Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní August: Gbogbo èdè—Èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú-ìwé 32 tí ó tẹ̀lé e yìí ni a lè fi lọni fún ọrẹ ₦24: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Gbogbo èdè—Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. A níláti sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé. October: Gbogbo èdè—Àsansílẹ̀-owó fún Ilé-Ìṣọ́nà tàbí Jí! Ṣe àkànṣe ìsapá láti fi àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn sóde. A tún lè fi àsansílẹ̀-owó lọni nígbà ìpadàbẹ̀wò. November: Gẹ̀ẹ́sì—New World Translation of the Holy Scriptures àti ìwé náà The Bible—God’s Word or Man’s? Yorùbá—Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun. Àwọn èdè yòókù—Iwe Itan Bibeli Mi tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétáásì tí a mẹ́nukàn lókè yìí níláti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Ìjọ kọ̀ọ̀kan yóò gba fọ́ọ̀mù Literature Inventory mẹ́ta. Akọ̀wé ìjọ níláti rí ìránṣẹ́ tí ń bójútó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ August kí wọ́n sì dá ọjọ́ tí wọn yóò ṣèṣirò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà nínú ìjọ ní ìparí oṣù náà. Wọ́n gbọ́dọ̀ ka àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà lọ́wọ́ níti gidi, kí wọ́n sí kọ àròpọ̀ rẹ̀ sínú fọ́ọ̀mù Literature Inventory. Ìránṣẹ́ tí ń bójútó ìwé ìròyìn lè sọ àròpọ̀ iye ìwé ìròyìn tí ó wà lọ́wọ́ fún wọn. Ẹ jọ̀wọ́ fi ẹ̀dà tí ó wà lókè ránṣẹ́ sí Society ó pẹ́ jù ní September 6. Ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì yín. Ẹ lè lo ẹ̀dà kẹ́ta fún àkọdánrawò yín. Akọ̀wé níláti bójútó ìṣirò náà, alábòójútó olùṣalága sì níláti ṣàyẹ̀wò fọ́ọ̀mù tí a ti kọ ọ̀rọ̀ kún náà. Akọ̀wé àti alábòójútó olùṣalága yóò fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà.
◼ A tún ń fi ẹ̀dà méjì fọ́ọ̀mù Congregation Analysis Report S-10 ránṣẹ́ sí yín pẹ̀lú. Ẹ níláti kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù yìí pẹ̀lú ìṣọ́ra gidigidi kí ẹ sì fi ẹ̀dà tí ó wà lókè ránṣẹ́ sí Society ó pẹ́ jù ní September 6, 1995, pẹ̀lú ìròyìn August yín. Ẹ̀dà kejì jẹ́ ti fáìlì yín.
◼ A ń fi ẹ̀dà méjì Report on Literacy ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. Ẹ níláti kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù yìí ní August 1 kí ẹ sì fi ránṣẹ́ sí wa ní August 6. Ẹ tọ́jú ẹ̀dà kan sínú fáìlì yín. Ẹ níláti kọ ọ̀rọ̀ kún inú fọ́ọ̀mù náà, yálà ẹ ní kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà tàbí bẹ́ẹ̀kọ́.
◼ Ẹ jọ̀wọ́ ẹ óò rí àtúnṣe tí a ṣe nínú Àwọn Ọ̀gangan Ibi Àpéjọpọ̀ Àgbègbè 1995 tí ó fara hàn nínú Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 1995 nísàlẹ̀. Fún àwọn ìjọ tí ọ̀gangan ibi àpéjọpọ̀ wọn tàbí ọjọ́ àpéjọpọ̀ wọn ti yípadà, alábòójútó olùṣalága níláti jọ̀wọ́ ṣe ìfilọ̀ ọjọ́ àti/tàbí ọ̀gangan ibi titun náà ní Ìpàdé Iṣẹ́-Ìsìn tí ó tẹ̀lé e kí ó sì lẹ ìsọfúnni yìí mọ́ pátákó ìsọfúnni, ní fífa ìlà sábẹ́ ọ̀gangan ibi àpéjọpọ̀ àti ọjọ́ àpéjọpọ̀ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yan ìjọ wọn sí.
November 10-12, 1995
JOS (Gẹ̀ẹ́sì, Hausa) NE-2B, 3, 4
December 1-3, 1995
AGBANI 3 (Igbo) IB-2 àwọn ìjọ ní ìtòtẹ̀léra lọ́nà a, b, d láti N sí Z; IB-8: Gbogbo ìjọ YÀTỌ̀ SÍ Ugwuibe (Afikpo); IB-3
MGBOKO UMUORIA 5 (Igbo) IB-28, 31; àti Ugwuibe (Afikpo) pẹ̀lú ní IB-8
ULI 2 (Gẹ̀ẹ́sì) àwọn ìjọ EE-10 ní ìtòtẹ̀léra lọ́nà a, b, d láti A sí N; EE-8
December 8-10, 1995
ULI 3 (Igbo) IB-24, 25, 29
December 15-17, 1995
AKURE 1 (Yorùbá) Y-19, 22, 23; Y-18: Gbogbo ìjọ YÀTỌ̀ SÍ Aiyeteju Amuro, Egbe, Isanlu, Magadisu (Kaduna), Panisau (Kano), àti Mopa
ULI 4 (Igbo) IB-5, 7, 23; àti àwọn ìjọ Igbo ní B-3 pẹ̀lú
December 22-24, 1995
AKURE 2 (Yorùbá) Y-21, 24; Y-25: Gbogbo ìjọ YÀTỌ̀ SÍ Temi Adara
MGBOKO UMUORIA 8 (Igbo) IB-15, 16
January 5-7, 1996
MGBOKO UMUORIA 10 (Igbo) IB-9, 19A
ULI 5 (Igbo) IB-21, 26
January 12-14, 1996
ULI 6 (Gẹ̀ẹ́sì) àwọn ìjọ EE-10 ní ìtòtẹ̀léra lọ́nà a, b, d láti O sí Z; EE-9