ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/97 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún March

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún March
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 3
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 10
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 17
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 24
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 31
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 3/97 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún March

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 3

Orin 53

15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti bẹ̀rẹ̀ sí í ké sí àwọn olùfìfẹ́hàn sí Ìṣe Ìrántí ní March 23. Fi ẹ̀dà ìkésíni sí Ìṣe Ìrántí kan hàn, kí o sì rọ gbogbo àwùjọ láti gba mélòó kan kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pín wọn ní ọ̀sẹ̀ yí.

10 min: “Ìrànlọ́wọ́ Ní Àkókò Tí Ó Tọ́.” Pe àfiyèsí sí àpilẹ̀kọ yìí, kí o sì tọ́ka sí àwọn kókó pàtàkì tí ó wúlò gidigidi láti inú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìtẹ̀jáde tuntun náà.

20 min: “Ríran Àwọn Ìdílé Lọ́wọ́ Láti Ní Ọjọ́ Ọ̀la Wíwà Pẹ́ Títí.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 5) Sọ̀rọ̀ ṣókí lórí ìpínrọ̀ 1, lẹ́yìn náà, kí o jíròrò bí a ṣe lè mú ọkàn ìfẹ́ dàgbà nínú ìwé Ayọ̀ Ìdílé nípa lílo àwọn àkòrí orí ìwé, àwọn àwòrán tí ó jojú ní gbèsè, àti àwọn àpótí àtúnyẹ̀wò. Jẹ́ kí àwọn akéde dídáńgájíá ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ tí ó wà ní ìpínrọ̀ 2 sí 5. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti ṣe àkànṣe ìsapá láti fi ìwé náà sóde lọ́dọ̀ àwọn ìdílé tí wọ́n ti fi ọkàn ìfẹ́ hàn ní ìṣáájú.

Orin 71 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 10

Orin 56

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàyẹ̀wò “Àwọn Ìránnilétí Ìṣe Ìrántí.” Rán gbogbo àwùjọ létí láti rí i dájú pé wọ́n tẹ̀ lé Bíbélì kíkà fún Ìṣe Ìrántí tí a ṣètò fún March 18 sí 23, gẹ́gẹ́ bí a ti tò ó lẹ́sẹẹsẹ nínú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́.

20 min: ‘Ẹ Fi Ara Yín Hàn Ní Ẹni Tí Ó Kún fún Ọpẹ́.’ Ìbéèrè àti ìdáhùn. Gbogbo àwùjọ gbọ́dọ̀ sapá tọkàntọkàn láti ké sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn olùfìfẹ́hàn, àwọn mẹ́ńbà ìdílé tí ó bá tẹ́wọ́ gbà wá, àti èyíkéyìí lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí kì í fi ìtara dara pọ̀ mọ́ ìjọ, láti wá sí Ìṣe Ìrántí. Àṣefihanni ṣókí nípa akéde kan tí ń ké sí olùfìfẹ́hàn sí Ìṣe Ìrántí ní lílo ìkésíni sí Ìṣe Ìrántí. Fi ọ̀rọ̀ ìlóhùnsí kún un lórí Ilé-Ìṣọ́nà July 1, 1988, ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 16 sí 17. Rọ gbogbo àwọn tí ó bá lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní April àti May láti ṣe bẹ́ẹ̀.

15 min: “Ríran Àwọn Ìdílé Lọ́wọ́ Láti Ní Ọjọ́ Ọ̀la Wíwà Pẹ́ Títí.” (Ìpínrọ̀ 6 sí 8) Fúnni ní àwọn àbá díẹ̀ tí ń fi bí a ṣe lè fi ìwé Ayọ̀ Ìdílé lọni hàn nígbà tí a bá ń ṣe ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà lẹ́nu iṣẹ́, ní ilé ẹ̀kọ́, níbi ọgbà ìtura, tàbí nínú ọkọ̀ èrò, títí kan ìgbà tí a bá ń ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí. Jẹ́ kí akéde kan tí ó dáńgájíá ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ tí ó wà ní ìpínrọ̀ 6 àti 7. Ìjíròrò nígbà ìpadàbẹ̀wò yẹ kí ó ran ẹni náà lọ́wọ́ láti mọrírì bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lè fún ìdè ìdílé lókun. A ní láti darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, pẹ̀lú ète sísọdá sínú ìwé Ìmọ̀, tàbí a lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nínú ìwé Ìmọ̀ fúnra rẹ̀.

