Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run Ti Ọdún 2000
Àwọn Ìtọ́ni
Ní ọdún 2000, àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí ni yóò jẹ́ ìṣètò fún dídarí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run.
ÀWỌN ÌWÉ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́: Orí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun [bi12-YR], Ilé Ìṣọ́ [w-YR], àti “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò” gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun [td-YR] la gbé iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ kà.
Kí a bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà LÁKÒÓKÒ, pẹ̀lú orin, àdúrà, àti ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ ṣókí. Kò pọndandan láti mẹ́nu kan nǹkan tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ. Bí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ti ń nasẹ̀ apá kọ̀ọ̀kan, yóò sọ kókó ọ̀rọ̀ tí a óò jíròrò. Tẹ̀ lé ìlànà tó tẹ̀ lé e yìí:
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ: Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni kó bójú tó èyí, a óò sì gbé e ka Ilé Ìṣọ́. Kí a ṣe iṣẹ́ yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìtọ́ni oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, láìsí àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ. Ète rẹ̀ kì í ṣe láti wulẹ̀ kárí ibi tí a yàn fúnni, bí kò ṣe láti pa àfiyèsí pọ̀ sórí bí ìsọfúnni tí a ń jíròrò ṣe wúlò, ní títẹnu mọ́ ohun tí yóò ṣe ìjọ láǹfààní jù lọ. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a yàn ni kí a lò.
Àwọn arákùnrin tí a yan iṣẹ́ yìí fún ní láti ṣọ́ra láti má ṣe kọjá àkókò tí a fún wọn. A lè fún wọn ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́ bó bá pọndandan tàbí bí olùbánisọ̀rọ̀ bá béèrè fún un.
ÀWỌN KÓKÓ PÀTÀKÌ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ KÍKÀ: Ìṣẹ́jú mẹ́fà. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni kó bójú tó o, kó sì mú kí àkójọ ọ̀rọ̀ náà bá àwọn àìní àdúgbò mu lọ́nà tó gbéṣẹ́. Kò pọndandan pé kó lẹ́ṣin ọ̀rọ̀. Èyí kò ní wulẹ̀ jẹ́ àkópọ̀ lórí ibi tí a yàn fún kíkà. A lè ṣe àkópọ̀ àlàyé aláàbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan, lórí gbogbo orí tí a yàn. Ṣùgbọ́n, olórí ète náà ni láti ran àwùjọ lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí ìsọfúnni náà fi ṣeyebíye fún wa àti bí ó ti ṣeyebíye tó fún wa. Lẹ́yìn náà, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò yọ̀ǹda àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ láti lọ sí kíláàsì wọn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KEJÌ: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Èyí jẹ́ Bíbélì kíkà lórí ibi tí a yàn fúnni tí arákùnrin kan yóò bójú tó. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ kìíní àti ní àwùjọ kejì tó jẹ́ àfikún. Ìwé kíkà tí a yàn fún akẹ́kọ̀ọ́ sábà máa ń mọ níwọ̀n tí yóò jẹ́ kó lè ṣe àlàyé ṣókí ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀. A lè fi ìtàn tó yí àwọn ẹsẹ náà ká, ìjẹ́pàtàkì àsọtẹ́lẹ̀ tàbí ẹ̀kọ́ inú rẹ̀, àti bí àwọn ìlànà rẹ̀ ṣe kàn wá kún un. Kí ó ka gbogbo ẹsẹ tí a yàn fún un pátá, láìdánudúró lágbede méjì láti ṣàlàyé ohunkóhun. Àmọ́ ṣá o, níbi tí àwọn ẹsẹ tí yóò kà kò bá ti tẹ̀ léra, akẹ́kọ̀ọ́ náà lè sọ ẹsẹ tí yóò ti máa bá Bíbélì kíkà náà lọ.