ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 8/1 ojú ìwé 26-29
  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé Tí Ń Mú Ìdùnnú Wá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé Tí Ń Mú Ìdùnnú Wá
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ó Yẹ Kí A Kẹ́kọ̀ọ́?
  • Mú Kí Àyíká Náà Tuni Lára
  • Jẹ́ Kí Bíbélì Tani Jí
  • Ran Gbogbo Wọn Lọ́wọ́ Láti Kópa
  • Bá Wọn Sọ̀rọ̀—Máà Ṣe Mú Wọ́n Bínú!
  • Ìsapá Náà Yẹ
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Déédéé Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé—Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ṣiṣẹ́ Lati Pa Idile Rẹ Mọ́ Wọnu Ayé Titun Ti Ọlọrun
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Títẹ́wọ́gba Ẹrù Iṣẹ́ Bíbójútó Ìdílé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 8/1 ojú ìwé 26-29

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé Tí Ń Mú Ìdùnnú Wá

Bíbélì sọ pé: “Nípa ìmọ̀ ni iyàrá fi kún fún onírúurú ọrọ̀ iyebíye àti dídùn.” (Òwe 24:4) Àwọn ohun iyebíye tí wọ́n níye lórí wọ̀nyí kì í ṣe ìṣúra ti ara nìkan ṣùgbọ́n ó ní ìfẹ́ tòótọ́, ìbẹ̀rù Ọlọ́run, àti ìgbàgbọ́ lílágbára nínú pẹ̀lú. Ní tòótọ́, irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ ń mú ìgbésí ayé ìdílé tí ó sunwọ̀n jáde. (Òwe 15:16, 17; Pétérù Kíní 1:7) Ṣùgbọ́n, láti lè ní wọn, a ní láti mú ìmọ̀ Ọlọ́run wá sínú agboolé wa.

ẸRÙ iṣẹ́ olórí ìdílé ni láti gbin ìmọ̀ yí sọ́kàn àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀. (Diutarónómì 6:6, 7; Éfésù 5:25, 26; 6:4) Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà dídára jù lọ tí a lè gbà ṣe èyí ni nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tí a ń ṣe déédéé. Ẹ wo bí èyí ṣe lè gbádùn mọ́ àwọn tí ń kópa nínú rẹ̀ tó nígbà tí a bá darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́nà tí ó pèsè ìtọ́ni, tí ó sì tuni lára! Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn ohun pàtàkì tí dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tí ó gbéṣẹ́ ní nínú yẹ̀ wò.a

Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé máa ń gbéṣẹ́ jù lọ nígbà tí a bá ń ṣe é déédéé. Bí a bá fi ṣe ọ̀ràn ìgbà tí àyè rẹ̀ bá yọ tàbí èyí tí a kò múra rẹ̀ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ó di ségesège. Nítorí náà o gbọ́dọ̀ ‘ra àkókò pa dà’ fún ìkẹ́kọ̀ọ́. (Éfésù 5:15-17) Yíyan àkókò déédéé tí yóò rọrùn fún gbogbogbòò lè jẹ́ ìpèníjà. Olórí ìdílé kan jẹ́wọ́ pé: “A ní ìṣòro ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa déédéé. A gbìyànjú àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ títí tí a fi rí àkókò kan ní àṣáálẹ́ tí ó rọrùn fún wa. Nísinsìnyí a ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa déédéé.”

Gbàrà tí ẹ bá ti rí àkókò kan tí ó rọrùn fún yín, ṣọ́ra kí ẹ má ṣe fàyè gba ìpínyà ọkàn láti da ìkẹ́kọ̀ọ́ náà rú. Maria,b tí ó jẹ́ ẹni ọdún 33 nísinsìnyí, rántí pé: “Bí àwọn àlejò bá dé nígbà tí a ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, Dádì yóò ké sí wọn láti jókòó títí tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà yóò fi parí. Bí tẹlifóònù bá sì dún, yóò wulẹ̀ sọ fún onítọ̀hún pé òun yóò tẹ̀ ẹ́ láago bí ó bá ṣe díẹ̀ sí i.”