Orin 72 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 17

Orin 63

15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó. Sọ àwọn ìṣètò tí ìjọ ṣe fún Ìṣe Ìrántí. Gbogbo àwùjọ gbọ́dọ̀ ṣe ìwéwèé àṣekágbá láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn olùfìfẹ́hàn lọ́wọ́ láti wà níbẹ̀.

15 min: Àwọn àìní àdúgbò. Tàbí ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà kan lórí àpilẹ̀kọ náà, “Ó Ha Yẹ Kí O Tọrọ Àforíjì Ní Tòótọ́ Bí?” láti inú Ilé Ìṣọ́ September 15, 1996, ojú ìwé 22 sí 24.

15 min: “Gbé Agbo Ilé Rẹ Ró.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àwọn ìrírí láti inú ìwé 1995 Yearbook, ojú ìwé 228 kún un.

Orin 75 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 24

Orin 67

9 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàlàyé pé kò tí ì pẹ́ jù láti fi ìwé ìbéèrè fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní April sílẹ̀. Sọ àfikún ìṣètò tí ìjọ ti ṣe fún àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn nínú oṣù náà.

24 min: “Máyà Le Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 20) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàṣefihàn ìpínrọ̀ 16 ní ṣókí.

12 min: Ríran Akéde Tuntun Kan Lọ́wọ́ Láti Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́. Ṣàtúnyẹ̀wò ìpínrọ̀ 19 nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996. Ṣàṣefihàn bí akéde dídáńgájíá kan ṣe ń múra akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí àwọn alàgbà ṣẹ̀ṣẹ̀ fọwọ́ sí láti di akéde tí kò ti ṣe batisí sílẹ̀. Wọ́n ṣe àyẹ̀wò ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 111, ìpínrọ̀ 2 pa pọ̀. Akéde tí ó ti ní ìrírí sọ àwọn ohun tí ó ṣeé ṣe láti bá pàdé nígbà tí ó bá ń ṣàjọpín nínú ìjẹ́rìí ilé dé ilé àti pé kò sí ìdí láti jọ̀gọ̀nù bí ọ̀pọ̀ jù lọ kò bá dáhùn pa dà lọ́nà rere. Akéde sọ ìrírí tí ń fúnni níṣìírí tí ń fi ayọ̀ tí a ń rí hàn nígbà tí a bá rí ẹnì kan tí ó jẹ́ olótìítọ́ inú tí yóò fetí sílẹ̀. Wọ́n múra ìgbékalẹ̀ ìfilọni ìwé ìròyìn rírọrùn, tí ó ṣe ṣókí, pa pọ̀, wọ̀n sì fi dánra wò lẹ́yìn náà. Ó gbóríyìn fún un lọ́nà tí ó fún un níṣìírí, wọ́n sì ṣètò pàtó láti nípìn-ín pa pọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́sẹ̀ yí.

Orin 89 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 31

Orin 70

15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ké sí gbogbo àwọn olùfìfẹ́hàn láti wá sí àkànṣe ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn ní April 6. Rán gbogbo àwùjọ létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn fún March sílẹ̀. Kéde orúkọ gbogbo àwọn tí yóò ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní April. Ṣàyẹ̀wò Àpótí Ìbéèrè.

20 min: “Máyà Le Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò.” (Ìpínrọ̀ 21 sí 35) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàyẹ̀wò àpótí tí ó wà ní ojú ìwé 3. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti ka gbogbo ìpadàbẹ̀wò tí wọ́n ṣe nínú oṣù náà nígbà tí wọ́n bá ń ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn.

10 min: Ṣàyẹ̀wò Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Àfilọni fún April. Fi àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ lọni. Bí a kò bá gba àsansílẹ̀ owó, fi àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni. Ní ṣókí, sọ àwọn àbá lórí bí a ṣe lè múra àwọn ìgbékalẹ̀ ìwé ìròyìn sílẹ̀, èyí tí ó fara hàn ní ìpínrọ̀ 3, 4, àti 8 ní ojú ìwé 8 Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1996. Jẹ́ kí àwọn akéde méjì ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ kúkúrú kan tàbí méjì. Àwọn akéde gbọ́dọ̀ pa àkọsílẹ̀ àwọn tí ó bá gba ìwé ìròyìn mọ́, kí wọ́n sì fi wọ́n kún ipa ìwé ìròyìn wọn.

Orin 92 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́