ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/07 ojú ìwé 8
  • Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Tí Jésù Fi Lélẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Tí Jésù Fi Lélẹ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Pé Jọ Láti Jọ́sìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Kọ́ Àwọn Ọlọ́kàn Tútù Láti Máa Rìn Lọ́nà Tí Ọlọ́run Fẹ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ṣé O Máa Ń Mú Kí Àwọn Ìpàdé Ìjọ Gbéni Ró?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ìpàdé Máa Ń Ṣe Àwọn Ọ̀dọ́ Láǹfààní
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 9/07 ojú ìwé 8

Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Tí Jésù Fi Lélẹ̀

1. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀?

1 Bá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, a gbọ́dọ̀ máa rántí pé ọ̀nà tá a gbà ń ṣe é lè ní ipa tó lágbára lórí àwọn tó ń wò wá. Jésù kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ àtohun tó ṣe. Ìyẹn làwọn èèyàn tó ń wò ó fi mọ̀ pé ó ní ìtara, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó sì gbájú mọ́ bó ṣe máa mú kí orúkọ Bàbá rẹ̀ di mímọ́, ó sì pinnu láti ṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ láṣeyọrí.—1 Pét. 2:21.

2. Láwọn ọ̀nà wo ni àpẹẹrẹ tá a bá fi lélẹ̀ lè gbà nípa lórí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí?

2 Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù Ilé-dé-Ilé: Bíi ti Jésù, àpẹẹrẹ táwa náà ń fi lélẹ̀ lè ran àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Báwọn akéde tuntun àtàwọn akéde tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọwọ́ iṣẹ́ ìwàásù bá rí wa tá à ń fìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, á mú káwọn náà ṣàyẹ̀wò ọwọ́ tí wọ́n fi mú iṣẹ́ ìwàásù. Bí wọ́n bá rí wa tá à ń láyọ̀ tá a sì ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wá lógún, wọ́n á lè máa rántí bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé káwọn náà jẹ́ aláyọ̀ àtẹni tí ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì máa ń jẹ lógún lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Bí wọ́n bá sì rí ọ̀nà tó já fáfá tá a gbà ń lo Ìwé Mímọ́, bá a ṣe ń ṣe ìpadàbẹ̀wò àti bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, á wu àwọn náà láti máa ṣe bá a ṣe ń ṣe.

3. Ọ̀nà wo ni àpẹẹrẹ tiwa lè gbà jẹ́ àwòkọ́ṣe fáwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí nìyẹn sì lè fi kọ́ wọn?

3 Tó O Bá Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: Ó kéré tán, àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń kíyè sí wa. Bí àpẹẹrẹ, a lè ti ṣàlàyé fún wọn tẹ́lẹ̀ pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn sílẹ̀, kí wọ́n máa ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́, kí wọ́n sì tún máa fàlà sábẹ́ àwọn kókó tó bá ṣe pàtàkì, wọ́n á mọ̀ báwa alára ò bá múra sílẹ̀. (Róòmù 2:21) Tá a bá ń pa àdéhùn mọ́, àwọn pàápàá ò ní fẹ́ kí nǹkan míì dí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn lọ́wọ́. Kò sí àní-àní pé àwọn náà á kíyè sí bá a ṣe ń yọ̀ǹda ara wa láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti bí ìgbàgbọ́ wa ṣe lágbára tó. Kò yà wá lẹ́nu pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tímọ́tímọ́ bá kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ sábà máa ń di òjíṣẹ́ onítara tí iṣẹ́ wọn máa ń sèso rere.

4. Ẹ̀kọ́ wo ni ohun tá a bá ṣe nípàdé ń kọ́ àwọn ẹlòmíì?

4 Láwọn Ìpàdé Ìjọ: Gbogbo Kristẹni ló ń kọ́ni nípasẹ̀ fífi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ láwọn ìpàdé ìjọ. Àwọn olùfìfẹ́hàn tó ń wá sípàdé máa ń jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ rere tá à ń fi lélẹ̀ nínú ìjọ. Wọ́n máa ń kíyè sí bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wa, bá a ṣe wà níṣọ̀kan àti bá a ṣe ń múra lọ́nà tó bójú mu. (Sm. 133:1) Wọ́n tún máa ń kíyè sí bí a kì í ṣeé pa ìpàdé ìjọ jẹ àti bá a ṣe máa ń ṣe ìpolongo ìrètí wa ní gbangba. Ọkùnrin kan tó wá sípàdé wa kíyè sí bí ọmọbìnrin kékeré kan ṣe tètè rí ẹsẹ Bíbélì tí olùbánisọ̀rọ̀ pè àti bó ṣe ń fojú bá a lọ nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ ń kà á. Ohun tí ọmọbìnrin yìí ṣe ló mú kí ẹni náà sọ pé ká máa wá kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

5. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fojú kéré àpẹẹrẹ tá à ń fi lélẹ̀?

5 Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tó dáa táwọn ẹlòmíì bá fi lélẹ̀. (Fílí. 3:17; Héb. 13:7) Nígbà náà, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù dáadáa, àwọn ẹlòmíì á rí wa, èyí á sì wá mú káwọn náà máa ṣe ohun tó tọ́. Pẹ̀lú èyí lọ́kàn wa, ǹjẹ́ ká máa fi ọ̀rọ̀ inú 1 Tímótì 4:16 sọ́kàn pé: “Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́