Ṣùgbọ́n, èyí kò túmọ̀ sí pé kò lè sí àyè fún títẹ̀síhìn-ín sọ́hùn-ún. Ipò pàjáwìrì tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ lè dìde, nígbà míràn, ó sì lè pọn dandan láti má ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tàbí láti sún un síwájú. (Oníwàásù 9:11) Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra láti má ṣe fàyè gba èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí láti da ìtòlẹ́sẹẹsẹ yín rú.—Fílípì 3:16.

Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ kan ṣe yẹ kí ó gùn tó? Robert, tí ó ti kẹ́sẹ járí nínú títọ́ ọmọbìnrin kan àti ọmọkùnrin kan dàgbà, sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà ìkẹ́kọ̀ọ́ wa máa ń gba wákàtí kan. Nígbà tí àwọn ọmọ wa ṣì kéré, a gbìyànjú láti mú kí wọ́n pọkàn pọ̀ láàárín wákàtí kan náà nípa gbígbé onírúurú nǹkan yẹ̀ wò, irù bí ìpínrọ̀ mélòó kan nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́, àwọn àyọkà inú Bíbélì tí a ṣàyàn, àti àwọn apá mìíràn nínú àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn.” Maria rántí pé: “Nígbà tí èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin méjèèjì ṣì kéré gan-an, ìkẹ́kọ̀ọ́ wa máa ń gba 20 ìṣẹ́jú nígbà méjì tàbí mẹ́ta láàárín ọ̀sẹ̀ kan. Bí a ti ń dàgbà, ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ máa ń gba nǹkan bíi wákàtí kan.”

Kí Ni Ó Yẹ Kí A Kẹ́kọ̀ọ́?

Ríronú lórí ìbéèrè yí nígbà tí gbogbo ènìyàn ti jókòó fún ìkẹ́kọ̀ọ́ yóò yọrí sí ìjákulẹ̀ àti ìpàdánù àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ṣíṣeyebíye. Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ kì yóò ní ohun pàtó láti fojú sọ́nà fún, kò sì ní pẹ́ tí yóò fi sú wọn. Nítorí náà, ṣáájú àkókò, ẹ yan ọ̀kan nínú àwọn ìtẹ̀jáde Society tí ẹ óò gbé yẹ̀ wò.

“Olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú” ti pèsè ìtẹ̀jáde rẹpẹtẹ tí a lè yàn nínú rẹ̀. (Mátíù 24:45-47) Ẹ lè lo ìwé kan tí ìdílé kò tí ì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Ẹ sì wo bí yóò ti gbádùn mọ́ni tó láti ṣàyẹ̀wò àwọn apá tí a yàn láti inú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures bí àwọn ìdìpọ̀ wọ̀nyí bá wà ní èdè yín! Fún àpẹẹrẹ, ẹ lè ṣàyẹ̀wò àpilẹ̀kọ náà lórí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ní àwọn ọ̀sẹ̀ tí ó ṣáájú Ìṣe Ìrántí. Ọ̀pọ̀ ìdílé ń gbádùn mímúra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tí ọ̀sẹ̀ náà sílẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn àfikún àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ pẹ̀lú ń pèsè àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó pinmirin láti kẹ́kọ̀ọ́. Olórí ìdílé, tí ó mọ àìní ìdílé rẹ̀ nípa tẹ̀mí, wà ní ipò tí ó dára jù lọ láti pinnu ìtẹ̀jáde tí wọn yóò kẹ́kọ̀ọ́.

Maria rántí pé: “A máa ń kẹ́kọ̀ọ́ ìtẹ̀jáde kan tí a ti yàn ṣáájú àkókò. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìbéèrè kan bá dìde tàbí ti ipò kan bá yọjú ní ilé ẹ̀kọ́, nígbà náà, a óò lọ sínú ìsọfúnni tí ó bá a mu.” Àníyàn àkànṣe, irú bí ìṣòro tí àwọn èwe ń dojú kọ ní ilé ẹ̀kọ́, dídá ọjọ́ àjọròde, àwọn ìgbòkègbodò afẹ́, àti irú nǹkan bẹ́ẹ̀, máa ń jẹ yọ. Nígbà tí èyí bá jẹ yọ, yan àwọn àpilẹ̀kọ tàbí ìtẹ̀jáde tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro tí ó wà nílẹ̀. Bí o bá rí ìsọfúnni nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tí ó dé kẹ́yìn, tí ìwọ yóò fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ ní kíá mọ́sá, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti ṣètò fún ìyẹn. Àmọ́ ṣáá o, ìwọ yóò fẹ́ láti fi ìyípadà náà tó àwọn mẹ́ńbà ìdílé létí ṣáájú àkókò. Ṣùgbọ́n rí i dájú pé ẹ pa dà sórí ìwé tí ẹ ti ṣètò fún tẹ́lẹ̀ gbàrà tí ẹ bá ti bójú tó àìní náà.

