ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/96 ojú ìwé 4
  • Pípadà Lọ sí Ọ̀dọ̀ Àwọn Tí Wọ́n Fi Ọkàn-Ìfẹ́ Hàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Pípadà Lọ sí Ọ̀dọ̀ Àwọn Tí Wọ́n Fi Ọkàn-Ìfẹ́ Hàn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 2/96 ojú ìwé 4

Pípadà Lọ sí Ọ̀dọ̀ Àwọn Tí Wọ́n Fi Ọkàn-Ìfẹ́ Hàn

1 Bí ìkìmọ́lẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí ṣe túbọ̀ ń ga sí i lárá àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n dágunlá tẹ́lẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú ìhìn rere. Èyí gbé ìpènijà kan dìde fún gbogbo wa, níwọ̀n bí ìwàláàyè púpọ̀ ti wà nínú ewu. A ha lè ṣètò àwọn àlámọ̀rí wa, kí á sì túbọ̀ fi ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú àwọn ẹni wọ̀nyí bí? (Luku 13:24) Ìrọ̀lẹ́ lè jẹ́ àkókò dídára láti padà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ti fi ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. Rántí pé, láìsí ìpadàbẹ̀wò gbígbéṣẹ́, yóò ṣòro láti sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn, gẹ́gẹ́ bí Oluwa wa Jesu Kristi ti pa á láṣẹ.—Matt. 28:19, 20.

2 Ní ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan tí ó fi ọkàn-ìfẹ́ hàn, ọ̀pọ̀ akéde ti rí i pé ìyọsíni tààràtà yìí dára láti lò:

■ “Ọ̀pọ̀ ènìyàn tí a bá sọ̀rọ̀ ti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí wọ́n ní nínú Bibeli, nípa lílo ìwé yìí.” Lẹ́yìn náà, ní ṣíṣí ìtọ́ka àwọn àkòrí nínú ìwé Walaaye Titilae, o lè béèrè pé: “Kókó ẹ̀kọ́ wo níhìn-ín ni o ní ọkàn-ìfẹ́ sí jù lọ?” Jẹ́ kí ó fèsì. Ṣí i sí orí ìwé tí ẹni náà fi ọkàn-ìfẹ́ hàn sí, kí o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́. Kárí kìkì àwọn kókó díẹ̀, kí o sì ṣètò pàtó láti padà wá.

3 Ní ṣíṣiṣẹ́ lórí ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ níbi tí o ti fi ìwé “Walaaye Titilae” síta, ìwọ́ lè sọ pé:

■ “Nígbà tí mo ṣèbẹ̀wò kẹ́yìn, a jíròrò àwọn ipò ayé tí ń fẹ́ ìyípadà. O ha ti ṣe kàyéfì rí nípa ìdí tí Ọlọrun fí fàyè gba ìwà ibi?” Jẹ́ kí ó fèsì. Ṣí i sí ojú ìwé 99, ìpínrọ̀ 2, ní kíkíyè sí àwọn ìbéèrè ẹ̀kọ́ náà. Ka ìpínrọ̀ yìí, kí o sì jíròrò rẹ̀, ní yíyẹ àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ wò. O lè fi kún ìjíròrò náà nípa gbígbé ìpínrọ̀ méjì sí i yẹ̀ wò.

4 Bí o bá fi ìwé àṣàrò kúkúrú “Igbesi-aye ninu Aye Titun alalaafia kan” sílẹ̀, o lè sọ pé:

■ “Nígbà ìbẹ̀wò wa tí ó kẹ́yìn, a jíròrò bí ìwàláàyè yóò ti rí nínú ayé tuntun alálàáfíà kan. Ìwọ kì yóò ha fẹ́ láti jẹ́ apá kan ayé tuntun Ọlọrun, níbi tí òdodo yóò máa gbé bí?” Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka 2 Peteru 3:13, kí o sì ṣí ìwé àṣàrò kúkúrú náà sí ojú ìwé 3, lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Igbesi-Aye ninu Ayé Titun Ọlọrun,” kí o sì jíròrò ìpínrọ̀ 1 sí 6 níbẹ̀. Bí onílé bá fi ọkàn-ìfẹ́ hàn, fi ìwé Walaaye Titilae hàn án. Fi ìwé náà lọ̀ ọ́ ni iye tí a ń fi síta, kí o sì ṣètò láti máa bá ìjíròrò náà nìṣó nígbà ìbẹ̀wò rẹ tí yóò tẹ̀ lé e.

5 Ǹjẹ́ kí á máa bá a nìṣó láti fí ọkàn-ìfẹ́ hàn sí àwọn ènìyàn ní àgbègbè ìpínlẹ̀ wa, ní títipa báyìí fi hàn pé a ń bomi rin ohun ọ̀gbìn ẹlẹgẹ́ ti ìgbàgbọ́ Kristian tí a fi sítọ̀ọ́jú wa. Bí a ti ń fi ìṣòtítọ́ ṣe èyí, a lè ní ìgbọ́kànlé pé Ọlọrun yóò mú un dàgbà sí ìyìn àti ògo rẹ̀.—1 Kor. 3:7.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́