ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/96 ojú ìwé 4
  • Wíwà Láàyè Títí Láé Nínú Paradise Lórí Ilẹ̀ Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwà Láàyè Títí Láé Nínú Paradise Lórí Ilẹ̀ Ayé
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 2/96 ojú ìwé 4

Wíwà Láàyè Títí Láé Nínú Paradise Lórí Ilẹ̀ Ayé

1 Inú gbogbo wá dùn nígbà tí a mú ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye jáde ní 1982. Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ ti sọ, ó ti jẹ́ àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wúlò nínú mímú ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sínú òdodo. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn aláìlábòsí ọkàn ti wá sínú ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́, pẹ̀lú àrànṣe ìwé yìí.—Joh. 8:32.

2 Kí ló jẹ àwọn ènìyàn ní àgbègbè ìpínlẹ̀ wa lógún jù lọ? Kí ni yóò jẹ́ ohun ajẹnilọ́kàn fún ọ̀dọ́ kan? àgbàlagbà kan? ọkọ, aya, tàbí àwọn òbí? Ìmúra sílẹ̀ ṣáájú yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ọ̀pọ̀ ìgbékalẹ̀ yíyàtọ̀ síra, kí á sì múra tán láti yí wọn padà bí a ti ń kíyè sí ìhùwàpadà onílé. Àyẹ̀wò ìwé Reasoning, ní ojú ìwé 9 sí 15, yóò fún wa ní àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó ju 40 lọ, tí a lè lò láti gbé ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kalẹ̀.

3 Láàárín oṣù February, o lè lo ọ̀nà ìyọsíni kan bí èyí:

■ “A ti ń bá díẹ̀ lára àwọn aládùúgbò rẹ sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn ànímọ́ tí wọn yóò fẹ́ kí ẹnì kan tí ń ṣàkóso àwọn ẹlòmíràn ní. Ǹjẹ́ mo lè béèrè irú ànímọ́ kan tàbí méjì tí o rò pé ó fani lọ́kàn mọ́ra? [Jẹ́ kí ó fèsì. Fiyè sí àwọn kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀. Fohùn ṣọ̀kan bí ó bá bá a mu.] Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Bibeli ṣàpèjúwe àwọn ìtóótun Ẹni náà tí a ti tẹ́wọ́ gbà láti jẹ́ olùṣàkóso aráyé? [Ka Isaiah 9:6, 7, kí o sì máa bá a nìṣó.] Báwo ni o rò pé yóò ti rí láti gbé lábẹ́ irú olùṣàkóso bẹ́ẹ̀?” Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà, pe àfiyèsí rẹ̀ sí Orin Dafidi 146:3, 4. Fi àwọn àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 11 sí 13 hàn-án, kí o sì fi ìtẹ̀jáde náà lọ̀ ọ́.

4 Ní títọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú ìròyìn àdúgbò ní lọ́ọ́lọ́ọ́, o lè sọ pé:

■ “O ha gbọ́ ìròyìn nípa [mẹ́nu kan ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó kan àwọn ènìyàn ládùúgbò gbọ̀ngbọ̀n.]? O ha ti ṣe kàyéfì rí nípa ìyípadà tí ń bá ayé yìí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò wa fi hàn pé a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò ìgbékalẹ̀ búburú yìí, àti pé láìpẹ́, Ọlọrun yóò sọ ilẹ̀ ayé di paradise ẹlẹ́wà kan.” Ní ibi tí o dé yìí, gbé ìsọfúnni tí ó wà nínú ìwé Walaaye Titilae, ojú ìwé 150 sí 153 yẹ̀ wò, kí o sì fi ìwé náà lọ̀ ọ́.

5 Bí o bá yàn láti lo ìyọsíni tí ó túbọ̀ rọrùn, o lè lo ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan bí èyí:

■ “Ìwọ yóò ha fẹ́ láti gbé nínú Paradise bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bibeli nawọ́ ìrètí àgbàyanu ti gbígbé nínú Paradise lórí ilẹ̀ ayé títí láé sí gbogbo àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun, tí wọ́n sì fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀. Ìwọ yóò ha fẹ́ láti jẹ́ ọ̀kan nínú wọn bí?” Jẹ́ kí ó fèsì. Ka Owe 10:30, kí o sì tọ́ka onílé sí inú ìwé Walaaye Titilae, orí 19, ojú ìwé 156 sí 158. Lẹ́yìn ṣíṣàlàyé àwọn àwòrán náà, fi ìwé náà lọ̀ ọ́, kí o sì ṣètò fún ìpadàbẹ̀wò.

6 Níbi tí onílé kò bá ti lè san iye owó tí a ń fi ìwé síta, ṣùgbọ́n tí ó fi ọkàn-ìfẹ́ hàn, o lè sọ pé:

■ “Níwọ̀n bí o kò ti ní owó tí o lè san, èmi yóò fẹ́ láti fi ìwé àṣàrò kúkúrú kan sílẹ̀ fún ọ. A pe àkọlé rẹ̀ ní: Igbesi-aye ninu Aye Titun alalaafia kan. Àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ fi bí ìwàláàyè yóò ti rí nínú paradise kan tí a mú padà bọ̀ sípò hàn. Ọ̀fẹ́ ni.” Ka ìpínrọ̀ kan tàbí méjì pẹ̀lú onílé, kí o sì ṣètò fún ìpadàbẹ̀wò.

7 Bí a ti ń fi ìwé náà lọni, a kò gbọdọ̀ gbàgbé láti mú kí àwọn olùfetísílẹ̀ wá mọ àǹfààní tí wọ́n ní láti jẹ láti inú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.—Owe 3:27.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́