Mú Kí Àyíká Náà Tuni Lára

Ó máa ń rọrùn jù lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ ní ibi tí ó pa rọ́rọ́. (Jákọ́bù 3:18) Nítorí náà jẹ́ kí àyíká náà tuni lára, síbẹ̀ kí ó fi ọ̀wọ̀ hàn. Olórí ìdílé kan ní United States sọ pé: “Yálà a ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú iyàrá tàbí ní ọ̀dẹ̀dẹ̀, a máa ń gbìyànjú láti jókòó pa pọ̀ dípò tí a óò fi jókòó gátagàta nínú iyàrá ńlá. Fún wa, èyí ń pèsè ìmọ̀lára onífẹ̀ẹ́.” Maria sì rántí pẹ̀lú ìmọrírì ńláǹlà pé: “A yọ̀ǹda fún èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin láti yan ibi tí a óò ti fẹ́ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀sẹ̀ náà nínú ilé. Èyí mú kí ara tù wá.” Rántí pé iná tí ó mọ́lẹ̀, ètò ìjókòó tí ó rọni lọ́rùn, àti àyíká amóríyá tí kò rí jákujàku, túbọ̀ ń jẹ́ kí ara tuni. Níní ìpápánu fún ìdílé lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tún ń mú kí alẹ́ náà gbádùn mọ́ni.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ìdílé kan máa ń yàn láti jẹ́ kí àwọn ìdílé mìíràn dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn, tí ń mú kí ó túbọ̀ lárinrin, kí ó sì kún fún onírúurú ọ̀rọ̀ ìlóhùnsí. Nígbà tí a bá ké sí àwọn ẹni tuntun nínú òtítọ́ láti lọ́wọ́ nínú ìṣètò yí, wọ́n lè jàǹfààní nínú rírí bí olórí ìdílé kan tí ó jẹ́ onírìírí ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé.

Jẹ́ Kí Bíbélì Tani Jí

Jẹ́ kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ta àwọn ọmọ jí, wọn yóò sì máa fojú sọ́nà fún wọn. O lè ṣe èyí nípa fífún àwọn ọmọdé níṣìírí láti ya àwòrán ìran inú Bíbélì. Nígbà tí ó bá yẹ, jẹ́ kí àwọn ọmọ fi ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì tàbí àwòkẹ́kọ̀ọ́ kan dá a yín lára yá. Ní ti ọ̀ràn àwọn ọmọ kéékèèké, kò pọn dandan láti rọ̀ mọ́ ọ̀nà oníbèéèrè àti ìdáhùn tí a sábà máa ń lò. Kíka ìtàn nípa àwọn ènìyàn inú Bíbélì tàbí sísọ ìtàn wọn jẹ́ ọ̀nà gbígbádùnmọ́ni láti gbin ìlànà Ọlọ́run síni lọ́kàn. Robert, tí a mẹ́nu kàn níṣàájú, rántí pé: “Nígbà míràn a óò ka àwọn àyọkà Bíbélì, a óò máa gbà á kà, ní kíka onírúurú ‘ohùn’ gẹ́gẹ́ bí a ṣe yàn án fún wa.” A lè ké sí àwọn ọmọ láti yan ènìyàn tí wọ́n fẹ́ láti ṣojú fún nínú ìkàwé náà.

