè kọ́lé sí tàbí tí wọ́n rí ẹ̀bùn ilẹ̀ tí wọ́n lè tà gbà kí wọ́n sì lo owó tí wọ́n bá rí níbẹ̀ fún iṣẹ́ ìkọ́lé. Àní àwọn kan wà tí wọ́n yọ̀ǹda láti pèsè àwọn ohun èlò ìkọ́lé tàbí láti pèsè oúnjẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé náà.
13 Àwọn ìjọ kan ti gba ẹ̀yáwó látinú Owó Àkànlò Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba. Owó àkànlò tó ń jẹ́ kí Society lè yani lówó yìí wá látinú ọrẹ tí ẹgbẹ́ ará kárí ayé fi ń ṣètìlẹyìn. Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso gbà pé kí a yáni lówó yìí lábẹ́ àwọn ipò tí yóò jẹ́ kí àwọn ará lè san wọ́n padà bí agbára wọn bá ṣe gbé e tó. Ọ̀pọ̀ ló ti fi ìmoore hàn nítorí ìṣètò onífẹ̀ẹ́ yìí tó ń jẹ́ kí “ìmúdọ́gba” owó lè wà láàárín àwọn tó ní “àṣẹ́kùsílẹ̀” àti àwọn tí kò ní ‘tó.’ (2 Kọ́r. 8:14, 15) Láti bójú tó iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe yìí, àwọn ìjọ tó yáwó máa ń ṣiṣẹ́ kára láti san án padà. (Gál. 6:5) Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ìjọ kan ní ìṣòro fún ìgbà díẹ̀ láti san owó tí wọ́n yá padà fún Society, ohun tó dára ni kí àwọn alàgbà fún ìjọ níṣìírí pé kí wọ́n pa àdéhùn wọn mọ́.
14 Ní ti iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, a rọ àwọn ìjọ pé kí wọ́n má “pilẹ̀” kíkọ́ gbọ̀ngàn tuntun nígbà tí kò bá pọndandan. Bí àpẹẹrẹ, ìjọ méjì tàbí mẹ́ta tí wọ́n wà lágbègbè kan náà lè jọ máa lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Nípa báyìí, ní àwọn àgbègbè tí ìjọ bíi mélòó kan bá wà, gbogbo wọn lè jọ sapá láti kọ́ gbọ̀ngàn kan dípò tí ìjọ kọ̀ọ̀kan yóò fi ní gbọ̀ngàn tirẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n á lè máa lo gbọ̀ngàn náà dáadáa, ẹrù ìnáwó ọ̀hún yóò sì rọrùn láti gbé.
15 Bí ìjọ kan bá pinnu láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, ojú ẹsẹ̀ yẹn ni kí àwọn ará bẹ̀rẹ̀ sí í máa fi ọrẹ ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìkọ́lé ọ̀hún. Fún ète yẹn, àwọn ìjọ kan ti ṣí àkáǹtì tí wọ́n ń fi owó pa mọ́ sí fún iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n á ṣe lọ́jọ́ iwájú. Nígbà tí ìjọ bá bẹ̀rẹ̀ sí jíròrò bóyá yóò ṣeé ṣe láti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, ìwọ fúnra rẹ lè fi owó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ọ̀hún. Láfikún sí i, o lè fẹ́ láti pinnu iye tí o lè máa fi ṣètìlẹyìn lóṣooṣù, bí Jèhófà ti ń bù kún ọ. Àwọn alàgbà lè wádìí èyí látọ̀dọ̀ ìjọ kí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wéwèé fún iṣẹ́ náà. Ìwé pélébé tí olúkúlùkù kọ iye tí wọn yóò máa fi ṣe ìtìlẹyìn sí, ṣùgbọ́n tí wọn kò ní kọ orúkọ wọn sí ti tó láti fi mọ iye tí ó lè wọlé. Ní ìbámu pẹ̀lú ìwádìí yìí, àwọn alàgbà lè dábàá ìpinnu kan fún ìjọ nípa bí ìjọ yóò ṣe máa san ẹ̀yáwó padà, nípa ipa tí ìjọ yóò kó nínú iṣẹ́ ìkọ́lé tàbí nínú ṣíṣètọ́jú Gbọ̀ngàn Àpéjọ, tàbí nínú sísan owó tí a fi ń bójú tó àwọn ìnáwó Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó ṣe pàtàkì pé kí a ronú nípa àwọn ìnáwó wọ̀nyí ní ìbámu pẹ̀lú agbára ìjọ. Pọ́ọ̀lù dábàá pé kí àwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì máa tẹ̀ lé ìlànà ṣíṣe nǹkan déédéé kí wọ́n lè rí i dájú pé wọ́n ń ṣe àwọn nǹkan rere tí wọ́n ní lọ́kàn. (1 Kọ́r. 16:2) Nítorí èyí, a ní láti lo ìdánúṣe, ìṣàkóso ara ẹni, àti ìpinnu.—1 Kọ́r. 9:23, 25, 27.
