Jèhófà Yẹ fún Ìyìn Gidigidi
A Óò Ṣe Ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ní April 16
1 À ń wọ̀nà lójú méjèèjì fún dídé April 16, 2003. Lálẹ́ ọjọ́ náà ni a óò ṣe ayẹyẹ ikú Jésù, tí a óò dara pọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa káàkiri ayé ní yíyin orúkọ Jèhófà lógo. Jèhófà yẹ fún gbogbo ìyìn wa nítorí àgbàyanu ẹ̀bùn ìràpadà tó fún wa. Nípasẹ̀ ẹ̀bùn yìí, yóò mú àwọn ìbùkún àgbàyanu wá sórí gbogbo aráyé onígbọràn. Tọkàntọkàn la fi dara pọ̀ mọ́ onísáàmù náà ní sísọ pé: “Jèhófà tóbi, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi.”—Sm. 145:3.
2 Àkókò Ìṣe Ìrántí jẹ́ àkókò fún ṣíṣàṣàrò lórí oore Ọlọ́run àti gbèsè ọpẹ́ tá a jẹ Jèhófà fún rírán tó rán “Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo . . . sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.” (1 Jòhánù 4:9, 10) Ṣíṣègbọràn sí àṣẹ náà láti ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa lọ́kàn pé, “Jèhófà jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú . . . ó sì pọ̀ ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” (Sm. 145:8) Láìsí àní-àní, ìràpadà náà ni ìfẹ́ tó ga jù lọ tí Jèhófà fi hàn sí ọmọ aráyé. (Jòhánù 3:16) Nígbà tá a bá ronú nípa ìfẹ́ Ọlọ́run tá a sì ṣàṣàrò lórí bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́ àti adúróṣinṣin, èyí á sún wa láti yin Jèhófà. Títí ayé la óò máa yin Jèhófà fún ìfẹ́ tí kò láàlà tó fi hàn sí wa nípa mímú kí ìyè ayérayé ṣeé ṣe fún wa.—Sm. 145:1, 2.
3 Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Yin Jèhófà: Ìmọrírì fún ẹ̀bùn tó ga jù lọ tí Ọlọ́run fún wa, ìyẹn ìpèsè ìràpadà náà, ló ń sún wa láti ké sí àwọn mìíràn láti dara pọ̀ mọ́ wa nínú yíyin Jèhófà. Ọlọ́run mí sí onísáàmù náà láti kọ̀wé pé: “Wọn yóò máa fi ọ̀yàyà sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ yanturu oore rẹ, wọn yóò sì fi ìdùnnú ké jáde nítorí òdodo rẹ.” (Sm. 145:7) Lọ́dún tó kọjá nìkan, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé lo ohun tó lé ní bílíọ̀nù kan wákàtí nínú iṣẹ́ ìwàásù. Kí ni àbájáde ìsapá wa? Ní ìpíndọ́gba lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé ọgọ́rùn-ún [5,100] èèyàn là ń batisí, gẹ́gẹ́ bí àmì ìyàsímímọ́ wọn fún Jèhófà. Pẹ̀lú àròpọ̀ èèyàn tó jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ọ̀kẹ́ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́rìndínláàádọ́ta [15,597,746] tó wá sí Ìṣe Ìrántí, èyí tí àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn-án tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í yin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí akéde ìhìn rere wà lára wọn, ó fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí àwọn olùjọsìn Jèhófà pọ̀ sí i lọ́jọ́ iwájú! Gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba, a mọrírì àǹfààní tá a ní láti máa kéde ìhìn rere náà àti láti máa darí ọkàn àwọn ẹlòmíràn sọ́dọ̀ Jèhófà, sọ́dọ̀ Ọmọ rẹ̀ àti sí Ìjọba rẹ̀.
4 Ọ̀nà dídára kan láti rọ àwọn mìíràn láti bọlá fún Jèhófà ni kíké sí wọn láti dara pọ̀ mọ́ wa láti ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Ṣé o ti ṣàkọsílẹ̀ orúkọ gbogbo àwọn tó o fẹ́ ké sí àtàwọn mìíràn tó máa pọn dandan pé kó o rán létí ọjọ́ àti àkókò náà? Ṣé o ti fún gbogbo àwọn tó o kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ní ìwé ìkésíni? Bí o kò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀, sapá láti rí i pé o ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìwọ̀nba àkókò tó kù. Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí a fi ń ṣe ayẹyẹ náà. Níbi ayẹyẹ náà, wà ní ìmúrasílẹ̀ láti kí àwọn àlejò tó bá wá dáadáa. Mú kí ara tù wọ́n, fi wọ́n han àwọn ẹlòmíràn, kó o sì yìn wọ́n fún wíwá tí wọ́n wá.
5 Wíwá sí Ìṣe Ìrántí lè mú kí àwọn ẹni tuntun tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó máa ń ní ìpayà nítorí ìrírí bíbanilẹ́rù tó ti ní, èyí tó máa ń mú kó ṣòro gan-an fún un láti wà níbi tí èrò bá pọ̀ sí, wá sí Ìṣe Ìrántí. Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé báwo ló ṣe rí ìpàdé náà sí, ó sọ pé: “Alẹ́ mímọ́ gbáà ni, mo sì láyọ̀ láti wà níbẹ̀.” Látìgbà náà ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé.
6 Lẹ́yìn Ìṣe Ìrántí: Kí la lè ṣe láti ran àwọn olùfìfẹ́hàn wọ̀nyí lọ́wọ́ láti di olùyin Jèhófà? Àwọn alàgbà yóò ṣàkíyèsí àwọn ẹni tuntun tó wá sí Ìṣe Ìrántí, wọn yóò sì ṣètò kí àwọn akéde tó tóótun bẹ̀ wọ́n wò kété lẹ́yìn ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí náà láti ṣàtúnyẹ̀wò àwọn nǹkan atunilára tí wọ́n gbọ́ tí wọ́n sì rí pẹ̀lú wọn. Àwọn kan lè nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Ó tún yẹ ká ké sí wọn láti máa wá sí gbogbo ìpàdé ìjọ tí à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, níwọ̀n bí wíwá déédéé yóò ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ìmọ̀ Bíbélì wọn pọ̀ sí i.
7 À ń ṣètò láti ran gbogbo àwọn akéde aláìṣedéédéé àtàwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́ láti máa wá sí ìpàdé déédéé. Bí àwọn alàgbà bá ké sí ọ láti ran ẹnì kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́ láti tún bẹ̀rẹ̀ sí jáde òde ẹ̀rí padà, múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀. Fífi irú àníyàn onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn sí àwọn arákùnrin wa ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìyànjú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, èyí tó sọ pé: “Níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.”—Gál. 6:10.
8 Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa ṣe àkànṣe ìsapá láti wà ní ibi Ìṣe Ìrántí ní April 16. A ò ní fẹ́ láti ṣàìwá síbi ayẹyẹ mímọ́ jù lọ yìí láti yin Jèhófà. Bẹ́ẹ̀ ni, nísinsìnyí àti títí láé, ẹ jẹ́ ká máa yin Jèhófà fún àwọn arabaríbí iṣẹ́ rẹ̀!—Sm. 145:21.