Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún August
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 4
Orin 16
7 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá fún oṣù April, ti orílẹ̀-èdè àti ti ìjọ àdúgbò.
13 min: “Àwọn Ìpàdé Ń Runi Lọ́kàn Sókè sí Iṣẹ́ Àtàtà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àwọn àǹfààní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró ṣáájú àti lẹ́yìn àwọn ìpàdé hàn.—Wo Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ojú ìwé 83, ìpínrọ̀ 17 àti 18.
25 min: “Gbára Lé Jèhófà Láti Mú Kí Àwọn Nǹkan Dàgbà.” Ọ̀rọ̀ àsọyé àti àwọn àṣefihàn. Tẹnu mọ́ ìdí tí a fi ní láti ṣe ìpadàbẹ̀wò sí ibi tí a bá ti fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ sóde. Jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn méjì tí a múra sílẹ̀ dáradára tí ń fi bí a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ hàn. Fi àwọn àbá tí ó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1997, ìpínrọ̀ 7 sí 11 kún un.
Orin 78 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 11
Orin 20
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
15 min: “Àwọn Àgbàlagbà Ń Wàásù Láìdáwọ́ Dúró.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi ìrírí nípa ìyá àgbà arúgbó tí ó ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kún un, láti inú Ilé-Ìṣọ́nà, July 1, 1988, ojú ìwé 13.
20 min: “Ìmúgbòòrò Tí Ń Bá A Nìṣó Ń Mú Àìní fún Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Pọ̀ Sí I.” Jíròrò ìpínrọ̀ 1 sí 10 àkìbọnú lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹnu mọ́ àwọn ìdí tí ó fi yẹ kí àwọn alàgbà kàn sí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ní ìbẹ̀rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ronú nípa kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba.
Orin 71 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 18
Orin 14
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn Ìnáwó.
15 min: “Ìmúgbòòrò Tí Ń Bá A Nìṣó Ń Mú Àìní fún Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Pọ̀ Sí I.” Ọ̀rọ̀ àsọyé tí ó kún fún ìtara lati ẹnu alàgbà lórí ìpínrọ̀ 11 sí 17 àkìbọnú. Tẹnu mọ́ àìní fún àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni púpọ̀ sí i. Bí àkókò bá ti wà tó, fi àwọn ìrírí tí ó bá a mu nípa àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí a ti kọ́ ní àgbègbè yín kún un.
20 min: Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò. Fi hàn bí a ṣe lé gbé ìbéèrè dìde kí a sì lọ sínú ìwé pẹlẹbẹ náà fún ìdáhùn. Fún àpẹẹrẹ, ìwé pẹlẹbẹ náà dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí: Ìrètí èyíkéyìí ha wà fún àwọn òkú bí? (Ojú ìwé 5 àti 6) Ó ha burú láti kẹ́dùn bí? (Ojú ìwé 8 àti 9) Báwo ni ẹnì kan ṣe lè kojú ẹ̀dùn? (Ojú ìwé 18) Báwo ni àwọn ẹlòmíràn ṣe lè ṣèrànwọ́? (Ojú ìwe 20 sí 23) Báwo ni a ṣe lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti lóye ikú? (Ojú ìwé 25) Ìtùnú wo ni Bíbélì fúnni? (Ojú ìwé 27) Lẹ́yìn náà, jíròrò ní ṣókí pẹ̀lú àwọn akéde méjì tí ó tóótun nípa bí wọ́n ṣe lo ìwé pẹlẹbẹ yìí ní ìpadàbẹ̀wò láti dáhùn àwọn ìbéèrè tí a sábà máa ń béèrè nípa ikú. Ṣàṣefihàn bí a ṣe lè lo ìwé pẹlẹbẹ náà nígbà tí a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò.
Orin 94 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 25
Orin 23
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo àwùjọ létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn sílẹ̀. Ṣe ìfilọ̀ àwọn ìṣètò iṣẹ́ ìsìn pápá fún òpin ọ̀sẹ̀ yí.
15 min: “Jàǹfààní Dídára Jù Lọ ní Ilé Ẹ̀kọ́.” Bàbá jíròrò àpilẹ̀kọ pẹ̀lú àwọn ọmọ, fi àwọn kókó tí ń ranni lọ́wọ́ kún un láti inú Jí!, December 22, 1995, ojú ìwé 7 sí 11.
20 min: Wàásù Pẹ̀lú Ète. Alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tàbí méjì ṣàtúnyẹ̀wò ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 8 sí 12. Pé àfiyèsí sórí àwọn ìdí lílágbára tí ó fi yẹ kí a pa ìṣarasíhùwà dídára, tí ó sì ń bá a lọ mọ́ sí ìṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, kí a sì máa fìgbà gbogbo fọwọ́ sowọ́ pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ètò àjọ.
Orin 100 àti àdúrà ìparí.