Jẹ́ Kó Mọ́ Ẹ Lára Láti Máa Dé Lásìkò
1. Àpẹẹrẹ wo ni Jèhófà fi lélẹ̀ tó bá kan ọ̀ràn ká ṣe nǹkan lásìkò?
1 Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe nǹkan lákòókò tó yẹ. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ “ní àkókò tí ó tọ́.” (Héb. 4:16) Ó tún máa ń fún wa ní “oúnjẹ [tẹ̀mí] ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mát. 24:45) Ìdí nìyẹn tó fi dá wa lójú pé ọjọ́ ìbínú rẹ̀ tó ń bọ̀ “kì yóò pẹ́.” (Háb. 2:3) Àǹfààní ńlá mà ló jẹ́ fún wa o pé Jèhófà máa ń ṣe nǹkan lásìkò! (Sm. 70:5) Àmọ́, nítorí pé ẹ̀dá aláìpé ni wá, ọwọ́ wa sì máa ń dí lọ́pọ̀ ìgbà, kì í rọrùn fún wa láti máa dé síbi tá a bá fẹ́ lọ lásìkò. Kí nìdí tó fi yẹ kó mọ́ wa lára láti máa dé lásìkò?
2. Kí nìdí tí ṣíṣe nǹkan lásìkò fi máa ń bọlá fún Jèhófà?
2 Ó ti wá túbọ̀ ṣòro fún àwọn èèyàn láti máa ṣe nǹkan lásìkò láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí torí pé àwọn èèyàn ti di olùfẹ́ ara wọn, wọn kò sì lè kó ara wọn níjàánu. (2 Tím. 3:1-3) Torí náà, tí àwa Kristẹni kì í bá pẹ́ lẹ́yìn, yálà ní ibi iṣẹ́, tá a bá ní àdéhùn tàbí ní àwọn ìpàdé, àwọn ẹlòmíì máa ń kíyè sí i, èyí sì máa bọlá fún Jèhófà. (2 Pét. 2:12) Ṣé a sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ lásìkò, àmọ́ tá a wá rí i pé lọ́pọ̀ ìgbà a máa ń pẹ́ dé sí àwọn ibi tá a ti ń jọ́sìn Ọlọ́run? Tá a bá ń dé sí ìpàdé lásìkò, tí orin àti àdúrà ìbẹ̀rẹ̀ ṣojú wa, ìyẹn fi hàn pé ó wù wá láti fara wé Baba wa ọ̀run Ẹni tó máa ń ṣe nǹkan létòlétò.—1 Kọ́r. 14:33, 40.
3. Tá a bá ń dé lásìkò, báwo lèyí ṣe fi hàn pé à ń gba tàwọn ẹlòmíì rò?
3 Tá a bá ń dé lásìkò, ṣe là ń fi hàn pé a gba tàwọn ẹlòmíì rò. (Fílí. 2:3, 4) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá máa ń tètè dé sípàdé ìjọ, tó fi mọ́ ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ó máa jẹ́ kí ọkàn àwọn ará tó kù balẹ̀. Àmọ́, táwọn èèyàn bá ti mọ̀ wá sí apẹ́lẹ́yìn, ohun tá à ń sọ fún àwọn míì ni pé àwọn ni ò rí nǹkan fàkókò wọn ṣe ni wọ́n ṣe tètè dé. Téèyàn bá ń dé lásìkò, ó fi hàn pé onítọ̀hún ṣeé gbára lé, ó jẹ́ aláápọn, ó sì ṣeé fọkàn tán. Àwọn èèyàn sì máa ń mọyì àwọn ìwà yìí.
4. Tá a bá máa ń pẹ́ lẹ́yìn, kí la lè ṣe sí i?
4 Tó o bá máa ń pẹ́ lẹ́yìn, ó yẹ kó o ronú lórí ohun tó fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀. Ṣètò àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe, má sì jẹ́ kó pọ̀ jù, kó o lè parí gbogbo rẹ̀ lásìkò tó yẹ. (Oníw. 3:1; Fílí. 1:10) Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. (1 Jòh. 5:14) Tá a bá ń ṣe nǹkan lásìkò, ńṣe là ń fi hàn pé a mọyì Òfin méjì tó tóbi jù lọ, èyí tó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wa.—Mát. 22:37-39.