ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/97 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún July

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún July
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 7
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 14
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 21
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 28
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 7/97 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún July

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 7

Orin 6

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá fún oṣù March, ti orílẹ̀-èdè àti ti ìjọ àdúgbò.

15 min: “A San Èrè fún Ìṣòtítọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àpẹẹrẹ tí a sọ nínú Jí!, January 22, 1993, ojú ìwé 18 sí 21 kún un.

20 min: “Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Rí Ìtùnú.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn ìgbékalẹ̀ kan tàbí méjì. Ké sí àwùjọ láti sọ àwọn ọ̀nà míràn tí wọ́n ti gbà lo ìwé pẹlẹbẹ kan náà láti bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. Fún lílo àwọn ọ̀rọ̀ rírọrùn tí a ṣàyàn dáradára láti ru ọkàn ìfẹ́ sókè níṣìírí. (Wo Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ojú ìwé 7, ìpínrọ̀ 9 sí 11.) Dárúkọ àwọn ìwé pẹlẹbẹ míràn tí a lè fi lọni tí ìjọ sì ní lọ́wọ́.

Orin 70 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 14

Orin 5

12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Jíròrò Àpótí Ìbéèrè.

18 min: “Jẹ́rìí Níbikíbi Tí Àwọn Ènìyàn Bá Wà.” Ọ̀rọ̀ àsọyé. Bí àkókò bá ti wà tó, a lè ṣàjọpín àfikún àwọn ìrírí láti inú ìwé 1997 Yearbook, ojú ìwé 43 sí 46.

15 min: Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló. Alàgbà jíròrò àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tí ó fi hàn bí ó ti ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn láti ìgbà ọmọdé jòjòló. (Òwe 22:6; 2 Tím. 3:14, 15) Àwọn òbí kan ronú pé kò yẹ láti pèsè ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì tí ó rinlẹ̀ fún àwọn ọmọ títí di ìgbà tí wọ́n bá dàgbà tó láti ṣe àwọn ìpinnu tiwọn fúnra wọn. Nínú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ọmọ ti bá ayé lọ. Ó yẹ kí ìtọ́ni tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ ní ìgbà ọmọdé jòjòló. (g97-YR 3/8 ojú ìwé 26, 27; w88-YR 8/1 ojú ìwé 12, 13) Fọ̀rọ̀ wá tọkọtaya tí ń ṣàníyàn nípa ipò tẹ̀mí àwọn ọmọ wọn lẹ́nu wò. Fi hàn bí bàbá ṣe ń mú ipò iwájú, ṣùgbọ́n pé àwọn òbí méjèèjì ń ṣe ipa tiwọn ní pípèsè ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ó ṣe déédéé, tí ó sì jinlẹ̀, fún kíkọ́ àwọn ọmọ. Tọkọtaya sọ ohun tí wọ́n ti ń ṣe ní sísapá láti fi òtítọ́ kọ́ àwọn ọmọ wọn, ní fífi àwọn àbá tí ètò àjọ náà ti pèsè sílò lórí níní ìtòlẹ́sẹẹsẹ gbígbéṣẹ́, tí ó wúlò, fún kíkọ́ni nínú ilé. Alàgbà tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì fífi ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba àwọn òbí níyànjú láti ṣe sílò.—w85-YR 10/1 23; Éfésù 6:1-4.

Orin 71 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 21

Orin 14

12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó. Ṣàyẹ̀wò “A Óò Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.”

13 min: ‘Ta Ni Yóò Lọ fún Wa?’ Ọ̀rọ̀ àsọyé gbígbéṣẹ́. Fi ìṣírí tí a fúnni láti ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé àti ìrírí tí ó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 1997, ìpínrọ̀ 16 àti 17 kún un. Àwọn tí kò lè ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé lè fẹ́ láti wéwèé oṣù tàbí àwọn oṣù tí wọn yóò ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn tí ń bọ̀.

20 min: Múra Sílẹ̀ Láti Jẹ́rìí Láìjẹ́ Bí Àṣà. Lójoojúmọ́, a máa ń ní àǹfààní láti jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn tí a bá bá pàdé. Nígbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀, a lè rí i pé a kò ní Bíbélì tàbí àwọn ìtẹ̀jáde tí a óò lò. Wéwèé ṣáájú. Ní ilé, mú kí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó nítòsí ẹnu ọ̀nà tí o ti máa ń kí àwọn àlejò. Kó onírúurú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sínú àpò tàbí àpamọ́wọ́ kí o sì gbé e dání tàbí kí o gbé e sínú ọkọ̀ rẹ, ní ibi iṣẹ́ rẹ, tàbí nínú àpótí tábìlì rẹ ní ilé ẹ̀kọ́. Mú nǹkan dání nígbà tí o bá ń wọkọ̀ èrò. Kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀ dání nígbà tí o bá ń rìnrìn àjò fún iṣẹ́ ajé, nígbà tí o bá ń rìnrìn àjò lọ sí àpéjọpọ̀, nígbà tí o bá ń ṣèbẹ̀wò sí ìlú ìbílẹ̀ rẹ tàbí nígbà tí o bá ń lọ fún ìsinmi. Jíròrò àwọn àfikún àbá tí ó wà nínú Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ojú ìwé 81 àti 82, ìpínrọ̀ 11 sí 16. Ní ṣókí, ṣàṣefihàn àwọn ọ̀nà mélòó kan láti gbà yọ sí olùtajà kan, òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni, ẹlẹgbẹ́ ẹni ní ilé ẹ̀kọ́, abánirìnrìn-àjò, tàbí ẹni tí ó wà lẹ́nu ìsinmi.

Orin 72 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 28

Orin 15

12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo àwùjọ létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn sílẹ̀. Ṣàyẹ̀wò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àfilọni fún oṣù August. Ní ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò ní oṣù August, pọkàn pọ̀ sórí pípadà ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìwé pẹlẹbẹ tí o fi sóde ní oṣù July ní gbígbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní lílo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù March 1997, tọ́ka sí àwọn kókó pàtàkì mélòó kan fún ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò tí ó gbéṣẹ́. A ní láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí nínú ìwé Ìmọ̀.

15 min: Àìní àdúgbò. Tàbí, kí alàgbà kan sọ ọ̀rọ̀ àsọyé lórí “Kọ̀ Láti Gba Àwọn Ìtàn Èké,” tí a gbé ka Ilé-Ìṣọ́nà, April 1, 1994, ojú ìwé 29 sí 31.

18 min: Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Láṣepé. Ìjíròrò láti ẹnu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn, tí a gbé karí ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 5 sí 8. Tẹnu mọ́ bí iṣẹ́ ìwàásù náà ti ṣe pàtàkì tí ó sì jẹ́ kánjúkánjú tó, ní ríru gbogbo àwùjọ sókè láti fọwọ́ pàtàkì mú ẹrù iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́.

Orin 75 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́