Sọ Fáwọn Ẹlòmíràn Nípa “Ìmọ́lẹ̀ Ayé”
1. Ìmọ́lẹ̀ ńlá wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló sì máa jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ mọ̀ nípa ìmọ́lẹ̀ yìí?
1 Jèhófà gba ẹnu wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ní ti àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ibú òjìji, àní ìmọ́lẹ̀ ti tàn sórí wọn.” (Aísá. 9:2) “Ìmọ́lẹ̀ ńlá” yẹn ṣe kedere nínú iṣẹ́ Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run. Iṣẹ́ tó ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé àti ìbùkún tí ikú ìrúbọ tó kú mú wá ló yọ àwọn tí ò mọ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn. Irú ìmọ́lẹ̀ yẹn làwọn èèyàn nílò lásìkò tí òkùnkùn bo ayé yìí. Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa jẹ́ àkókò tó dáa jù lọ fún wa láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa “ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Jòh. 8:12) Lọ́dún tó kọjá, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ dé ìwọ̀n àyè kan nípa bí wọ́n ṣe dara pọ̀ mọ́ wa láti tẹ̀lé àṣẹ Jésù pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Bí Ìrántí Ikú Kristi ọdún yìí ṣe ń sún mọ́, ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa ìmọ́lẹ̀ ńlá tí Jèhófà ń mú kó máa tàn?—Fílí. 2:15.
2. Báwo la ṣe lè mú kí ọkàn wa túbọ̀ mọrírì ẹbọ ìràpadà, kí nìyẹn á sì sún wa láti ṣe?
2 Ẹ Ní Ìmọrírì Àtọkànwá: Àkókò tó dáa láti ṣàṣàrò lórí ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sí aráyé nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà ni àkókò Ìrántí Ikú Kristi. (Jòh. 3:16; 2 Kọ́r. 5:14, 15) Ó dájú pé bá a bá ṣe àṣàrò lọ́nà bẹ́ẹ̀, a ó lè túbọ̀ mọrírì ìṣẹ̀lẹ̀ mímọ́ yẹn. Gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run ló yẹ kó ṣètò àkókò láti ka àkànṣe Bíbélì kíkà fún Ikú Ìrántí Kristi gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ̀ nínú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ kí wọ́n sì ṣàṣàrò lé e lórí. Ríronú lórí àwọn ànímọ́ Jèhófà tí kò lẹ́gbẹ́, èyí tó hàn nípa bó ṣe pèsè ẹbọ ìràpadà lọ́nà gíga lọ́lá, tó ohun tó yẹ ká tìtorí rẹ̀ máa yangàn pé òun ni Ọlọ́run wa. Ṣíṣàṣàrò lórí oore tí ìràpadà náà ṣe wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan á jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀, á sì sún wa láti fi gbogbo okun wa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—Gál. 2:20.
3. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì Ìṣe Ìrántí?
3 Bá a bá jẹ́ kí ìmọrírì tá a ní fún ìpèsè tí Jèhófà ṣe láti fún wa ní ìgbàlà jinlẹ̀, ìtara tá a ní fún Ìrántí Ikú Kristi á ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa, àwọn tá à ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn, àwọn aládùúgbò wa, àwọn tá a jọ wà nílé ẹ̀kọ́, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn míì tá a pè wá síbi àkànṣe ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. (Lúùkù 6:45) Nítorí náà, sa gbogbo ipá rẹ láti pe àwọn èèyàn yìí síbẹ̀, nípa fífún wọn níwèé ìkésíni tá a tẹ̀ kí wọ́n má bàa gbàgbé. Kí àwọn ará kan má bàa gbàgbé orúkọ èyíkéyìí, wọ́n máa ń kọ orúkọ ẹni tí wọ́n máa ń pè wá síbi Ìrántí Ikú Kristi sínú ìwé kan, lọ́dọọdún ni wọ́n sì máa ń fi orúkọ àwọn ẹni tuntun kún un. Ṣíṣe àwọn nǹkan tá a sọ yìí létòlétò àti ṣíṣe gbogbo ohun tó yẹ láti ké sí àwọn tó fìfẹ́ hàn jẹ́ ọ̀nà kan tó dáa láti gbà fi ìmọrírì tá a ní hàn fún “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ . . . aláìṣeé-ṣàpèjúwe” tí Jèhófà Ọlọ́run fún wa.—2 Kọ́r. 9:15.
4. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi kún ohun tá à ń ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lóṣù March àti April?
4 Lílo Àkókò Tó Pọ̀ Sí I Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́: Ṣó o máa fi kún àkókò tó ò ń lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lóṣù March àti April? Ó dájú pé Ọlọ́run á tì wá lẹ́yìn bá a ṣe ń sapá láti wàásù “ìhìn rere ológo nípa Kristi.” Jèhófà, Orísun gbogbo ìlàlóye tá à ń rí látinú Bíbélì, pàṣẹ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn.” (2 Kọ́r. 4:4-6) Bó bá yẹ, kí àwọn alàgbà ṣètò fún ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá láwọn àkókò mìíràn àti láwọn ibi tó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀. Kí wọ́n máa fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa ṣíṣètìlẹyìn fún àwọn ará tó bá fẹ́ láti lo àkókò tó pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Wọ́n lè ṣètò fún wíwàásù láwọn òpópónà lọ́wọ́ ìdájí tàbí wíwàásù láti ilé dé ilé lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa wà nílé. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti fi kún àkókò tó ò ń lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, bu iye wákàtí tó o mọ̀ pé o lè bá, kó o sì sakun láti lé e bá. Ohun tí ọ̀pọ̀ máa ń ṣe láti fún Jèhófà ní ohun tó dára jù lọ ni ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.—Kól. 3:23, 24.