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸTA: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Arábìnrin ni a óò yan èyí fún. A óò gbé kókó ẹ̀kọ́ iṣẹ́ yìí ka “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò” gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. A lè gbé e kalẹ̀ lọ́nà ìjẹ́rìí aláìjẹ́-bí-àṣà, ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, àwọn tí ń kópa sì lè jókòó tàbí kí wọ́n dúró. Ọ̀nà tí akẹ́kọ̀ọ́ gbà ṣàlàyé ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a yàn fún un, àti ọ̀nà tó gbà ran onílé lọ́wọ́ láti ronú lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ni yóò jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ́kàn jù lọ. Akẹ́kọ̀ọ́ tí a yan iṣẹ́ yìí fún gbọ́dọ̀ mọ̀wéékà. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò ṣètò fún olùrànlọ́wọ́ kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n a lè lo olùrànlọ́wọ́ mìíràn ní àfikún. Ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tí a gbà lo Bíbélì ni ká fún ní àfiyèsí pàtàkì, kì í ṣe ọ̀nà tí a gbà gbé e kalẹ̀.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸRIN: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Kókó ọ̀rọ̀ fún iṣẹ́ yìí ni a óò gbé kárí “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò” gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a yàn ni ká lò, kí akẹ́kọ̀ọ́ sì sakun láti sọ bí a ṣe lè fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sílò. A lè yan Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin fún arákùnrin tàbí arábìnrin. Nígbà tí a bá yàn án fún arákùnrin, àsọyé ni kó fi sọ. Nígbà tí a bá yàn án fún arábìnrin, kó sọ ọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àlàyé tí a ṣe fún Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹta. Ní àfikún sí i, bí a bá fi àmì yìí, #, ṣáájú ẹṣin ọ̀rọ̀ fún Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin, ó dáa pé kó jẹ́ arákùnrin ni a óò yàn án fún.
*ÀFIKÚN ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ BÍBÉLÌ KÍKÀ: A fi èyí sínú àwọn àkámọ́ lẹ́yìn nọ́ńbà orin fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Nípa títẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí, ní kíka nǹkan bí ojú ìwé mẹ́wàá lọ́sẹ̀, a lè ka Bíbélì látòkè délẹ̀ ní ọdún mẹ́ta. A kò gbé apá kankan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ tàbí àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀ karí àfikún ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà yìí.
Ọ̀RỌ̀ ÀKÍYÈSÍ: Fún àfikún ìsọfúnni àti ìtọ́ni lórí ìmọ̀ràn, ìdíwọ̀n àkókò, àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, àti mímúra àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀, jọ̀wọ́ wo ojú ìwé kẹta nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1996.
ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ
Jan. 3 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 4 sí 6
