ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/98 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún January

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún January
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 5
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 12
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 19
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 26
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 1/98 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún January

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 5

Orin 10

8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

17 min: “Ní Ìdùnnú Nínú Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná.” Ìjíròrò àpilẹ̀kọ pẹ̀lú àwùjọ. Tẹnu mọ́ àwọn ìjẹ́pàtàkì ìgbékalẹ̀ tí ó gbéṣẹ́: (1) Kíni bí ọ̀rẹ́, (2) sọ̀rọ̀ lórí kókó ọ̀rọ̀ kan tí a nífẹ̀ẹ́ sí tí ń lọ lọ́wọ́ tàbí kí o gbé ìbéèrè dìde lórí rẹ̀, (3) tọ́ka sí ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó bá a mu wẹ́kú kan, kí o sì (4) darí àfiyèsí sí ìtẹ̀jáde tí o fi ń lọni. Jẹ́ kí akéde kan tí ó dáńgájíá ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ ìgbà àkọ́kọ́ àti ìpadàbẹ̀wò tí ó bá a mu tí a dábàá rẹ̀.

20 min: Múra Sílẹ̀ Nísinsìnyí Láti Di Òfin Ọlọ́run Lórí Ẹ̀jẹ̀ Mú. Alàgbà títóótun jíròrò ìjẹ́pàtàkì kíkọ ọ̀rọ̀ kún káàdì Advance Medical Directive/Release. Ìdarísọ́nà tí a mí sí tí ó wà ní Orin Dáfídì 19:7 fi hàn pé Ìṣe 15:28, 29 jẹ́ ọ̀rọ̀ ìsọjáde òfin pípé ti Ọlọ́run lórí ẹ̀jẹ̀. Àwọn adúróṣinṣin olùjọ́sìn ń sakun láti di òfin yẹn mú. Ìwé àkọsílẹ̀ yí sọ ìpinnu rẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ di mímọ̀ ó sì ń sọ̀rọ̀ fún ọ nígbà tí o kò bá lè sọ̀rọ̀ fúnra rẹ. (Fi wé Òwe 22:3.) Káàdì tuntun kan ń pèsè ìpolongo ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ti kíkọ̀ tí o kọ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀. Lẹ́yìn ìpàdé yìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó ti ṣe batisí tí wọ́n fẹ́ láti ní káàdì tuntun kan ni a óò fún ní ọ̀kan, àwọn tí wọ́n sì ní àwọn ọmọ aláìtójúúbọ́ tí kò tí ì ṣe batisí yóò gba Identity Card (Káàdì Ìdánimọ̀) fún ọmọ kọ̀ọ̀kan. A kò ní kọ ọ̀rọ̀ kún inú àwọn káàdì wọ̀nyí ní alẹ́ òní. Kí ẹ fara balẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ kún inú wọn ní ilé ṣùgbọ́n kí ẹ MÁ ṢE bu ọwọ́ lù ú. Bíbuwọ́lù ú, jíjẹ́rìí sí i, àti kíkọ déètì sí gbogbo àwọn káàdì náà ni a óò ṣe lẹ́yìn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tí ń bọ̀, lábẹ́ àbójútó olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ. Èyí yóò jẹ́ kí ó rí i dájú pé gbogbo àwọn tí a pín sí àwùjọ rẹ̀ tí wọ́n fẹ́ láti ṣe ohun tí ìtọ́sọ́nà ìṣègùn yí béèrè rí ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ń fẹ́ gbà. Àwọn tí ń bu ọwọ́ lu káàdì náà bí ẹlẹ́rìí gbọ́dọ̀ rí i nígbà tí ẹni tí ó ni káàdì náà ń buwọ́ lù ú. Ẹnikẹ́ni tí kò bá sí lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà náà tí ó sì ń fẹ́ kọ ọ̀rọ̀ kún káàdì náà kí ó sì buwọ́ lù ú ni àwọn olùdarí tàbí alàgbà yóò ràn lọ́wọ́ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí yóò tẹ̀ lé e títí di ìgbà tí gbogbo akéde tí ó ti ṣèrìbọmi bá tó kọ ọ̀rọ̀ kún káàdì wọn lọ́nà tí ó bójú mu. (Ṣàtúnyẹ̀wò lẹ́tà October 15, 1991.) Nípa títún àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò nínú káàdì yí kọ láti bá ipò àti ìdánilójú tiwọn mu, àwọn akéde tí kò tí ì ṣe batisí lè kọ ìtọ́sọ́nà tiwọn tí wọn yóò lò fún ara wọn àti ti àwọn ọmọ wọn.

