Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Oṣù October
ÀKÍYÈSÍ: Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yóò ṣètò Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní àkókò àpéjọpọ̀. Kí àwọn ìjọ ṣe àtúnṣe tó yẹ láti fàyè sílẹ̀ fún lílọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run,” lẹ́yìn náà, kí wọ́n sì ṣètò fún àtúnyẹ̀wò ọlọ́gbọ̀n ìṣẹ́jú lórí àwọn kókó pàtàkì inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Ṣíṣe àtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti àpéjọpọ̀ àgbègbè náà ni kí a yàn ṣáájú fún àwọn arákùnrin títóótun mẹ́ta tí wọ́n á lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn kókó pàtàkì. Àtúnyẹ̀wò tí a múra sílẹ̀ dáadáa yìí yóò ran ìjọ lọ́wọ́ láti rántí àwọn kókó pàtàkì tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn yóò fi sílò, tí wọn óò sì lò nínú pápá. Àlàyé èyíkéyìí láti ọ̀dọ̀ àwùjọ àti ìrírí tí wọn óò mẹ́nu kàn gbọ́dọ̀ ṣe ṣókí, kó sì ṣe tààràtà.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 4
Orin 147
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ táa yàn látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: “Pípadà Bẹ Àwọn Tó Fìfẹ́ Hàn Wò Ṣe Pàtàkì Nínú Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn.” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
20 min: “Kópa Nínú Ìpolongo Àsansílẹ̀ Owó Tó Kẹ́sẹ Járí.” Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bójú tó o lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Fún àwọn akéde níṣìírí láti gbé góńgó fífi àsansílẹ̀ owó sóde kalẹ̀. Tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì kíkọ ọ̀rọ̀ kún àwọn fọ́ọ̀mù àsansílẹ̀ owó lọ́nà títọ́ àti fífi wọ́n ránṣẹ́ ní kánmọ́.
Orin 130 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 11
Orin 194
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò àti ìrírí látinú iṣẹ́ ìsìn pápá.
15 min: Àìní àdúgbò.
20 min: Jẹ́ Kí Fífi Ìwé Ìròyìn Sóde Jẹ Ọ́ Lógún! Sọ àròpọ̀ iye ìwé ìròyìn tí ìjọ fi sóde lóṣù tó kọjá. Mélòó lèyí jẹ́ lára gbogbo èyí tí ẹ rí gbà látọ̀dọ̀ Society? Bí iye tí ẹ fi sóde bá kéré gan-an sí iye tí ẹ ń gbà, kí ló yẹ kí ẹ ṣe? Sọ pé kí àwùjọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí: (1) Kí akéde kọ̀ọ̀kan béèrè fún ìwé ìròyìn tí ó tó tí ó sì yẹ wẹ́kú. (2) Máa ka gbogbo ọjọ́ Saturday sí Ọjọ́ Ìwé Ìròyìn. (3) Ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ ìsìn tìẹ láti fi iṣẹ́ ìwé ìròyìn kún un ní gbogbo oṣù. (4) Wéwèé láti túbọ̀ máa jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà ní lílo ìwé ìròyìn láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. (5) Mú ìwé ìròyìn tó ní àwọn àpilẹ̀kọ tí a dìídì kọ fún àwọn oníṣòwò àti àwọn amọṣẹ́dunjú tó ṣeé ṣe kí wọ́n fẹ́ràn lọ fún wọn. (6) Ní àkọsílẹ̀ pípéye nípa àwọn tí o fi sóde, wá àwọn tí wàá máa mú ìwé ìròyìn lọ fún déédéé, kí o sì máa mú àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lọ fún wọn. (7) Lo àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn ògbólógbòó lọ́nà rere kí wọ́n má bàa ṣẹ́ jọ. Fi àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ hàn, kí o sì tọ́ka sí àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kó ru ìfẹ́ sókè. Jẹ́ kí àgbàlagbà kan ṣàṣefihàn fífi ìwé ìròyìn lọni ní ṣókí, kí o sì jẹ́ kí èwe kan náà ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.—Wo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1996.