Orin 9 [*Jeremáyà 49 sí 52]
No. 1: Mọrírì Àwọn Ìbùkún Jèhófà (w98-YR 1/1 ojú ìwé 22 sí 24)
No. 2: Diutarónómì 6:4-19
No. 3: td-YR 22A Ìdí Tí Ọlọ́run Kò Fi Tẹ́wọ́ Gba Ìjọsìn Àwọn Baba Ńlá
No. 4: td-YR 22B A Lè Bọlá fún Ẹ̀dá Ènìyàn, Ṣùgbọ́n Ọlọ́run Nìkan Ni A Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn
Jan. 10 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 7 sí 10
Orin 49 [*Ìdárò 1 sí 5]
No. 1: Gbé Ọlọ́run Tòótọ́ Ga (w98-YR 1/1 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: Diutarónómì 8:1-18
No. 3: td-YR 4A Amágẹ́dónì—Ogun Tí Yóò Fi Òpin sí Ìwà Burúkú
No. 4: td-YR 4B Ìdí Tí Amágẹ́dónì Fi Jẹ́ Ìgbésẹ̀ Onífẹ̀ẹ́ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
Jan. 17 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 11 sí 14
Orin 132 [*Ìsíkíẹ́lì 1 sí 9]
No. 1: Ìdí Tó Fi Yẹ Láti Wéwèé Ṣáájú fún Àwọn Olólùfẹ́ Wa (w98-YR 1/15 ojú ìwé 19 sí 22)
No. 2: Diutarónómì 11:1-12
No. 3: td-YR 17A Ìbatisí—Ohun Kan Tí A Ń Béèrè Lọ́wọ́ Kristẹni
No. 4: td-YR 17B Ìbatisí Kò Wẹ Ẹ̀ṣẹ̀ Nù
Jan. 24 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 15 sí 19
Orin 162 [*Ìsíkíẹ́lì 10 sí 16]
No. 1: Agbára Òtítọ́ Tí Ń Yíni Padà, Tó sì Ń Múni Ṣọ̀kan (w98-YR 1/15 ojú ìwé 29 sí 31)
No. 2: Diutarónómì 19:11-21
No. 3: td-YR 8A Bíbélì Jẹ́ Ọ̀rọ̀ Onímìísí ti Ọlọ́run
No. 4: td-YR 8B Bíbélì—Amọ̀nà Wíwúlò fún Ọjọ́ Wa
Jan. 31 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 20 sí 23
Orin 13 [*Ìsíkíẹ́lì 17 sí 21]
No. 1: Ohun Tí Ìwé Mímọ́ Sọ Nípa Ìyìn àti Ìpọ́nni (w98-YR 2/1 ojú ìwé 29 sí 31)
No. 2: Diutarónómì 20:10-20
No. 3: td-YR 8D Bíbélì—Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
No. 4: td-YR 11A Gbígba Ẹ̀jẹ̀ Sára Rú Òfin Ìjẹ́mímọ́ Ẹ̀jẹ̀
Feb. 7 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 24 sí 27
Orin 222 [*Ìsíkíẹ́lì 22 sí 27]
No. 1: Ìdí fún Níní Ẹ̀mí Nǹkan-Yóò-Dára Tòótọ́ (w98-YR 2/1 ojú ìwé 4 sí 6)
No. 2: Diutarónómì 25:5-16
No. 3: td-YR 11B A Ha Gbọ́dọ̀ Dáàbò Bo Ẹ̀mí Ẹni Lọ́nàkọnà?
No. 4: td-YR 30A Ìgbà Wo Ni Àwọn Àkókò Kèfèrí Dópin?
Feb. 14 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 28 sí 30
Orin 180 [*Ìsíkíẹ́lì 28 sí 33]
No. 1: Mú Ẹ̀mí Ìmoore Dàgbà (w98-YR 2/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Diutarónómì 28:1-14
No. 3: td-YR 43A Kí Ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni Jẹ́?
No. 4: td-YR 43B Ṣé Pétérù ni “Àpáta Ràbàtà”?
Feb. 21 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 31 sí 34
Orin 46 [*Ìsíkíẹ́lì 34 sí 39]
No. 1: w84-YR 8/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 8
No. 2: Diutarónómì 32:35-43
No. 3: td-YR 29A Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Tòótọ́ Ti Àkọsílẹ̀ Ìṣẹ̀dá Bíbélì Lẹ́yìn
No. 4: td-YR 29B Ṣé Sáà Wákàtí Mẹ́rìnlélógún Ni Gígùn Ọjọ́ Ìṣẹ̀dá Kọ̀ọ̀kan?
Feb. 28 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 1 sí 5
Orin 40 [*Ìsíkíẹ́lì 40 sí 45]
No. 1: w84-YR 11/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 3
No. 2: Jóṣúà 2:8-16
No. 3: td-YR 2A Ṣé Orí Àgbélébùú Ni Jésù Kú Sí?
No. 4: td-YR 2B Ṣé Ó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Jọ́sìn Àgbélébùú?