Pípèsè Ohun Tí A Nílò
16 Láti lè pèsè àfikún Gbọ̀ngàn Ìjọba tí a nílò ní Nàìjíríà àti ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè mìíràn, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti gbé ètò àkànṣe kan kalẹ̀. Ète rẹ̀ ni láti pèsè àwọn gbọ̀ngàn tí a nílò wọ̀nyí láàárín ọdún díẹ̀ tí yóò tẹ̀ lé e. Ní ọ́fíìsì ẹ̀ka ti Nàìjíríà, a ti gbé Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kalẹ̀ nínú èyí tí a ti yan àwọn arákùnrin láti ṣètò kí wọ́n sì mú ipò iwájú nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kí wọ́n sì máa ṣe kòkáárí ètò ọ̀hún. Nípasẹ̀ ẹ̀ka náà, a ti pèsè àwòrán ilé tó kúnjú ìwọ̀n àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ohun èlò, a sì ti ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ń bá a lọ fún gbogbo àwọn tó ń kópa nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn arákùnrin tó wà ní ẹ̀ka náà ló ń ṣe kòkáárí ìgbòkègbodò ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ará tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wọ́n máa ń ṣàyẹ̀wò gbogbo iṣẹ́ ìkọ́lé ṣáájú kí wọ́n tó gbé ìgbésẹ̀ lórí rẹ̀ àti ṣáájú kí wọ́n tó dábàá pé kí á tẹ́wọ́ gbà á.
17 Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn máa ń gba ìsọfúnni àti ìtọ́ni látọ̀dọ̀ ẹ̀ka náà, ìyẹn sì ń jẹ́ kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún ìjọ láti rí ilẹ̀, láti ya àwòrán, kí wọ́n sì gba ìyọ̀ǹda fún kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tún máa ń ran ìjọ lọ́wọ́ láti tóótun fún ìrànwọ́ owó látọ̀dọ̀ Society. A gba àwọn ìjọ tó bá ń wéwèé láti ra ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ kọ́ gbọ̀ngàn sí tàbí tí wọ́n fẹ́ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba nímọ̀ràn pé kí wọ́n kàn sí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn wọn láìfọ̀rọ̀ jáfara. Ọ̀pọ̀ ìṣòro ni wọ́n á lè tipa báyìí yẹra fún nípa kíkọ́gbọ́n látinú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá àti látinú àwọn ìtọ́ni tí Society pèsè kẹ́yìn. Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn yóò wá kàn sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba èyí tí yóò wá dábàá ìṣètò tí yóò jẹ́ kí ìjọ lè kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba láàárín àkókò kúkúrú pẹ̀lú ìrànwọ́ àwọn ará tó ní òye iṣẹ́. Níwọ̀n bí gbọ̀ngàn táa nílò ti pọ̀ jọjọ, ó máa gba ọdún díẹ̀ kí gbogbo ìjọ tó wà ní Nàìjíríà tó lè ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bójú mu tó sì wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Nítorí ìdí yìí, yóò gba sùúrù. Ṣùgbọ́n o, bí àwọn ìjọ ti ń dúró dé ìgbà tí gbọ̀ngàn wọn yóò di kíkọ́, àwọn ará lè ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ náà nípa mímú ọrẹ wá.