Orin 105 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 18
Orin 196
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: “Ṣé Ò Ń Kó Lọ Síbòmíràn?” Àsọyé tí ń fúnni níṣìírí tí akọ̀wé sọ. Nígbà tí àwọn akéde bá rí i pé ó pọndandan fún àwọn láti ṣí lọ sí ìjọ mìíràn, ó ṣe pàtàkì kí a mọ̀ wọ́n dáadáa ní àgbègbè tuntun tí wọ́n ṣí lọ kí wọ́n lè dènà ìfàsẹ́yìn èyíkéyìí nípa tẹ̀mí. Tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn alàgbà mọ̀ nípa irú ìwéwèé bẹ́ẹ̀ kí wọ́n sì béèrè ìrànwọ́ wọn nípa bí àwọn ṣe lè kàn sí ìjọ àwọn tuntun.
20 min: “Bí Àwọn Ìpàdé Ṣe Lè Fún Wa Ní Ìdùnnú Púpọ̀ Sí I.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ àwọn àpẹẹrẹ pàtó nípa bí a ṣe lè gba tàwọn ẹlòmíràn rò kí a sì máa fún ara wa níṣìírí nínú àwọn ìpàdé. Sọ pé kí àwùjọ sọ àpẹẹrẹ láti inú àwọn ìrírí tiwọn.
Orin 152 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 25
Orin 179
15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ran gbogbo akéde lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ láti fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀ lọni ní oṣù November. Ṣàlàyé bí a ṣe lè múra ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó ṣàlàyé ìbéèrè yìí pé, “Ṣé Ọlọ́run ń dáhùn àdúrà?” Lo àwọn kókó tó wà ní ẹ̀kọ́ 7 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà tàbí èyí tó wà ní orí 16, ìpínrọ̀ 12 sí 14, nínú ìwé náà. Ṣàṣefihàn ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rírọrùn kan tó ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan.
15 min: Wíwá Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Táa Gbé Karí Bíbélì. Akéde kan, tó bá olùfìfẹ́hàn kan tó béèrè ìbéèrè kan láti inú Bíbélì pàdé, lọ bá ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan. Dípò sísọ ohun tí ó jẹ́ ìdáhùn, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ṣàlàyé bí akéde náà ṣe lè rí ìdáhùn. Lákọ̀ọ́kọ́, ó ṣàtúnyẹ̀wò àwọn àbá tí ó wà nínú Iwe-Amọna, ìkẹ́kọ̀ọ́ 7, ìpínrọ̀ 8 àti 9. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n wá jọ ṣàyẹ̀wò nípa ìbéèrè kan tí àwọn èèyàn sábà máa ń béèrè ní ìpínlẹ̀ wọn. Wọ́n wo àwọn ìtọ́kasí kan tó sọ̀rọ̀ nípa kókó náà, wọ́n sì rí àwọn kókó tí ń yíni lérò padà tó ṣàlàyé ìdí tí Bíbélì fi dáhùn bẹ́ẹ̀. Fún àwùjọ níṣìírí láti máa ṣe irú ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ń mérè wá yìí láti máa ṣàyẹ̀wò àwọn ìbéèrè Bíbélì.
15 min: Àwọn Góńgó Tí A Lè Gbé Kalẹ̀. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn góńgó tó ṣeé lé bá táa tò lẹ́sẹẹsẹ sínú àpótí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ March 15, 1997, ojú ìwé 11. Fún àwùjọ níṣìírí láti kópa nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ṣàlàyé bí lílé àwọn góńgó wọ̀nyí bá ṣe lè ṣe wá láǹfààní lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Sọ pé kí àwùjọ sọ ìdùnnú tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n lé àwọn góńgó kan tó jẹ́ ti ìṣàkóso Ọlọ́run bá.
Orin 151 àti àdúrà ìparí.