ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/96 ojú ìwé 1
  • Fi Ìbùkún fún Jehofa “ní Gbogbo Ọjọ́”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Ìbùkún fún Jehofa “ní Gbogbo Ọjọ́”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Yin Jèhófà Lójoojúmọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Sọ Fáwọn Ẹlòmíràn Nípa “Ìmọ́lẹ̀ Ayé”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Jèhófà Yẹ fún Ìyìn Gidigidi
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • “Wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ní Kíkún”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 3/96 ojú ìwé 1

Fi Ìbùkún fún Jehofa “ní Gbogbo Ọjọ́”

1 Nínú Orin Dafidi 145:2 (NW), Ọba Dafidi ṣèlérí fún Jehofa pé: “Ní gbogbo ọjọ́, èmi óò máa fi ìbùkún fún ọ, èmi óò sì máa yin orúkọ rẹ fún àkókò títí lọ gbére, àní títí láé.” Àwa pẹ̀lú ní ìdí láti fi ìbùkún fún Bàbá wa ọ̀run, kí á sì yìn ín! Ṣùgbọ́n, báwo ni a ṣe lè fara wé àpẹẹrẹ Dafidi nínú gbígbé ipò ọba aláṣẹ Jehofa ga “ní gbogbo ọjọ́”?

2 Fífi Ìmọrírì fún Jehofa Kún Ọkàn-Àyà Wa: Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun déédéé ń mú kí ìmọrírì wá jinlẹ̀ sí i fún ohun tí Jehofa ti ṣe, fún ohun tí ó ń ṣe, àti fún ohun tí yóò ṣe fún wa. Bí a ti ń mú ìmọrírì dàgbà fún àwọn ìṣe àgbàyanu rẹ̀, a óò máa fọ̀yàyà sọ̀rọ̀ ìwà rere rẹ̀ káàkiri. (Orin Da. 145:7) A óò máa fi ìháragàgà yin Jehofa ní gbogbo àkókò yíyẹ.

3 Yin Jehofa Nínú Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ Ojoojúmọ́: Nígbà tí a bá ń bá àwọn aládùúgbò, ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni, òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni, àti àwọn mìíràn tí a ń bá pàdé lójoojúmọ́ sọ̀rọ̀, a lè ní àǹfààní láti ṣàjọpín ìrètí wa pẹ̀lú wọn. Aládùúgbò kan lè sọ àníyàn rẹ̀ jáde nípa ìwà ọ̀daràn ní àgbègbè náà; ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni lè ṣàníyàn nípa ìjoògùnyó tàbí ìwà pálapàla; òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni lè sọ èrò kan nípa ọ̀ràn ìṣèlú. A lè tọ́ka sí àwọn ìlànà àti ìlérí tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí ń fi ipa ọ̀nà tí a ní láti tọ̀ nísinsìnyí àti àtúnṣe ìkẹyìn sí àwọn ìṣòro wọ̀nyí hàn. Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, tí a sọ ní “àkókò tí ó tọ́” lè jẹ́ ìbùkún!—Owe 15:23, NW.

4 Sọ̀rọ̀ Nípa Jehofa fún Àkókò Kíkún: Ẹni tí ó ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún Jehofa ń fẹ́ láti ṣàjọpín ìhìn rere náà pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ẹlòmíràn bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (Orin Da. 40:8-10) Lórí èyí, ó yẹ kí á bi ara wa pé, ‘Mo ha ń ṣe gbogbo ohun tí àyíká ipò mí gbà mí láyè láti ṣe bí?’ Ọ̀pọ̀ ti rí i pé, pẹ̀lú ìyípadà díẹ̀ tí ó mọ́gbọ́n dání, ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti di aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bí àyíká ipò lọ́ọ́lọ́ọ́ kò bá fi àyè gba ìyẹn, a ha lè forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ bí? Níwọ̀n bí ìgbà Ìṣe Ìrántí tí ń bọ̀ ti jẹ́ àkókò láti mú ìgbòkègbodò wa gbòòrò sí i, oṣù March àti April yóò jẹ́ àkókò tí ó dára láti mú iṣẹ́ ìsìn wa pọ̀ sí i nípa ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

5 Ran Àwọn Ẹni Tuntun Lọ́wọ́ Láti Dara Pọ̀ Mọ́ Wa Nínú Fífi Ìbùkún fún Jehofa: Ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Jesu máa ń rán wa létí nígbà gbogbo nípa ìdí tí a fi ní láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa, kí a sì yin orúkọ Rẹ̀. Èyí jẹ́ àkókò tí ó dára ní pàtàkì láti fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wa níṣìírí láti dara pọ̀ mọ́ wa nínú sísọ̀rọ̀ nípa ipò ọba Jehofa ní gbangba. Rọ̀ wọ́n láti fi tàdúràtàdúrà ronú lórí ohun tí ó wà ní ìpínrọ̀ 7 sí 9 ní ojú ìwé 173 sí 175 nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Bí wọ́n bá tóótun, kò sí ìdí fún wọn láti fà sẹ́yìn nínú wíwàásù nítorí pé wọn kò nírìírí. Àwọn akéde dídáńgájíá wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti fi bí a ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà hàn wọ́n. Bí àwọn ẹni tuntun bá lè lo ìgboyà láti sọ ìhìn rere náà, wọ́n lè nígbọkànlé pé Jehofa yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.—Ìṣe 4:31; 1 Tessa. 2:2.

6 A ń mú àǹfààní ayérayé wá fún ara wa àti fún àwọn ẹlòmíràn nígbà tí a bá ń wá ọ̀nà láti fi ìbùkún fún Jehofa ní gbogbo ọjọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́