Iṣẹ́ Tí Ọlọ́run Ń Tì Lẹ́yìn
1 Ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run òde òní ló kàwé tí wọ́n gboyè rẹpẹtẹ, tàbí ni wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí olókìkí nínú ayé. Látàrí èyí, àwọn èèyàn kan kì í fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa nítorí pé wọ́n kà á sí ohun tí kò ṣe pàtàkì. (Aísá. 53:3) Àmọ́ ṣá o, iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí à ń ṣe ti mú ìtùnú àti ìrètí bá ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn yíká ayé. Báwo làwọn èèyàn tí wọn kò kà sí láwùjọ ṣe lè gbé irú àwọn nǹkan ńlá bẹ́ẹ̀ ṣe? Nípasẹ̀ ìtìlẹyìn Ọlọ́run nìkan lèyí fi lè ṣeé ṣe. (Mát. 28:19, 20; Ìṣe 1:8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run . . . yan àwọn ohun aláìlera ayé, kí ó bàa lè kó ìtìjú bá àwọn ohun tí ó lágbára.”—1 Kọ́r. 1:26-29.
2 Ọ̀pọ̀ lára àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ló jẹ́ àwọn ènìyàn “tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù.” (Ìṣe 4:13) Síbẹ̀, wọ́n fi ẹ̀mí àìṣojo ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́, Jèhófà sì bù kún ìsapá wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun ìdènà àti àtakò wà, “ọ̀rọ̀ Jèhófà ń bá a nìṣó ní gbígbilẹ̀ àti ní bíborí lọ́nà tí ó ní agbára ńlá.” Kò sí ohunkóhun tó lè dá iṣẹ́ náà dúró nítorí pé Ọlọ́run ló ń tì í lẹ́yìn. (Ìṣe 5:38, 39; 19:20) Bákan náà lọ̀ràn ṣe rí láyé òde òní. Àní, àtakò lílekoko tí àwọn alákòóso tó lágbára ń ṣe pàápàá kò lè ṣèdíwọ́ fún bí ìhìn rere náà ṣe ń fìdí múlẹ̀ tó sì ń gbilẹ̀.—Aísá. 54:17.
3 Ọlọ́run Ni Gbogbo Ìyìn Yẹ: Ǹjẹ́ ó yẹ kí àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tá a ní láti jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run mú ká máa ṣògo nínú ara wa? Rárá o. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, ó kọ̀wé pé: “Àwa ní ìṣúra yìí nínú àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe, kí agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má sì jẹ́ èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde.” (2 Kọ́r. 4:7) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé okun tí Ọlọ́run ń fún òun ló ń jẹ́ kí òun lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun.—Éfé. 6:19, 20; Fílí. 4:13.
4 Lọ́nà kan náà, àwa náà mọ̀ pé ohun tó mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà lè ṣeé ṣe ni pé à ń “rí ìrànlọ́wọ́ tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run gbà.” (Ìṣe 26:22) Jèhófà ń tipasẹ̀ ìpòkìkí jákèjádò ayé náà lò wá lọ́nà àgbàyanu láti mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì, ìmìtìtì yìí sì jẹ́ àmì ìdájọ́ rẹ̀ tó máa fọ́ àwọn orílẹ̀-èdè túútúú láìpẹ́. (Hág. 2:7) Àǹfààní ńlá la mà ní o láti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run” nínú iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí ńláǹlà yìí!—1 Kọ́r. 3:6-9.