Orin 142 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 12

Orin 125

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣe ìfilọ̀ àwọn ìṣètò iṣẹ́ ìsìn pápá fún òpin ọ̀sẹ̀.

15 min: “Ṣíṣàìṣojúṣàájú Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹnu mọ́ àwọn apá ìhà kókó ẹ̀kọ́ yìí tí ó kan ìpínlẹ̀ àdúgbò ní pàtàkì.

20 min: “Jèhófà Ń Fúnni ní Agbára tí Ó Ré Kọjá Ìwọ̀n Ti Ẹ̀dá.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. (Wo w90-YR 7/15 19, ìpínrọ̀ 15 àti 16.) Ṣètò pé kí àwọn kan sọ ìrírí tí ń fúnni níṣìírí tí ń fi bí Jèhófà ti fún wọn lókun hàn.

Orin 81 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 19

Orin 1

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.

15 min: Àìní àdúgbò.

20 min: Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé Tí Ń Mú Ayọ̀ Wá. Tọkọtaya ń jíròrò àwọn àìní tẹ̀mí ìdílé wọn. Wọ́n ń ṣàníyàn nípa àwọn agbára ìdarí ti ayé tí ń nípa lórí àwọn ọmọ wọn ní ọ̀nà tí kò dára, wọ́n rí ìjẹ́pàtàkì fífún ipò tẹ̀mí àwọn ọmọ wọn lókun ṣùgbọ́n wọ́n gbà pé ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé àwọn kò lọ déédéé kì í sì í fìgbà gbogbo gbéṣẹ́. Wọ́n jọ ṣàyẹ̀wò ìdámọ̀ràn lórí bí a ṣe lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tí ó nítumọ̀, èyí tí a pèsè nínú Ilé Ìṣọ́, August 1, 1997, ojú ìwé 26 sí 29. Àwọn méjèèjì pinnu láti ṣiṣẹ́ lórí dídáàbòbò ìlera tẹ̀mí àwọn ọmọ wọn.

Orin 146 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 26

Orin 187

12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní oṣù February. Mẹ́nu kan kókó kan tàbí méjì láti inú ìwé Ayọ̀ Ìdílé tí yóò ṣèrànwọ́ nígbà tí a bá ń fi lọni.

15 min: “Fi Ọ̀wọ̀ Hàn fún Ibi Ìjọsìn Jèhófà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Kí alàgbà kan, tí yóò lè fi inú rere mú un bá ipò àdúgbò mu, bójú tó o.

18 min: Ríròyìn Ìpín Tiwa Nínú Iṣẹ́ Ìjẹ́rìí Kárí Ayé. (Tí a gbé karí ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa ojú ewé 100 sí 102, 106 sí 110) Ọ̀rọ̀ àsọyé àti ìjíròrò tí akọ̀wé yóò bójú tó. Lẹ́yìn fífi àpẹẹrẹ ìṣáájú tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu ti ríròyìn ìgbòkègbodò wa déédéé hàn, òun yóò ké sí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ méjì láti ṣàyẹ̀wò ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ náà, “Idi Tí A Fi Nrohin Iṣẹ-Isin Pápá-Oko Wa.” Akọ̀wé yóò wá tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì títètè fi ìròyìn tí ó péye sílẹ̀. Òun yóò tọ́ka sí ìdí tí gbígbé góńgó ti ara ẹni ka iwájú, fi ṣàǹfààní, ní fífi gbólóhùn tí ń fúnni níṣìírí nípa àwọn ìbùkún tí ń wá fún àwọn tí wọ́n ń nípìn-ín kíkún nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà parí ọ̀rọ̀.

Orin 189 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́