Àwọn Òbí Tí Ń Yọ̀!
1 Bí o bá jẹ́ ọ̀dọ́ kan tí ń gbé nínú ilé Kristian, ọ̀nà àrà-ọ̀tọ̀ kan wà tí o lè gbà mú inú àwọn òbí rẹ dùn. Bí o bá ń lépa ọ̀nà òdodo, “bàbá rẹ àti ìyá rẹ yóò yọ̀.” (Owe 23:22-25) Gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, àwọn òbí rẹ fẹ́ ohun tí ó dára jùlọ fún ọ. Kò sí ohun tí ó lè dùn mọ́ wọn nínú ju rírí ọ kí o sọ òtítọ́ di tìrẹ kí o sì ya ìgbésí-ayé rẹ sí mímọ́ fún Jehofa.
2 Ó yẹ kí o dúpẹ́ fún níní àwọn òbí tí wọ́n wà nínú òtítọ́. Láti ìgbà ìbí rẹ, wọ́n ti bọ́ ọ, ra aṣọ sí ọ lọ́rùn, pèsè ibùgbé fún ọ, ní àfikún sí títọ́jú rẹ nígbà tí o bá ṣàìsàn. Èyí tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì jù, wọ́n ti sakun láti kọ́ ọ nípa Jehofa àti àwọn ọ̀nà òdodo rẹ̀; ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó lè mú ìyè àìnípẹ̀kun rẹ dájú nìyí. (Efe. 6:1-4) Báwo ni o ṣe lè fi ìmọrírì rẹ hàn?
3 Sọ Òtítọ́ Di Tìrẹ: Àwọn òbí rẹ ti gbìyànjú láti kọ́ ọ láti fi ọwọ́ tí ó nípọn mú òtítọ́, láti tẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí, kí o sì wà pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú ètò-àjọ Jehofa. O lè fi ìmọrírì hàn nípa fífi ìfẹ́ hàn nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé láìjẹ́ pé a fi ipá mú ọ. Fi ìfẹ́ àtọkànwá hàn sí lílọ sí àwọn ìpàdé, ní lílo àtinúdá fúnra rẹ láti múra kí ìdílé bàa lè dé sí ìpàdé lákòókò. Jókòó ti àwọn òbí rẹ nínú ìpàdé, sì tẹ́tísílẹ̀ dáradára nípa fífi ojú bá a lọ nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí a ń kẹ́kọ̀ọ́. Nàgà fún ṣíṣàjọpín nínú àwọn ìpàdé nípa dídáhùn. Fi ara rẹ hàn gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ tí ó múratán nínú Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun, ní títẹ́wọ́gba iṣẹ́ àyànfúnni kí o sì sa gbogbo ipá rẹ láti ṣe é. Yọ̀ǹda ara rẹ láti bójútó àwọn iṣẹ́ láyìíká Gbọ̀ngàn Ìjọba, níbi tí a óò ti nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ. Lílọ́wọ́ sí irú àwọn ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ lè mú ọ pọkànpọ̀ sórí àwọn ohun tí ó dára fún ọ nípa tẹ̀mí.
4 Gbé Góńgó Kalẹ̀ ní Ṣísẹ̀-N-Tẹ̀lé: Nàgà fún ìpín tí ó ṣe gúnmọ́ nínú iṣẹ́-ìsìn pápá, ní fífi ìfẹ́ àtọkànwá hàn fún títóótun gẹ́gẹ́ bí akéde kan. Máa bá Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ lọ tàbí, lọ́nà tí ó túbọ̀ dára sí i, ka Bibeli látòkèdélẹ̀ fúnra rẹ. Pinnu láti dójú ìwọn ohun tí a ń béèrè fún láti ṣe ìyàsímímọ́ àti batisí. Àwọn òbí rẹ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fìṣọ́ra wéwèé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìlànà ẹ̀kọ́ rẹ ní ilé-ẹ̀kọ́, láti baà lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí yóò mú ọ gbaradì fún ìpín kíkún nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa. Pọkànpọ̀ sórí mímú ìfùsì tí yóò sún àwọn ẹlòmíràn láti dámọ̀ràn rẹ fún àǹfààní àkànṣe irú bí iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tàbí iṣẹ́-ìsìn Beteli dàgbà. (Ìṣe 16:1, 2) Lílé àwọn góńgó rẹ bá lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ‘máa wádìí dájú awọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù, kí o lè kún fún èso òdodo.’—Filip. 1:10, 11.
5 Ìgbà èwe jẹ́ àkókò láti kẹ́kọ̀ọ́, láti jèrè ìrírí, àti láti jèrè òye nípa bí a ti ń bá àwọn ẹlòmíràn lò. Ó jẹ́ àkókò tí o lè gbádùn ìgbésí-ayé láìsí gbogbo ìkìmọ́lẹ̀ àti ẹrù-iṣẹ́ tí ń bá àkókò ìgbà àgbà rìn. Solomoni sọ pé: “Máa yọ̀, ìwọ ọ̀dọ́mọdé nínú èwe rẹ; kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó mú ọ lárayá ní ọjọ́ èwe rẹ.” (Oniwasu 11:9) Bí o bá pọkàn rẹ pọ̀ sórí ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa nígbà èwe rẹ, ìwọ yóò ká àwọn ìbùkún tí yóò wà títíláé.—1 Kron. 28:9.
6 Bí o bá “lépa òdodo” dípò “awọn ìfẹ́-ọkàn tí ó sábà máa ń bá ìgbà èwe rìn,” ìwọ kì yóò kó ẹrù ìnira ti àníyàn àti ìrora-ọkàn bá àwọn òbí rẹ. (2 Tim. 2:22) Ìwọ yóò fún ọkàn-àyà ìwọ tìkáraàrẹ ní ìdí láti yọ̀. (Owe 12:25) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìwọ yóò mú ìdùnnú-ayọ̀ wá fún Ẹlẹ́dàá rẹ, Jehofa Ọlọrun.—Owe 27:11.