Mar. 6 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 6 sí 9
Orin 164 [*Ìsíkíẹ́lì 46 sí Dáníẹ́lì 2]
No. 1: Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín! (w98-YR 2/15 ojú ìwé 8 sí 11)
No. 2: Jóṣúà 7:1, 10-19
No. 3: td-YR 24A Kí Ló Ń Fa Ikú?
No. 4: td-YR 24B Ṣé Òkú Lè Pa Ọ́ Lára?
Mar. 13 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 10 sí 13
Orin 138 [*Dáníẹ́lì 3 sí 7]
No. 1: Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Òòfà Agbára Ìdánilọ́rùn (w98-YR 2/15 ojú ìwé 23 sí 27)
No. 2: Jóṣúà 11:6-15
No. 3: td-YR 24D Ṣé Àwọn Èèyàn Lè Bá Àwọn Ìbátan Wọn Tó Ti Kú Sọ̀rọ̀?
No. 4: td-YR 10A Èṣù Ha Jẹ́ Ẹni Gidi Bí?
Mar. 20 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 14 sí 17
Orin 10 [*Dáníẹ́lì 8 sí Hóséà 2]
No. 1: Àwọn Èèyàn Olùṣòtítọ́ “Tí Ó Ní Ìmọ̀lára Bí Tiwa” (w98-YR 3/1 ojú ìwé 26 sí 29)
No. 2: Jóṣúà 15:1-12
No. 3: td-YR 10B Èṣù—Ẹni Tí A Kò Lè Rí Tí Ń Ṣàkóso Ayé
No. 4: td-YR 10D Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì Tó Rẹ Ara Wọn Nípò Wálẹ̀
Mar. 27 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 18 sí 20
Orin 105 [*Hóséà 3 sí 14]
No. 1: Mímú Àwọn Ọjọ́ Tí Jésù Lò Kẹ́yìn Lórí Ilẹ̀ Ayé Wá sí Ìrántí (w98-YR 3/15 ojú ìwé 3 sí 9)
No. 2: Jóṣúà 18:1-10
No. 3: td-YR 25A Ilẹ̀ Ayé—A Dá A Láti Jẹ́ Párádísè
No. 4: td-YR 25B Ìyè Lórí Ilẹ̀ Ayé Kì Yóò Dópin Láé
Apr. 3 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 21 sí 24
Orin 144 [*Jóẹ́lì 1 sí Ámósì 7]
No. 1: w84-YR 11/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 5
No. 2: Jóṣúà 21:43 sí 22:8
No. 3: td-YR 44A Ǹjẹ́ O Lè Dá Àwọn Wòlíì Èké Mọ̀?
No. 4: td-YR 32A Báwo Ni Ìwòsàn Tẹ̀mí Ti Ṣe Pàtàkì Tó?
Apr. 10 Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 1 sí 4
No. 1: w85-YR 1/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 2
No. 2: Àwọn Onídàájọ́ 3:1-11
No. 3: td-YR 32B Ìjọba Ọlọ́run—Yóò Mú Ìwòsàn ti Ara Wíwàpẹ́títí Wá
No. 4: td-YR 32D Ìgbàgbọ́ Wò-ó-sàn Òde Òní Kò Ti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wá
Apr. 17 Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 5 sí 7
Orin 193 [*Míkà 6 sí Sefanáyà 1]
No. 1: Kẹ́kọ̀ọ́ Láti inú Ìtọ́ni Tí Jésù Fún Àwọn Àádọ́rin Ọmọ Ẹ̀yìn (w98-YR 3/1 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: Àwọn Onídàájọ́ 5:24-31
No. 3: td-YR 32E Fífi Ahọ́n Àjèjì Sọ̀rọ̀ Ha Jẹ́ Ẹ̀rí Dídájú Pé A Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run?
No. 4: td-YR 41A Àwọn Wo Ló Ń Lọ Sọ́run?
