Jèhófà Ń Fúnni ní Agbára tí Ó Ré Kọjá Ìwọ̀n Ti Ẹ̀dá
1 Àǹfààní tí ó ṣeyebíye ti iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀—iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni—ni a ti fi lé gbogbo ọmọ ẹ̀yìn Jésù lọ́wọ́. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Ṣùgbọ́n, àìpé ẹ̀dá ènìyàn àti àwọn pákáǹleke ti ètò àwọn nǹkan yìí máa ń mú wa rò pé a kò tóótun rárá nígbà míràn.
2 Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní Kọ́ríńtì lè tù wá nínú. Ó kọ̀wé pé: “Àwa ní ìṣúra yìí nínú àwọn ohun ìlò tí a fi amọ̀ ṣe.” (2 Kọ́r. 4:7) Pọ́ọ̀lù ní ìgbọ́kànlé pé: “Níwọ̀n bí a ti ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí . . . , àwa kò . . . juwọ́ sílẹ̀.” (2 Kọ́r. 4:1) Lóòótọ́, ìpèníjà ni ó jẹ́ fún gbogbo wa láti máa bá a nìṣó ní pípolongo ìhìn rere kí á má sì “juwọ́ sílẹ̀,” yálà a wà lára àwọn ẹni àmì òróró tàbí lára “àwọn àgùntàn míràn.” A nílò okun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.”—Jòh. 10:16; 2 Kọ́r. 4:7b.
3 Lọ́nà tí ń fúnni níṣìírí, ọ̀pọ̀ nínú Àwọn Ẹlẹ́rìí ni wọ́n jẹ́ onítara ajíhìnrere láìka ti pé wọ́n ní láti kojú àtakò, àwọn ọ̀ràn ìṣòro ìlera, tàbí ti àìrówó tí ó tó ná sí. Ó yẹ kí gbogbo wa mọ̀ pé iṣẹ́ tí a yàn fún wa láti wàásù ní ìtìlẹ́yìn Jèhófà. Dípò kí á jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí ìbẹ̀rù mú ìpinnu wa láti wàásù di aláìlágbára, ẹ jẹ́ kí a “máa bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa àti nínú agbára ńlá okun rẹ̀.”—Éfé. 6:10; Òwe 24:10.
4 Bí a Ṣe Lè Rí Agbára Ọlọ́run Gbà: Forí tì í nínú àdúrà, ní bíbéèrè fún ìrànlọ́wọ́ àti okun lọ́wọ́ Ọlọ́run. (Róòmù 12:12; Fílí. 4:6, 7) Nígbà náà, pẹ̀lú gbogbo ọkàn àyà rẹ, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láti pèsè agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá. (Òwe 3:5) Ka àwọn ìtàn ìgbésí ayé ti òde òní nínú àwọn ìwé ìròyìn wa, nítorí wọ́n ń pèsè ẹ̀rí pé Jèhófà ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ lónìí láti fara da àwọn àdánwò. Sún mọ́ àwọn ará nínú ìjọ pẹ́kípẹ́kí, má sì ṣe kọ àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀.—Róòmù 1:11, 12; Héb. 10:24, 25.
5 Ǹjẹ́ kí a ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti fi ara wa sójú ìlà láti rí agbára Jèhófà gbà—agbára kan tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá tí yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀ nínú iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì gidi ti wíwàásù Ìjọba náà.