Lílo àwòrán ilẹ̀ àti ṣáàtì yóò ran àwọn ọmọ tí wọ́n ti dàgbà lọ́wọ́ láti fojú inú wo àwọn àgbègbè ilẹ̀ náà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a jíròrò ti ṣẹlẹ̀ àti àwọn ohun tí ń bẹ níbẹ̀. Ó ṣe kedere pé, pẹ̀lú ìfinúwòye díẹ̀, ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé kan lè tani jí, kí ó sì jẹ́ onírúurú. Àwọn ọmọ yóò sì ní ìyánhànhàn fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Pétérù Kíní 2:2, 3.

Ran Gbogbo Wọn Lọ́wọ́ Láti Kópa

Kí àwọn ọmọdé lè gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, àwọn pẹ̀lú gbọ́dọ̀ kópa. Ṣùgbọ́n, mímú kí àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn kò dọ́gba kópa lè jẹ́ ìpèníjà. Ṣùgbọ́n ìlànà Bíbélì kan sọ pé: “Ẹni tí ń ṣe àbójútó, kí ó máa ṣe é pẹ̀lú ẹ̀mí ìfitaratara ṣe nǹkan ní tòótọ́ gidi.” (Róòmù 12:8) Jíjẹ́ onítara ń ṣèrànwọ́, nítorí ìtara máa ń gbèèràn.

Ronald mú kí Dina ọmọbìnrin rẹ̀ ọlọ́dún márùn-ún kópa, nípa mímú kí ó ka ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń jíròrò àti nípa sísọ pé kí ó sọ ohun tí ó rí nínú àwòrán. Bí Ìṣe Ìrántí ikú Kristi ṣe ń sún mọ́lé ní èṣí, ó darí àfiyèsí sí àwọn àwòrán tí ó tan mọ́ ọn nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí.c Ó kọ̀wé pé: “Èyí ràn án lọ́wọ́ láti lóye ìjẹ́pàtàkì ìṣẹ̀lẹ̀ náà.”

Pẹ̀lú Misha, ọmọbìnrin rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́wàá, Ronald tún fi apá mìíràn kún un. Ronald sọ pé: “Misha ti tẹ̀ síwájú dórí ibi tí ó ti lè lóye ohun tí àwòrán kan túmọ̀ sí kì í ṣe wíwo àwòrán náà lásán. Nítorí náà, nígbà tí a ń gbé ìwe Revelation—Its Grand Climax At Hand!d yẹ̀ wò, a pọkàn pọ̀ sórí ìtumọ̀ àwọn àwòrán náà, èyí sì ti ràn án lọ́wọ́.”

Bí àwọn ọmọ ti ń dàgbà di ọ̀dọ́langba, ké sí wọn láti sọ bí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí a ń gbé yẹ̀ wò lọ́wọ́ ṣe kàn wọ́n. Nígbà tí ìbéèrè bá dìde nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́, yan apá tí olúkúlùkù yóò ṣe ìwádìí lé lórí fún un. Robert ṣe ìyẹn nígbà tí Paul ọmọ rẹ̀ ọlọ́dún 12, béèrè nípa ẹgbẹ́ ilé ẹ̀kọ́ kan tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ tí ń ṣe eré ìdárayà Àjàalẹ̀ àti Dírágónì. Paul àti àwọn yòó kù nínú ìdílé wá ìsọfúnni nípa lílo Watchtower Publications Index, wọ́n sì ṣàtúnyẹ̀wò rẹ̀ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn. Robert sọ pé: “Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, Paul tètè lóye pé eré ìdárayá náà kò tọ́ fún àwọn Kristẹni.”

Robert tún máa ń yan ìwádìí fúnni ní àwọn ìgbà míràn. Aya rẹ̀, Nancy, rántí pé: “Nígbà tí a ṣe ìwádìí nípa àwọn àpọ́sítélì Jésù, a yan àpọ́sítélì kan fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ẹ wo bí ó ṣe múni lọ́kàn yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ tó láti rí bí àwọn ọmọ ti ń fi ìtara gbé ìròyìn wọn kalẹ̀ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé!” Ṣíṣe ìwádìí fúnra wọn àti ṣíṣàjọpín ìsọfúnni náà pẹ̀lú ìdílé ń ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ ‘láti dàgbà níwájú Olúwa.’—Sámúẹ́lì Kíní 2:20, 21.