5. Àǹfààní wo ni ọ̀pọ̀ ti jẹ látinú dídín tá a dín iye wákàtí tá a retí pé káwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ máa ròyìn kù?
5 Ṣé Ìwọ Náà Á Ṣe Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́? Ó ti lè lọ́dún méje báyìí tá a ti dín iye wákàtí tá a retí pé káwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ máa ròyìn kù. Àtúnṣe yìí ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti rí ayọ̀ àti àǹfààní tó wà nínú ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ǹjẹ́ ìwọ náà ti gbìyànjú rẹ̀ rí? Àwọn kan ti sọ ọ́ dàṣà láti máa ṣe é lọ́dọọdún. Láwọn ìjọ kan, ṣe làwọn akéde máa ń gba fọ́ọ̀mù ìwọṣẹ́ náà sígbà kan náà, èyí sì máa ń jẹ́ ọ̀kan lára ìgbòkègbodò ìjọ tó máa ń ṣe ìjọ láǹfààní gan-an lọ́dún iṣẹ́ ìsìn yẹn. Ṣé ìwọ náà á lè wá àyè fún oṣù kan láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tó ń fúnni láyọ̀ lákòókò Ìrántí Ikú Kristi? Ó lè jẹ́ oṣù April ló máa dáa jù fáwọn kan nítorí òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún tó wà nínú rẹ̀.
6. Ìṣètò tó lárinrin wo ló ti wà ní sẹpẹ́?
6 Àbí oṣù March tàbí April ni alábòójútó àyíká máa bẹ ìjọ yín wò? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, àfikún àǹfààní gidi nìyẹn o. Gẹ́gẹ́ bá a ti ṣèfilọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2006, gbogbo àwọn tó bá ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láàárín oṣù tí alábòójútó àyíká bá bẹ ìjọ wọn wò ló máa ní àǹfààní láti gbádùn apá àkọ́kọ́ ìpàdé tí wọ́n máa bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà ṣe. Kò síyè méjì pé ọ̀rọ̀ tí ń fún ìgbàgbọ́ lágbára tí wọ́n á bá àwọn tó wà nípàdé náà sọ á ṣèrànwọ́ fáwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Láfikún sí i, a óò láyọ̀ lóṣù March bá o ṣe máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ojú wọn là sí ìmọ́lẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tuntun náà Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? O ò ṣe pinnu láti bẹ̀rẹ̀ sí fi ìwé tuntun náà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
7, 8. (a) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣètò fún ṣíṣẹ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́? (b) Àǹfààní wo ló wà nínú kí ìdílé fọwọ́ sowọ́ pọ̀, oore wo ló sì ṣe fún ìdílé kan lápapọ̀?
7 Bó o ṣe ń ronú lórí àádọ́ta wákàtí tá a ń retí pé káwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ máa ròyìn, mọ ètò tó o lè ṣe tó máa jẹ́ kó o lè máa tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ kiri fún nǹkan bí wákàtí méjìlá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn tó ti ṣiṣẹ́ ọ̀hún láṣeyọrí àtàwọn míì. Èyí lè fún wọn níṣìírí láti dara pọ̀ mọ́ ẹ. Àwọn akéde lọ́mọdé lágbà tó ti ṣèrìbọmi ti rí i pé táwọn bá ṣètò tó mọ́yán lórí, kò fi bẹ́ẹ̀ nira láti mú ìpinnu tó dáa yìí ṣẹ. Fi sínú àdúrà. Lẹ́yìn náà, bó bá ṣeé ṣe fún ọ, ṣètò tó yẹ, wàá sì rí i pé iṣẹ́ olóyinmọmọ ni iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́!—Mál. 3:10.
8 Ọ̀pọ̀ ìdílé ló ti rí i pé bí ìdílé bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, ó kéré tán, ẹnì kan nínú ìdílé lè ṣe iṣẹ́ náà. Ìdílé kan tiẹ̀ pinnu pé àwọn márààrún tí wọ́n ti ṣèrìbọmi nínú ìdílé náà ló máa ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Àwọn ọmọ méjì tí ò tíì ṣèrìbọmi ṣètò àkànṣe kan láti fi kún ìgbòkègbodò tiwọn náà. Àǹfààní wo ni ìdílé yìí rí látinú ìsapá àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n ṣe yìí? Wọ́n sọ pé: “Oṣù alárinrin gbáà ni, a sì rí i pé ó túbọ̀ mú kí ìdílé wa wà níṣọ̀kan. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìbùkún ńlá yìí!”
9. Ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa tàn lákòókò Ìṣe Ìrántí yìí?
9 Ǹjẹ́ àkànṣe ìgbòkègbodò tá a fẹ́ ṣe lóṣù March àti April á ru wá sókè, ṣé á sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ Baba wa ọ̀run? Bá a ṣe máa ṣàṣeyọrí tó sinmi lórí bí àwa fúnra wa bá ṣe sapá tó láti túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ tá a sì fi kún ohun tá à ń ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ǹjẹ́ kí ìpinnu wa dà bíi ti onísáàmù náà, ẹni tó kọrin pé: “Èmi yóò fi ẹnu mi gbé Jèhófà lárugẹ gidigidi, èmi yóò sì máa yìn ín láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Sm. 109:30) Jèhófà yóò bá wa lọ́wọ́ sí ìgbòkègbodò tá à ń fi ìtara ṣe lákòókò Ìrántí Ikú Kristi yìí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa tan ìmọ́lẹ̀ ńlá náà nìṣó káwọn púpọ̀ sí i lè kúrò nínú òkùnkùn kí wọ́n sì “ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”—Jòh. 8:12.