Apr. 24 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Parí Diutarónómì 4 sí Àwọn Onídàájọ́ 7
Orin 91 [*Sefanáyà 2 sí Sekaráyà 7]
May 1 Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 8 sí 10
Orin 38 [*Sekaráyà 8 sí Málákì 4]
No. 1: Bọ̀wọ̀ fún Iyì Ara Ẹni Àwọn Ẹlòmíràn (w98-YR 4/1 ojú ìwé 28 sí 31)
No. 2: Àwọn Onídàájọ́ 9:7-21
No. 3: td-YR 16A Hẹ́ẹ̀lì Kì Í Ṣe Ibi Ìdálóró
No. 4: td-YR 16B Iná Ń Ṣàpẹẹrẹ Ìparun Yán-ányán-án
May 8 Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 11 sí 14
Orin 82 [*Mátíù 1 sí 8]
No. 1: Bánábà, “Ọmọ Ìtùnú” (w98-YR 4/15 ojú ìwé 20 sí 23)
No. 2: Àwọn Onídàájọ́ 13:2-10, 24
No. 3: td-YR 16D Ìròyìn Nípa Ọlọ́rọ̀ àti Lásárù Kì Í Ṣe Ẹ̀rí Ìdálóró Ayérayé
No. 4: td-YR 38A Ojú Ìwòye Kristẹni Nípa Àwọn Ayẹyẹ
May 15 Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 15 sí 18
Orin 26 [*Mátíù 9 sí 14]
No. 1: Ààbò Ayé Láìsí Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun (w98-YR 4/15 ojú ìwé 28 sí 30)
No. 2: Àwọn Onídàájọ́ 17:1-13
No. 3: td-YR 9A Lílo Àwọn Ère Kò Bọlá fún Ọlọ́run
No. 4: td-YR 9B Àbájáde Jíjọ́sìn Ère
May 22 Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 19 sí 21
Orin 42 [*Mátíù 15 sí 21]
No. 1: w85-YR 1/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 3
No. 2: Àwọn Onídàájọ́ 19:11-21
No. 3: td-YR 9D Jèhófà Nìkan La Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn
No. 4: td-YR 5A #Àmúlùmálà Ìgbàgbọ́ Kì Í Ṣe Ọ̀nà Ọlọ́run
May 29 Bíbélì kíkà: Rúùtù 1 sí 4
Orin 120 [*Mátíù 22 sí 26]
No. 1: w85-YR 3/1 ojú ìwé 20 àti 21
No. 2: Rúùtù 3:1-13
No. 3: td-YR 5B Ṣé Gbogbo Ìsìn Ló Dára?
No. 4: td-YR 34A Àwọn Kristẹni Gbọ́dọ̀ Máa Lo Orúkọ Ọlọ́run Gan-an
June 5 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 1 sí 3
Orin 191 [*Mátíù 27 sí Máàkù 4]
No. 1: w85-YR 1/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 1 sí 5
No. 2: 1 Sámúẹ́lì 1:9-20
No. 3: td-YR 34B Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Wíwà Ọlọ́run
No. 4: td-YR 34D #Mímọ Àwọn Ànímọ́ Ọlọ́run
June 12 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 4 sí 7
Orin 85 [*Máàkù 5 sí 9]
No. 1: Ta Ni Jèhófà? (w98-YR 5/1 ojú ìwé 5 sí 7)
No. 2: 1 Sámúẹ́lì 4:9-18
No. 3: td-YR 34E Kì Í Ṣe Gbogbo Ènìyàn Ní Ń Sin Ọlọ́run Kan Náà
No. 4: td-YR 12A Ṣé Ẹ̀sìn Tuntun Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
June 19 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 8 sí 11
Orin 160 [*Máàkù 10 sí 14]
No. 1: A San Èrè fún Ìwà Títọ́ (w98-YR 5/1 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: 1 Sámúẹ́lì 8:4-20
No. 3: td-YR 35A Jésù Kristi—Ọmọ Ọlọ́run àti Ọba Tí A Yàn
No. 4: td-YR 35B Ìdí Tí Ìgbàgbọ́ Nínú Jésù Fi Ṣe Kókó fún Ìgbàlà
June 26 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 12 sí 14
Orin 172 [*Máàkù 15 sí Lúùkù 3]
No. 1: Ọrọ̀ Ha Lè Mú Ọ Láyọ̀ Bí? (w98-YR 5/15 ojú ìwé 4 sí 6)
No. 2: 1 Sámúẹ́lì 14:1-14
No. 3: td-YR 35D Ṣé Wíwulẹ̀ Gba Jésù Gbọ́ Tó Láti Ní Ìgbàlà?
