ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/95 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́-ìsìn Fún August

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́-ìsìn Fún August
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 7
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 14
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 21
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 28
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
km 8/95 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́-ìsìn Fún August

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 7

Orin 118

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a ṣàyàn láti inú Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Pe àfiyèsí sí àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ tí a lè gbé jáde lákànṣe nínú àwọn ìgbékalẹ̀ wa.

15 min: “Irú Ènìyàn Wo Ni Ó Yẹ Kí Ẹ Jẹ́?” Ìbéèrè àti ìdáhùn.

20 min: “Ẹ Jẹ́ Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọrun—Ní Lílo Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ.” Arákùnrin tí a yan apá yìí fún yóò jíròrò onírúurú apá-ẹ̀ka ìwé pẹlẹbẹ náà pẹ̀lú akéde méjì tàbí mẹ́ta mìíràn. Lẹ́yìn náà wọn yóò ṣe ìdánrawò ìgbékalẹ̀ wọn pẹ̀lú ara wọn.

Orin 137 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 14

Orin 124

5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.

10 min: Lo Àkókò Ilé-Ẹ̀kọ́ Lọ́nà Tí Ó Ṣàǹfààní Jùlọ. Alàgbà ṣàṣefihàn bí òbí kan ṣe lè bá ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ ọ̀dọ́langba sọ̀rọ̀ nípa yíyan àwọn ẹ̀kọ́ tàbí iṣẹ́ ní ilé-ẹ̀kọ́. Jíròrò ìdí tí ó fi yẹ láti yan àwọn ẹ̀kọ́ tí yóò ṣèrànlọ́wọ́ nínú lílépa iṣẹ́ ìgbésí-ayé nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà ti November 1, 1992, ojú-ìwé 16 sí 18, ìpínrọ̀ 3 sí 11.

15 min: “Àwọn Òbí Tí Ń Yọ̀!” Ọ̀rọ̀-àsọyé láti ẹnu alàgbà. Fi àlàyé láti inú Ilé-Ìṣọ́nà ti August 15, 1987, ojú-ìwé 13 sí 15, ìpínrọ̀ 14 sí 23 kún un.

15 min: “Ìwà Kristian ní Ilé-Ẹ̀kọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Rọ àwọn òbí láti ṣàyẹ̀wò Ilé-Ìṣọ́nà ti July 15, 1991, ojú-ìwé 23 sí 26, pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, pàápàá jùlọ àwọn apá tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀ràn tí ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ dojúkọ.

Orin 157 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 21

Orin 148

15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Pe àfiyèsí sórí àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó fanimọ́ra lárà ọ̀tọ̀ nínú àwọn ìwé ìròyìn tí ó dé kẹ́yìn. Jíròrò àlàyé tí ó wà ní abẹ́ Ìròyìn Iṣẹ́-Ìsìn April.

10 min: “Àwọn Ìpàdé fún Iṣẹ́-Ìsìn Pápá.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka gbogbo ìpínrọ̀.

20 min: “Tẹ̀lé Ọ̀nà Ìfẹ́ Ti O Tayọ Rekọja.” Ìjíròrò ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà ti July 15, 1992, ojú-ìwé 27 sí 31 láti ẹnu alàgbà.

Orin 156 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 28

Orin 173

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. La ìṣètò fún iṣẹ́-ìsìn pápá ní òpin ọ̀sẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ kí o sì rọ àwùjọ láti fi ìtara-ọkàn ṣètìlẹ́yìn.

15 min: “Ìpadàbẹ̀wò Tí Yóò Yọrí sí Rere Ń Béèrè fún Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Tí Ó Gbéṣẹ́.” Ṣàyẹ̀wò àwọn kókó inú rẹ̀ kí o sì ṣètò fún àṣefihàn kan tàbí méjì.

20 min: Fi Ìwé Walaaye Titilae Lọni ní September. Ṣàlàyé bí ìwé yìí ṣe ń kó ipa pàtàkì nínú jíjíhìn iṣẹ́ ìdájọ́ Jehofa. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà ti April 1, 1988, ojú-ìwé 25 sí 26, ìpínrọ̀ 17 sí 18.) Sọ ìrírí tí ó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti April 1, 1992, ojú-ìwé 15, ìpínrọ̀ 3 sí 4. Pe àfiyèsí sí àwọn àwòrán fífanimọ́ra tí ó fara hàn ní ojú-ìwé 3, 11 sí 13, àti 156 sí 158 nínú ìwé náà. Jíròrò àwọn ọ̀nà tí a lè gbà lo àwọn àwòrán wọ̀nyí láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Jẹ́ kí akéde tí ó dáńgájíá kan ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ kúkúrú kan ní lílo ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ tí ó wà ní ojú-ìwé 156 sí 158. Tẹnumọ́ góńgó gbígbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Rán àwùjọ létí láti gba àwọn ẹ̀dà tí wọn yóò lò ní òpin ọ̀sẹ̀ yìí.

Orin 178 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́