18 Láfikún sí ìtìlẹyìn, ìdánilẹ́kọ̀ọ́, àti ìṣekòkáárí púpọ̀ sí i tí a óò máa pèsè fún àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn nípasẹ̀ Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, a ti gbé Àwọn Àwùjọ Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kalẹ̀ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún àkókò kíkún tí yóò sì máa ṣiṣẹ́ lábẹ́ àbójútó ẹ̀ka tuntun yẹn. Kí àwùjọ tó ń kọ́lé yìí lè wà, Society ti dá ọ̀wọ́ àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún mìíràn sílẹ̀. Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ la ń pè ní àwọn òṣìṣẹ́ tí ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Gẹ́gẹ́ bí àwọn òṣìṣẹ́ yòókù tó ń ṣe àkànṣe iṣẹ́ alákòókò kíkún, irú bí àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe àti àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ti ṣe, àwọn òṣìṣẹ́ wọ̀nyí ń fi irú ẹ̀mí tí Aísáyà ní hàn, wọ́n ń sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísá. 6:8) Bí àwọn ará wọ̀nyí ti mọ̀ nípa ọ̀nà tí Society ń gbà kọ́lé, wọ́n jẹ́ ìrànwọ́ ńláǹlà fún àwọn ìjọ nínú kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti píparí wọn. Ì báà jẹ́ Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tàbí Àwùjọ Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ló ṣètìlẹyìn fún ìjọ kan tó fẹ́ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, ìjọ tó ń kọ́ gbọ̀ngàn náà ló ni iṣẹ́ ìkọ́lé yẹn ní ti gidi. Àfikún ìrànwọ́ èyíkéyìí tí Society bá pèsè ni wọ́n gbọ́dọ̀ wò pé ó jẹ́ àfikún ìtìlẹyìn. Èyí túmọ̀ sí pé nígbà tí ìjọ kan bá dáwọ́ lé iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ, àtàwọn tó ní òye iṣẹ́ àtàwọn tí kò ní òye iṣẹ́ ló gbọ́dọ̀ ṣètìlẹyìn ní ìbámu pẹ̀lú ètò tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe.
19 Lọ́wọ́lọ́wọ́, a ń fẹ́ ọ̀pọ̀ olùyọ̀ǹda ara ẹni sí i láti ṣèrànwọ́ nínú kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ọ̀pọ̀ fọ́ọ̀mù tí a fi ń béèrè fún dídi àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba la ti fi ránṣẹ́ sí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn alàgbà. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba yàtọ̀ sí àwọn òṣìṣẹ́ tí ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ti pé ọ̀sẹ̀ méjì sí oṣù mẹ́ta lá máa ń pe àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni fún láti wá ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Àwùjọ Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Irú àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń jẹun, wọ́n sì máa ń rí ibùgbé níbi iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n ti ń ṣèrànwọ́, bó bá sì pọndandan, a lè ṣèrànwọ́ fún wọn láti bójú tó ìnáwó ìrìn àjò wọn. Lára àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọ̀nyí ni Society ti máa ń yan àwọn òṣìṣẹ́ tí ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí o bá nífẹ̀ẹ́ sí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yìí, o lè sọ fún alábòójútó olùṣalága ìjọ rẹ tí yóò jẹ́ kí o mọ̀ bí o bá tóótun láti gba fọ́ọ̀mù ìwọṣẹ́. Ní pàtàkì, àwọn ará tó tóótun nípa tẹ̀mí tí wọ́n ní òye nípa iṣẹ́ ìkọ́lé la ń wá. Lékè ohun gbogbo, àwọn ará wọ̀nyí gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tẹ̀mí, wọ́n gbọ́dọ̀ ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe tán láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa pẹ̀lú àwọn tí a yàn láti mú ipò iwájú. Kódà bí a kò bá pè ọ́ lójú ẹsẹ̀, a óò tọ́jú ìwé ìwọṣẹ́ rẹ sínú fáìlì títí di ìgbà tí a bá nílò rẹ.
