Fi Ọ̀wọ̀ Hàn fún Ibi Ìjọsìn Jèhófà
1 Nígbà tí a bá jẹ́ àlejò ní ilé ẹnì kan, a máa ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún ohun ìní ẹni yẹn, a kò ní ṣe nǹkan tí yóò bà á jẹ́, a kì í sì í da bí agbo ilé náà ṣe ń ṣe nǹkan létòlétò rú. Ẹ wo bí ó ti yẹ kí èyí tilẹ̀ ti rí bẹ́ẹ̀ tó nígbà tí a bá jẹ́ àlejò Jèhófà! Ó yẹ kí á mọ bí ó ṣe yẹ kí a hùwà nínú agbo ilé rẹ̀. (Orin Dá. 15:1; 1 Tím. 3:15) Yálà a ń ṣe ìpàdé Kristẹni wa nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, ilé àdáni, tàbí ní ibì kan tí ó wà fún gbogbo ará ìlú, ọ̀pọ̀ jáǹtìrẹrẹ nínú wa sábà máa ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún ibi ìjọsìn wa bí ẹni pé ilé Jèhófà, ẹni tí “ògo rẹ̀ borí ayé òun ọ̀run” ni.—Orin Dá. 148:13.
2 Àwọn ará kan ń fi àìlọ́wọ̀ hàn ní àwọn ìpàdé nípa pípariwo tàbí híhùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni pé ìsọfúnni tí a ń gbé jáde kò ṣe pàtàkì. Àwọn àgbàlagbà díẹ̀ máa ń ṣe ìjíròrò tí kò pọn dandan ní ẹnu àbáwọlé, fàráńdà, ilé ìtura, tàbí ní ìta Gbọ̀ngàn Ìjọba nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́. Nígbà tí a bá fún ọmọ kan tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n láyè láti lọ tọ́jú àbúrò rẹ̀, nígbà míràn, àwọn méjèèjì a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣeré tí wọn kò sì ní jàǹfààní púpọ̀ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. A ti rí àwọn èwe kan ní ìta Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́yìn ìpàdé tí wọ́n ń ṣeré, tí wọ́n ń pariwo gèè, tí wọ́n tilẹ̀ ń ta ìpá síra wọn. Nínú àwọn ọ̀ràn kan wọ́n ti yọ àwọn aládùúgbò lẹ́nu tàbí kí wọ́n ti ṣèdíwọ́ fún ìrìnnà ọkọ̀ ní ibi ìgbọ́kọ̀sí tàbí ní ojú pópó.
3 Bí A Ṣe Lè Yẹra fún Dídi Aláìlọ́wọ̀: Láìṣiyèméjì, ní mímọrírì ọlá àti jíjẹ́ ọlọ́wọ̀ ìjọsìn wa, àwa kò ní fẹ́ pín àwọn ẹlòmíràn níyà nípa sísọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́, jíjẹun, jíjẹ ṣingọ́ọ̀mù, rírún bébà, lílọ sí ilé ìtura láìnídìí, tàbí sísọ ọ́ dàṣà láti máa pẹ́ dé sí àwọn ìpàdé. Àwọn òbí tí wọ́n lọ́wọ̀ tí wọ́n sì mọrírì kò ní jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn dọ̀tí ilẹ̀, ìjókòó, tàbí ògiri Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ilé ibi tí a ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ. Kò sì sí iyè méjì pé gbogbo wa gbà pé, dájúdájú, kò sí àyè fún ìwà tí ń tini lójú, ọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn èyíkéyìí ní àwọn ìpàdé wa.—Éfé. 5:4.
4 Bí a bá ń fìgbà gbogbo rántí ète àwọn ìpàdé Kristẹni wa, àwa yóò rí i dájú pé àwa àti àwọn ọmọ wa fi ọ̀wọ̀ tí ó yẹ hàn fún ìjọsìn Jèhófà ní ibi tí a “ti yàn láti máa dúró.”—Orin Dá. 84:10, NW.