Sáàmù
Sí olùdarí. Ti Dáfídì. Orin.
109 Ìwọ Ọlọ́run tí mò ń yìn,+ má ṣe dákẹ́.
2 Nítorí àwọn ẹni burúkú àti àwọn ẹlẹ́tàn ń la ẹnu wọn sí mi.
Wọ́n ń fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ nípa mi;+
3 Wọ́n yí mi ká, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ìkórìíra sí mi,
Wọ́n ń bá mi jà láìnídìí.+
4 Mo nífẹ̀ẹ́ wọn, àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń ta kò mí;+
Síbẹ̀ mi ò dákẹ́ àdúrà.
6 Yan ẹni burúkú lé e lórí;
Kí alátakò* dúró sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
9 Kí àwọn ọmọ* rẹ̀ di aláìníbaba,
Kí ìyàwó rẹ̀ sì di opó.
10 Kí àwọn ọmọ* rẹ̀ máa tọrọ nǹkan kiri,
Kí wọ́n sì máa jáde látinú ilé wọn tó ti di ahoro lọ wá oúnjẹ.
11 Kí ẹni tó jẹ ní gbèsè gbẹ́sẹ̀ lé* gbogbo ohun tó ní,
Kí àwọn àjèjì sì kó ohun ìní rẹ̀.
12 Kí ẹnikẹ́ni má ṣe nawọ́ oore* sí i,
Kí ẹnikẹ́ni má sì ṣojú rere sí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò ní bàbá.
14 Kí Jèhófà rántí àṣìṣe àwọn baba ńlá rẹ̀,+
Kí ẹ̀ṣẹ̀ ìyá rẹ̀ má sì pa rẹ́.
15 Kí Jèhófà máa rántí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe;
Kí ó sì pa ìrántí wọn rẹ́ kúrò ní ayé.+
17 Ó fẹ́ràn kó máa gégùn-ún, ohun tó sì dà lé e lórí nìyẹn;
Kì í fẹ́ súre, torí náà, kò rí ìbùkún kankan gbà.
18 Ó gbé ègún wọ̀ bí aṣọ.
Ó dà sínú ara rẹ̀ bí omi,
Ó sì wọnú egungun rẹ̀ bí òróró.
19 Kí ègún wé mọ́ ọn bí aṣọ tó ń wọ̀+
Àti bí àmùrè tó ń dè nígbà gbogbo.
21 Àmọ́ ìwọ, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ,
Gbèjà mi nítorí orúkọ rẹ.+
Gbà mí sílẹ̀, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára.+
23 Mò ń kọjá lọ bí òjìji tó ń pa rẹ́ lọ;
Wọ́n ti gbọ̀n mí dà nù bí eéṣú.
24 Àwọn eékún mi ti yẹ̀ nítorí ààwẹ̀ gbígbà;
Mo ti rù, mo sì ń kú lọ.*
25 Mo ti di ohun tí wọ́n fi ń ṣe yẹ̀yẹ́.+
Tí wọ́n bá rí mi, ṣe ni wọ́n ń mi orí.+
26 Ràn mí lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run mi;
Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ gbà mí.
27 Kí wọ́n mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ló ṣe èyí;
Pé ìwọ, Jèhófà, ló ṣe é.
28 Kí wọ́n gégùn-ún, àmọ́ ṣe ni kí o súre fún mi.
Tí wọ́n bá dìde sí mi, jẹ́ kí ojú tì wọ́n,
Àmọ́ kí ìránṣẹ́ rẹ máa yọ̀.
30 Ẹnu mi á máa yin Jèhófà gidigidi;
Màá máa yìn ín níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn.+