20 Láfikún sí àwọn ohun tí Society ti ṣe yìí, ó yẹ kí àwọn alàgbà àti ìjọ lápapọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa. Àwọn àwòrán ilé tó kúnjú ìwọ̀n, àti àwọn ìlànà tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ti Society gbé kalẹ̀, lè máà bá ohun táa ń fẹ́ mu, ó sì lè ṣàìwù wá. Ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà tí àwọn aṣojú Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba bá fún wa bí wọ́n ti ń fi ìtọ́sọ́nà tí Society pèsè sílò lè yàtọ̀ sí ohun tí ìjọ wéwèé tàbí tí ìjọ fẹ́. Ọ̀nà tí Àwùjọ Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ń gbà kọ́lé lè yàtọ̀ sí ọ̀nà tí a mọ̀. Ṣùgbọ́n, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ète tí gbogbo wa ní kì í ṣe láti gbé ohun ìrántí kalẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tàbí fún ìjọ, ṣùgbọ́n láti pèsè ibi ìpàdé, inú wa yóò dùn láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí a yàn láti mú ipò iwájú nínú ọ̀ràn yìí. (1 Tẹs. 5:12, 13; Héb. 13:17) Ó dájú pé, láti lè pèsè àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí a nílò báyìí láàárín àkókò tí kò gùn, a ní láti fi àwọn ohun kan rúbọ, ó lè jẹ́ lílo ara wa, lílo àkókò wa, lílo ohun ìní wa, tàbí yíyááfì àwọn ohun kan.—Fílém. 2:2-4.
Ìkọ́lé Tí Ń Fògo fún Jèhófà
21 Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí a kọ́ dáadáa, tí a sì ń tọ́jú dáadáa ń fògo fún Jèhófà. A ń ké sí wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti gẹ́gẹ́ bí ìjọ pé kí a ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí a ní kí a sì ronú nípa ibi tí a lè ṣètìlẹyìn dé fún iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nípa kíkàn sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba nípasẹ̀ Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tí a yan ìjọ yín fún ṣáájú kí ẹ tó dáwọ́ lé iṣẹ́ ìkọ́lé èyíkéyìí (bóyá kíkọ́ ilé tuntun, píparí tàbí ṣíṣàtúnṣe gbọ̀ngàn tó ti wà tẹ́lẹ̀, tàbí ṣíṣe àwọn àfikún tàbí ìyípadà kan lára Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ẹ ti parí tẹ́lẹ̀), ẹ óò jàǹfààní látinú ìsọfúnni àti ìrírí tó wà nílẹ̀. A ń fẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba púpọ̀ sí i ní Nàìjíríà, a sì gbọ́dọ̀ máa fi í kún àdúrà wa. Pípèsè wọn ni yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ìkọ́lé títóbi jù lọ tí a tíì dáwọ́ lé rí ní orílẹ̀-èdè yìí. Kí ọwọ́ wa lè tẹ ohun tí à ń lépa, gbogbo wa yóò fẹ́ láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ti Society, a óò sì fẹ́ láti fi ìmúratán tẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà tí ẹ̀ka náà bá pèsè. Bí a sì ti ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò tí Society ń ṣe fún kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí, a mọ̀ pé yóò gba àkókò díẹ̀ kí gbogbo ìjọ tó lè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tiwọn. Inú wa yóò mà dùn o nígbà tí gbogbo ìjọ bá lè máa pàdé déédéé nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bójú mu kí Jèhófà lè kọ́ wọn, ní mímọ̀ pé gbogbo wa la kópa nínú mímú kí èyí ṣeé ṣe!—Sm. 122:1; Míkà 4:2.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó kúnjú ìwọ̀n, tó ní àyè ìjókòó èèyàn márùnlélọ́gọ́sàn-án [185] tí a kọ́ sí ìlú Warri
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó kúnjú ìwọ̀n, tó ní àyè ìjókòó ọgọ́rùn-ún [100] èèyàn tí a kọ́ sí ìlú Agbor
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó kúnjú ìwọ̀n, tó ní àyè ìjókòó àádọ́jọ [150] èèyàn tí a kọ́ sí ìlú Owode-Yewa