Ìwà Kristian ní Ilé-Ẹ̀kọ́
1 Bí o bá jẹ́ Kristian èwe kan tí ó ṣì wà ní ilé-ẹ̀kọ́, o nílò ìgbàgbọ́ lílágbára láti pa ìwàtítọ́ rẹ mọ́. A ṣí ọ payá sí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ búburú àti àwọn ipò tí ó lè dán ìgbàgbọ́ rẹ wò. Ó ṣe pàtàkì pé kí o fi ìmọ̀ràn Peteru sílò láti ‘tọ́jú ìwà rẹ kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín awọn orílẹ̀-èdè, pé, kí wọ́n lè tipa awọn iṣẹ́ rẹ àtàtà èyí tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí rẹ̀ yin Ọlọrun lógo.’ (1 Pet. 2:12) O nílò ìgboyà àti ìpinnu láti kojú ìpènijà yìí.
2 Nínú ilé-ẹ̀kọ́ tàbí ní òde ilé-ẹ̀kọ́, àwọn ipa ìsọdèérí ti ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbeyàwó, ọ̀rọ̀ rírùn, tábà, àti ìlòkulò oògùn yí ọ ká. Ní ojoojúmọ́, o ń dojúkọ àwọn ìdẹwò tí ń gbìyànjú láti ba àkọsílẹ̀ ìwà rere rẹ jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí àwọn àgbàlagbà, o gbọ́dọ̀ “ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́” bí o bá níláti foríti irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀.—Juda 3; wo Ilé-Ìṣọ́nà ti July 15, 1991, ojú-ìwé 23 sí 26.
3 Ní ilé-ẹ̀kọ́, àwọn ayẹyẹ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọlidé ayé wà. Ìwọ ha mọ àwọn ọlidé orílẹ̀-èdè àti ti ìsìn tí a ń gbé lárugẹ ní ilé-ẹ̀kọ́ rẹ bí? Bí ipò tí ń peni níjà kan bá dìde, ìwọ ha lè ‘di ẹ̀rí-ọkàn rere mú, pé kí ojú lè ti awọn tí ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà rere rẹ’?—1 Pet. 3:16.
4 Ìdẹfàmọ́ra àwọn ìgbòkègbodò ere ìdárayá ní ilé-ẹ̀kọ́ tàbí àwọn ìkẹ́gbẹ́pọ̀ lè dẹ ọ́ wò. O gbọ́dọ̀ wà lójúfò láti mọ̀ bí àwọn ìgbòkègbodò tí ó jọ bí èyí tí ń gbádùn mọ́ni wọ̀nyí ṣe lè fi ìgbàgbọ́ rẹ báni dọ́rẹ̀ẹ́. Àìní wà láti yan àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tí o lè gbádùn “pàṣípààrọ̀ ìṣírí” pẹ̀lú wọn, tí ìgbàgbọ́ ẹnì kìn-ínní ń gbé ìgbàgbọ́ ẹnì kejì ró.—Romu 1:12.
5 O Lè Forítì í, Pẹ̀lú Ìrànlọ́wọ́ Jehofa: Satani ń fi ìgbà gbogbo dán ìgbàgbọ́ rẹ wò. Àwọn ìdánwò tí o gbọ́dọ̀ forítì lè lekoko, ṣùgbọ́n àwọn èrè-ẹ̀san rẹ̀ mú kí gbogbo rẹ̀ tóyeyẹ. (1 Pet. 1:6, 7) O kò lè dá ṣàṣeyọrí nínú fíforítì í; o gbọ́dọ̀ wo Jehofa fún ìrànlọ́wọ́. Jesu rọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má baà bọ́ sínú ìdẹwò.” (Matt. 26:41) Ìbáwí àti ìkóra-ẹni-níjàánu ṣe kókó.—1 Kor. 9:27.
6 Máa fìgbà gbogbo rántí pé ìwọ yóò jíhìn fún Jehofa fún ìwà rẹ. (Oniwasu 11:9) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlòmíràn lè má ṣàkíyèsí ohun tí o ń ṣe, Jehofa mọ ohun tí o ń ṣe, yóò sì ṣe ìdájọ́. (Heb. 4:13) Ìfẹ́-ọkàn olótìítọ́-inú láti ṣe ohun tí ó dùn mọ́ ọn nínú yẹ kí ó sún ọ láti ‘ṣiṣẹ́ ìgbàlà tirẹ yọrí pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì.’ (Filip. 2:12) Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun lojoojúmọ́ jẹ́ ìrànwọ́ ńlá. Ó kún fún ìmọ̀ràn àti àwọn àpẹẹrẹ títayọlọ́lá tí a lè ṣàfarawé.—Heb. 12:1-3.
7 Ẹ̀yin òbí, ẹ ń kó ipa ṣíṣekókó. Ẹ níláti bójútó àwọn ọmọ yín, kí ẹ mọ àwọn ìṣòro tí wọ́n ń dojúkọ, kí ẹ sì pèsè ìrànlọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀. Ẹ ha ní àjùmọ̀ṣepọ̀ tí ó dára pẹ̀lú àwọn ọmọ yín bí? Ẹ ha ti gbin òye onímọrírì fún òfin àti ìlànà Ọlọrun sí wọn lọ́kàn bí? Nígbà tí wọ́n bá dojúkọ ìkìmọ́lẹ̀ tàbí ìdẹwò, àwọn ọmọ yín ha lágbára, tàbí wọ́n tètè máa ń juwọ́ sílẹ̀? Ìrẹ̀wẹ̀sì ha máa ń bá wọn nítorí wọ́n níláti dá yàtọ̀ láàárín àwọn ojúgbà wọn bí? Gẹ́gẹ́ bí òbí, ẹ ní ẹrù-iṣẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Deut. 6:6, 7) Bí ẹ bá ṣe iṣẹ́ yín dáradára, ẹ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jagunmólú nínú ìjà ìgbàgbọ́.—Owe 22:6.