ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/99 ojú ìwé 2-7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 10/99 ojú ìwé 2-7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù October: Gbogbo èdè—Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Àwọn ìwé ìròyìn ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù fún ọdún kan: ₦320; nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́, ₦450. Ẹlẹ́ẹ̀kan lóṣù fún ọdún kan tàbí ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù fún oṣù mẹ́fà: ₦160; nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́, ₦225. November: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. December: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ìjọ bá ní tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1986. Àwọn ìjọ tí kò bá ní irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ lè fi ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọni.

◼ “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ti Ọdún 2000” ni àkìbọnú tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí, kí a tọ́jú rẹ̀ kí a lè rí i lò jálẹ̀ ọdún 2000.

◼ Bí àwọn àkókò tí ìjọ yín máa ń ṣe ìpàdé yóò bá yí padà ní January 1, ó lè pọndandan pé kí ẹ béèrè fún àwọn ìwé ìléwọ́ tuntun láti fi àwọn àkókò ìpàdé tó yí padà hàn.

◼ Ní ti iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, a ń pèsè àwọn ìránnilétí tó tẹ̀ lé e yìí:

○ Kí a ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ nígbà tí aṣáájú ọ̀nà déédéé kan bá ṣíwọ́ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà. Ìfilọ̀ ṣókí náà lè lọ báyìí pé: “Èyí ni láti fi tó ìjọ létí pé [orúkọ] kò sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé mọ́.”

○ Òjìlélẹ́gbẹ̀rin [840] wákàtí la ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé lọ́dún.

○ Odindi ọdún kan ti gbọ́dọ̀ kọjá lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ bá bá ẹnì kan wí tàbí lẹ́yìn tí a bá gba ẹnì kan padà kí a tó lè gbà á fún iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú ọ̀nà déédéé.—Wo Àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1986, ìpínrọ̀ 21 àti 23.

◼ Kó lè túbọ̀ rọrùn fún Society láti máa bójú tó lẹ́tà rẹ, máa ṣe àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí: (1) Kọ orúkọ àti àdírẹ́sì rẹ sí apá ọ̀tún lókè lẹ́tà rẹ. (2) Buwọ́ lu lẹ́tà rẹ ní ìparí, kí o sì kọ orúkọ rẹ sí abẹ́ ibi tí o buwọ́ lù náà níwọ̀n bó ti jẹ́ pé a lè máà lóye ìbuwọ́lù náà, a sì lè má lè ka orúkọ ẹni tó buwọ́ lù ú. A kì í ka àwọn lẹ́tà tí a ò bá buwọ́ lù tàbí tí a ò kọ orúkọ sí kún nítorí wọn ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Bó bá jẹ́ pé ṣe lo tẹ lẹ́tà rẹ, kì í ṣe orúkọ rẹ nìkan ni wàá tẹ̀ sí ìsàlẹ̀ rẹ̀ nítorí ẹnikẹ́ni ló lè tẹ lẹ́tà kan kó sì tẹ orúkọ rẹ sí ìsàlẹ̀ rẹ̀. Kí o buwọ́ lù ú lókè orúkọ tí o tẹ̀ náà. Kí o tó fi ìwé èyíkéyìí ránṣẹ́ sí Society, jọ̀wọ́ ṣàtúnyẹ̀wò rẹ̀ láti rí i dájú pé o tẹ̀ lé àwọn kókó méjì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́