Bíbéèrè ìbéèrè—ìbéèrè tí ń wá ojú ìwòye ẹni àti èyí tí ń tọ́ni sọ́nà—tún jẹ́ ọ̀nà rere láti jẹ́ kí àwọn ọmọdé kópa. Àgbà Olùkọ́ náà, Jésù, béèrè àwọn ìbéèrè tí ń wá ojú ìwòye ẹni, irú bíi, “Kí ni ìwọ rò?” (Mátíù 17:25) Maria rántí pé: “Nígbà tí ẹnikẹ́ni nínú wa bá béèrè ìbéèrè, àwọn òbí wa kò dá wa lóhùn ní tààràtà rí. Wọ́n sábà máa ń béèrè ìbéèrè tí ń tọ́ni sọ́nà, ní ríràn wá lọ́wọ́ láti ronú lórí ọ̀ràn náà.”

Bá Wọn Sọ̀rọ̀—Máà Ṣe Mú Wọ́n Bínú!

Ìdùnnú tí a ń rí nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ń pọ̀ sí i bí gbogbo àwọn tí wọ́n pésẹ̀ bá lè sọ ojú ìwòye àti ìmọ̀lára wọn jáde láìbẹ̀rù pé a óò fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Ṣùgbọ́n, bàbá kan sọ pé: “Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tí ó dán mọ́rán máa ń ṣeé ṣe nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé kìkì bí ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ náà bá ṣí sílẹ̀ ní àwọn àkókò míràn. Kò lè jẹ́ kìkì àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ nìkan ni ẹ óò máa jùmọ̀ sọ̀rọ̀.” Ní gbogbo ọ̀nà, yẹra fún ọ̀rọ̀ òpònú tí ń gúnni bí idà, irú bíi, ‘Ṣe gbogbo ohun tí o fẹ́ sọ kò ju ìyẹn náà lọ? Mo rò pé nǹkan pàtàkì kan ni o fẹ́ sọ ni’; ‘Ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ gbáà nìyẹn’; ‘Toò, kí ni ẹnì kan tún lè retí lọ́dọ̀ rẹ? Àmọ́ ọmọ kékeré ni ẹ́ ṣá.’ (Òwe 12:18) Fi ìyọ́nú àti àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ. (Orin Dáfídì 103:13; Málákì 3:17) Jẹ́ kí wọn máa mú inú rẹ dùn, kí o sì tì wọ́n lẹ́yìn bí wọ́n ti ń sakun láti fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò.

Àyíká tí a ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé náà yẹ kí ó jẹ́ ibi tí ọkàn ọmọdé ti lè balẹ̀ láti gba ìtọ́ni. Òbí kan tí ó ti ṣàṣeyọrí láti tọ́ ọmọ mẹ́rin dàgbà ṣàlàyé pé: “Nígbà tí o bá bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́ ọmọdé sọ́nà, inú máa ń bí wọn.” Nínú irú àyíká bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ìsọfúnni náà má wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Nítorí náà, yẹra fún sísọ àwọn àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ di ìgbà ìbániwí àti ìjẹniníyà. Bí wọ́n bá pọn dandan, ṣe èyí lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́, má sì ṣe kó gbogbo wọn pọ̀.

Ìsapá Náà Yẹ

Kíkọ́ ìdílé tí ó lọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí ń gba àkókò àti ìsapá. Ṣùgbọ́n onísáàmù náà polongo pé: “Kíyè sí i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa: ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.” (Orin Dáfídì 127:3) A sì fi ẹrù iṣẹ́ “títọ́ [àwọn ọmọ] dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà,” lé àwọn òbí lọ́wọ́. (Éfésù 6:4) Nítorí náà, kọ́ bí a ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tí ó gbéṣẹ́, tí ó sì gbádùn mọ́ni. Sa gbogbo ipá rẹ láti pèsè “wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà,” kí àwọn ọmọ rẹ baà lè “dàgbà dé ìgbàlà.”—Pétérù Kíní 2:2; Jòhánù 17:3.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tí a gbé kalẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí tilẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ríran àwọn ọmọ lọ́wọ́ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, èròǹgbà náà tún wúlò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tí a ń ṣe níbi tí kò ti sí àwọn ọmọ.

b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

c Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde

d Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́