No. 4: td-YR 21A #Àwọn Ìbùkún Tí Ìjọba Ọlọ́run Yóò Mú Wá
July 3 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 15 sí 17
Orin 8 [*Lúùkù 4 sí 8]
No. 1: Yùníìsì àti Lọ́ìsì—Àwọn Olùkọ́ni Àwòfiṣàpẹẹrẹ (w98-YR 5/15 ojú ìwé 7 sí 9)
No. 2: 1 Sámúẹ́lì 16:4-13
No. 3: td-YR 21B Ìṣàkóso Ìjọba Bẹ̀rẹ̀ Nígbà Tí Àwọn Ọ̀tá Kristi Ṣì Wà Láàyè Síbẹ̀
No. 4: td-YR 21D Ìjọba Ọlọ́run Kò Wá Nípasẹ̀ Àwọn Ìsapá Èèyàn
July 10 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 18 sí 20
Orin 156 [*Lúùkù 9 sí 12]
No. 1: Dé Inú Ọkàn-Àyà Nípasẹ̀ Lílo Ọ̀nà Ìyíniléròpadà (w98-YR 5/15 ojú ìwé 21 sí 23)
No. 2: 1 Sámúẹ́lì 19:1-13
No. 3: td-YR 39A Ohun Tí “Òpin Ayé” Túmọ̀ Sí
No. 4: td-YR 39B #Wà Lójúfò Nípa Tẹ̀mí sí Ẹ̀rí Nípa Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn
July 17 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 21 sí 24
Orin 33 [*Lúùkù 13 sí 19]
No. 1: Gbé Ẹrù Iṣẹ́ Rẹ Nínú Ìdílé (w98-YR 6/1 ojú ìwé 20 sí 23)
No. 2: 1 Sámúẹ́lì 24:2-15
No. 3: td-YR 33A Ìyè Àìnípẹ̀kun Kì Í Ṣe Àlá Lásán
No. 4: td-YR 33B Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?
July 24 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 25 sí 27
Orin 60 [*Lúùkù 20 sí 24]
No. 1: Ìdájọ́ Òdodo—Nígbà Wo àti Lọ́nà Wo? (w98-YR 6/15 ojú ìwé 26 sí 29)
No. 2: 1 Sámúẹ́lì 25:23-33
No. 3: td-YR 33D Àwọn Tí Yóò Gba Ìyè Àìnípẹ̀kun Lórí Ilẹ̀ Ayé Kò Níye
No. 4: td-YR 19A #Ìdè Ìgbéyàwó Gbọ́dọ̀ Ní Ọlá
July 31 Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 28 sí 31
Orin 170 [*Jòhánù 1 sí 6]
No. 1: w85-YR 1/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 1 sí 24 ìpínrọ̀ 3
No. 2: 1 Sámúẹ́lì 31:1-13
No. 3: td-YR 19B Àwọn Kristẹni Gbọ́dọ̀ Bọ̀wọ̀ fún Ìlànà Ipò Orí
No. 4: td-YR 19D Ẹrù Iṣẹ́ Òbí sí Àwọn Ọmọ
Aug. 7 Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 1 sí 4
Orin 22 [*Jòhánù 7 sí 11]
No. 1: w85-YR 1/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 5
No. 2: 2 Sámúẹ́lì 2:1-11
No. 3: td-YR 19E Àwọn Kristẹni Gbọ́dọ̀ Gbé Kìkì Kristẹni Níyàwó
No. 4: td-YR 19Ẹ Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì í Kóbìnrin Jọ
Aug. 14 Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 5 sí 8
Orin 174 [*Jòhánù 12 sí 18]
No. 1: “Ẹ Tiraka Tokuntokun” (w98-YR 6/15 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: 2 Sámúẹ́lì 7:4-16
