Bí Àwọn Ìpàdé Ṣe Lè Fún Wa Ní Ìdùnnú Púpọ̀ Sí I
1 Àwọn ìpàdé ṣe kókó fún ìlera wa nípa tẹ̀mí. Ayọ̀ tí a ń rí nínú wọn sinmi ní tààràtà lórí ohun tí a bá ṣe ṣáájú ìpàdé, nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́ àti lẹ́yìn ìpàdé. Báwo la ṣe lè ran ara wa àti àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mú kí ayọ̀ tí wọ́n ń ní nígbà tí wọ́n bá wá sí ìpàdé pọ̀ jọjọ?
2 Ṣáájú Ìpàdé: Ìmúrasílẹ̀ máa ń ní ipa tààràtà lórí bí a ṣe ń gbádùn àwọn ìpàdé sí. Báa bá múra sílẹ̀ dáadáa, àá tún lè fiyè sílẹ̀ dáadáa, àá sì lè kópa nínú ìpàdé. Ní àfikún sí i, ó yẹ kí a máa múra iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá yàn fún wa ní ìpàdé dáadáa, ká ní in lọ́kàn pé a fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́nà pípéye bí wọ́n ṣe fún wa nítọ̀ọ́ni pé ká sọ ọ́ kí a sì fa àwùjọ lọ́kàn mọ́ra. Ká fi dánrawò dáadáa. Bí a bá ṣe ipa tiwa láti mú kí ìpàdé gbádùn mọ́ni kó sì gbéni ró lọ́nà tí ń ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní, ìtẹ̀síwájú ti àwa fúnra wa yóò máa fara hàn kedere, a óò sì túbọ̀ máa láyọ̀.—1 Tím. 4:15, 16.
3 Nígbà Tí Ìpàdé Ń Lọ Lọ́wọ́: Dídáhùn ní àwọn ìpàdé lè jẹ́ ká túbọ̀ máa gbádùn wọn. Àwọn apá ìpàdé tó ń béèrè pé kí àwùjọ lóhùn sí ni ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ máa wò bí iṣẹ́ tí a yàn fún òun. Ìdáhùn tó ṣe ṣókí tó sì sojú abẹ níkòó ló máa ń dára jù lọ. Sísọ àwọn ìrírí tó ṣe ṣókí máa ń fúnni níṣìírí gidigidi, ó ń tani jí, ó sì yẹ ká máa fi èyí kún un nígbàkígbà tó bá yẹ. (Òwe 15:23; Ìṣe 15:3) Nígbà tí a bá ń ṣiṣẹ́ ní ìpàdé, ó yẹ ká fi ìtara àti ìdánilójú sọ̀rọ̀, ká mú kó gbádùn mọ́ni, kó bọ́gbọ́n mu, kó sì ṣeé fi sílò.
4 Lẹ́yìn Ìpàdé: Gbogbo wa ni yóò jàǹfààní bí a bá fi inú rere bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀, bí a bá yára mọ́ wọn bí a ṣe ń kí wọn, tí a bá sì bá wọn ṣàjọpín àwọn kókó pàtàkì mélòó kan tí a jíròrò ní ìpàdé. Bí a bá ń fi ayọ̀ wa hàn nígbà tí a bá rí àwọn ọmọdé, àwọn àgbàlagbà, àti àwọn ẹni tuntun tí wọ́n ń kópa nínú àwọn ìpàdé lè mú kí ìfẹ́ ẹgbẹ́ ara jinlẹ̀ sí i. Dípò ṣíṣàríwísí àwọn tó pa ìpàdé jẹ, ṣe ló yẹ ká bá wọn ṣàjọpín ayọ̀ tí a rí nínú lílọ sí ìpàdé, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ máa fún wọn níṣìírí láti máa wá sí ìpàdé.—Heb. 10:24, 25.
5 Ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi àǹfààní ìpèsè ṣíṣe kókó yìí du ara wa, èyí tí a ń rí nínú ṣíṣe pàṣípààrọ̀ ìṣírí. (Róòmù 1:11, 12) Nípa fífi tọkàntọkàn sa gbogbo ipá wa, gbogbo wa lè máa rí ayọ̀ nínú lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni.