Ẹ Máa Hùwà Ní Irú Ọ̀nà Kan Tí Ó Yẹ Ìhìn Rere
1 Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jehofa, a fẹ́ láti bọlá fún orúkọ Jehofa. A mọ̀ pé ìwà, ọ̀rọ̀, ìmúra, àti ìwọṣọ wa lè nípa lórí ojú tí àwọn ènìyàn fi ń wo ìjọsìn tòótọ́. Èyí ń já sí òtítọ́, ní pàtàkì, nígbà tí a bá wà ní àwọn ìpàdé wa. A fẹ́ rí i dájú pé, gbogbo ohun tí a ń sọ, tí a sì ń ṣe ní àwọn ìpàdé, yẹ ìhìn rere, ó sì ń bọlá fún Jehofa.—Filip. 2:4.
2 Ọ̀pọ̀ ìlànà tí ayé ní fún wíwọṣọ àti mímúra kò bá ìlànà Kristian mu. Àwọn òjíṣẹ́ ìhìn rere ní láti fún ọ̀ràn yìí ní àfiyèsí dáradára. Ilé-Ìṣọ́nà ti June 1, 1989, ojú ìwé 20, sọ pé: “Kii ṣe ọ̀ranyàn ni kí aṣọ wa jẹ́ olówó-gọbọi, ṣugbọn kí ó mọ́tónítóní, kí ó ṣeérí, kí ó sì wà láìsí-àṣejù. Ohun tí a wọ̀ sí ẹsẹ̀ pẹlu ni a gbọ́dọ̀ túnṣe daradara kí ó sì ní ìrísí dídára. Lọna tí o farajọra, ní gbogbo awọn ipade, titikan Ibaralẹ-Kẹkọọ Iwe-Ijọ, awọn ara wa gbọ́dọ̀ mọ́tónítóní, a sì gbọ́dọ̀ wọṣọ lọ́nà tí ó wàlétònigín tí ó sì bamuwẹ́kú.”
3 Títètè dé jẹ́ àmì ìgbatẹnirò àti ìrònú jinlẹ̀ onífẹ̀ẹ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ipò tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ lè mú kí a pẹ́ dé sí ìpàdé. Ṣùgbọ́n, pípẹ́ẹ́ dé ní gbogbo ìgbà lè fi hàn pé, a kò ka ète mímọ́ ọlọ́wọ̀ ti ìpàdé náà sí, àti pé a kùnà láti mọrírì ẹrù iṣẹ́ tí a ní láti yẹra fún dídí àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn apẹ́lẹ́yìn máa ń pín ọkàn àwọn ẹlòmíràn níyà, wọ́n sì máa ń ṣèdíwọ́ fún wọn láti jàǹfààní kíkún láti inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Títètè dé ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún ìmọ̀lára àti ire gbogbo àwọn tí ó wà ní ìjókòó.
4 Ìfẹ́ fún àwọn aládùúgbò wa yẹ kí ó mú wa ṣọ́ra láti yẹra fún pípín ọkàn wọn níyà, nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́. Sísọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, jíjẹun, jíjẹ ṣingọ́ọ̀mù, rírún bébà, àti rírìnlọ-rìnbọ̀ sí ilé ìtura, lè ṣèdíwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn láti pọkàn pọ̀, kí ó sì bu iyì ọlá tí ó yẹ ibi ìjọsìn Jehofa kù. Kò bójú mu fún ẹnikẹ́ni láti máa ṣe iṣẹ́ ìjọ tàbí máa jíròrò pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, láìjẹ́ pé ohun pàjáwìrì kan ṣẹlẹ̀, tí ń béèrè pé kí àwọn arákùnrin náà fi àyè wọn sílẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó yẹ kí gbogbo àwùjọ wà lórí ìjókòó, kí wọ́n sì fetí sílẹ̀ sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, kí wọ́n baà lè ṣe ara wọn àti ìdílé wọn láǹfààní. Kò sí àyè fún àìmọ̀wàáhù nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, nítorí pé “ìfẹ́ . . . kì í hùwà lọ́nà tí kò bójúmu.”—1 Kor. 13:4, 5; Gal. 6:10.
5 Ìwà ẹ̀yẹ àwọn ọmọ wa nínú ìpàdé tún ń buyìn àti ọlá fún orúkọ Jehofa. Àbójútó dáradára láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí ṣe kókó. A ní láti rọ àwọn ọmọdé láti tẹ́tí sílẹ̀, kí wọ́n sì kópa. Ọ̀pọ̀ àwọn òbí tí wọ́n ní àwọn ọmọ kékeré máa ń yàn láti jókòó sí ibi tí yóò ti rọrùn fún wọn láti jáde síta, kí wọ́n sì bójú tó àìní àwọn ọmọ wọn kékeré, láìpín ọkàn àwọn ẹlòmíràn níyà láìyẹ.
6 Paulu rọni pé: “Ẹ máa hùwà ní irú-ọ̀nà kan tí ó yẹ ìhìnrere.” (Filip. 1:27) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a làkàkà láti hùwà lọ́nà rere, kí a sì gba ti àwọn ẹlòmíràn rò, nígbà tí a bá lọ sí ìpàdé. Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbo wa yóò mú kí “pàṣípààrọ̀ ìṣírí . . . lati ọ̀dọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnìkejì,” ṣeé ṣe.—Romu 1:12.