Àwọn Ìpàdé fún Iṣẹ́-Ìsìn Pápá
Nígbàkugbà tí a bá ṣe ìpàdé fún iṣẹ́-ìsìn pápá nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ sì péjọ, bí irú èyí tí a máa ń ṣe gbàrà lẹ́yìn ìpàdé ọjọ́ Sunday, nígbà náà alàgbà kan ṣoṣo ni ó níláti darí ìpàdé náà fún gbogbo àwùjọ. Kò gbọdọ̀ sí ìpàdé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ kọ̀ọ̀kan ní gbọ̀ngàn kan náà ní àkókò kan náà. Ṣùgbọ́n ṣáájú kí ìpàdé náà tó bẹ̀rẹ̀, ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ kọ̀ọ̀kan níláti jókòó sí ibi tí a yàn fún wọn nínú gbọ̀ngàn náà láti mú kí ó rọrùn láti ṣètò àwọn tí wọn yóò jọ ṣiṣẹ́. Ní ìparí ìtọ́ni náà àti ṣáájú kí a tó gbàdúrà, àwọn olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ kọ̀ọ̀kan níláti parí yíyan ìpínlẹ̀ àti yíyan àwọn akéde tí yóò jọ ṣiṣẹ́. Lẹ́yìn tí gbogbo wọ́n bá ti ṣe èyí, arákùnrin kan yóò gbàdúrà ìparí ṣáájú kí gbogbo àwùjọ tó jáde lọ nínú iṣẹ́-ìsìn.
Ẹ jọ̀wọ́ kíyèsi pé ìṣètò èyíkéyìí tí a bá ṣe nípa iṣẹ́-ìsìn pápá, títí kan ìpínlẹ̀ tí a óò ti ṣiṣẹ́ àti àwọn wo ni yóò jọ ṣiṣẹ́, a níláti parí gbogbo ìwọ̀nyí nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí nínú ilé tàbí ibi mìíràn tí a ti ṣe ìpàdé náà. Níwọ̀n bí èyí ti jẹ́ àwùjọ kan ṣoṣo, arákùnrin kan yóò ṣojú wọn nínú àdúrà ṣáájú kí wọ́n tó lọ sínú iṣẹ́-ìsìn pápá. A kò gbọdọ̀ pín àwọn ènìyàn tàbí ìpínlẹ̀ níta Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí níta àwọn ibi yòówù tí a ti ń pàdé fún iṣẹ́-ìsìn pápá.