Àwọn Àgbàlagbà Ń Wàásù Láìdáwọ́ Dúró
1 Bí àwọn ènìyàn ti ń dàgbà sí i, ọ̀pọ̀ nínú wọn máa ń fojú sọ́nà fún fífẹ̀yìntì kúrò nínú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí wọ́n ti ń ṣe nígbà gbogbo, kí wọ́n sì gbádùn ìgbésí ayé tí kò ní àníyàn ní sáà tí ó kù nínú ọjọ́ ayé wọn. Wọ́n lè ronú pé àwọn ti ṣiṣẹ́ kára tó tí ó sì yẹ kí wọ́n sinmi nísinsìnyí. Tàbí wọ́n lè wulẹ̀ fẹ́ láti jẹ ìgbádùn èyíkéyìí tí ó bá kù nínú ìgbésí ayé.—Lúùkù 12:19.
2 Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́, a ní ojú ìwòye tí ó yàtọ̀ nípa ìgbésí ayé. A mọ̀ pé kò sí ìfẹ̀yìntì kúrò nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ojú ìwòye wa dára nítorí pé a jẹ́ kí ‘ìyè àìnípẹ̀kun wà níwájú wa.’ (Júúdà 21) Ìmọ̀ àti ìrírí tí a ti kó jọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lè mú kí agbára ìfòyemọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye ẹnì kan sunwọ̀n sí i. Èyí lè mú kí ẹnì kan gbọ́n sí i, kí ó sì túbọ̀ jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì ènìyàn, kí ó sì fi ìmọrírì tí ó jinlẹ̀ sí i hàn fún ìgbésí ayé. Gbogbo àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ń ranni lọ́wọ́ gidigidi gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ìhìn rere.
3 Dídi àgbàlagbà kì í wulẹ̀ í ṣe ọ̀ràn dídi ogbó ní ti ara; ó kan ẹ̀mí ìrònú ẹni pẹ̀lú. Bí o bá fojú sọ́nà fún gbígbé fún àkókò gígùn, tí o sì làkàkà láti wà ní ọ̀dọ́ lọ́nà tí o gbà ń wòye nǹkan, àǹfààní tí o ní láti ṣe méjèèjì lè pọ̀ sí i. Àwọn àgbàlagbà lè mú kí ìgbésí ayé wọn túbọ̀ láásìkí nípa mímú ìmọ̀ wọn nípa tẹ̀mí pọ̀ sí i, kí wọ́n sì máa ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.—1 Kọ́r. 9:23.
4 Àwọn Àpẹẹrẹ Tí Ó Ṣẹlẹ̀ Ní Ti Gidi: Ní ẹni ọdún 86, arábìnrin kan sọ pé: “Nígbà tí mo bá ronú nípa 60 ọdún tí ó ti kọjá láti ìgbà tí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ìlérí afinilọ́kàn-balẹ̀ ti Ọlọ́run a ru dìde nínú ọkàn àyà mi. Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ẹni tí yóò gbégbèésẹ̀ ní ìdúróṣinṣin pẹ̀lú àwọn adúróṣinṣin ń jẹ́ kí a kárúgbìn ayọ̀ yanturu.” (Orin Dá. 18:25) Arákùnrin àgbàlagbà kan rántí bí ikú aya rẹ̀ ṣe dé bá a gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀lẹ̀ adániníjì, lẹ́yìn èyí tí ìlera rẹ̀ túbọ̀ burú sí i. Ó sọ pé: “Síbẹ̀, nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà, ara mi kọ́fẹ dáradára tí ó fi ṣeé ṣe fún mi láti wọnú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà ní ọdún méjì lẹ́yìn náà. Ẹ wo bí mo ṣe kún fún ìmọrírì sí Jèhófà tó pé ìlera mi ti sunwọ̀n sí i ní ti gidi pẹ̀lú ìgbòkègbodò ìwàásù tí mo mú pọ̀ sí i yìí!”
5 Ó mà yẹ fún ìgbóríyìn o pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn àgbàlagbà ti pinnu láti máa báa nìṣó ní wíwàásù títí dé àyè yòó wù tí ìlera àti okun wọn bá gbà wọ́n láàyè mọ—láìdáwọ́ dúró! Wọ́n ní ìdí rere láti polongo pé: “Ọlọ́run, ìwọ ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá: àti di ìsinsìnyí ni èmi ti ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ.”—Orin Dá. 71:17.