No. 3: td-YR 23A Màríà Jẹ́ Ìyá Jésù, Kì Í Ṣe “Ìyá Ọlọ́run”
No. 4: td-YR 23B Bíbélì Fi Hàn Pé Màríà Kì Í Ṣe “Wúńdíá Títí Lọ”
Aug. 21 Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 9 sí 12
Orin 107 [*Jòhánù 19 sí Ìṣe 4]
No. 1: Jẹ́ Aládùúgbò Rere (w98-YR 7/1 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: 2 Sámúẹ́lì 11:2-15
No. 3: td-YR 28A Ohun Tí Ìwé Mímọ́ Sọ Nípa Ìṣe Ìrántí
No. 4: td-YR 28B Ṣíṣayẹyẹ Máàsì Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu
Aug. 28 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Parí Àwọn Onídàájọ́ 8 sí 2 Sámúẹ́lì 12
Orin 177 [*Ìṣe 5 sí 10]
Sept. 4 Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 13 sí 15
Orin 183 [*Ìṣe 11 sí 16]
No. 1: Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Lẹ́kọ̀ọ́ Rere Ní Ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbésí Ayé Wọn (w98-YR 7/15 ojú ìwé 4 sí 6)
No. 2: 2 Sámúẹ́lì 13:20-33
No. 3: td-YR 37A Gbogbo Kristẹni Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Òjíṣẹ́
No. 4: td-YR 37B Àwọn Ẹ̀rí Ìtóótun fún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́
Sept. 11 Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 16 sí 18
Orin 129 [*Ìṣe 17 sí 22]
No. 1: Ojú Ìwòye Kristẹni Nípa Àṣà Ìsìnkú (w98-YR 7/15 ojú ìwé 20 sí 24)
No. 2: 2 Sámúẹ́lì 16:5-14
No. 3: td-YR 6A Ìdí Tí A Fi Kórìíra Àwọn Kristẹni Tòótọ́
No. 4: td-YR 6B Aya Kò Gbọ́dọ̀ Gba Ọkọ Rẹ̀ Láyè Láti Ya Òun Nípa sí Ọlọ́run
Sept. 18 Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 19 sí 21
No. 1: Ǹjẹ́ O Lè Gbára Lé Ẹ̀rí-Ọkàn Rẹ? (w98-YR 9/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: 2 Sámúẹ́lì 20:1, 2, 14-22
No. 3: td-YR 6D Ọkọ Kò Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Kí Aya Òun Dí Òun Lọ́wọ́ Sísin Ọlọ́run
No. 4: td-YR 1A Àwọn Àdúrà Tí Ọlọ́run Máa Ń Gbọ́
Sept. 25 Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 22 sí 24
Orin 98 [*Róòmù 2 sí 9]
No. 1: Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí A Lè Rí Kọ́ Láti Inú Ìwé Sámúẹ́lì Kìíní àti Ìkejì (w85-YR 1/15 ojú ìwé 22 sí 25)
No. 2: 2 Sámúẹ́lì 23:8-17
No. 3: td-YR 1B Ìdí Tí Àwọn Àdúrà Kan Kò Fi Lẹ́sẹ̀ Nílẹ̀
No. 4: td-YR 7A A Kò Yan Àyànmọ́ Kankan fún Ènìyàn
Oct. 2 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 1 sí 2
Orin 36 [*Róòmù 10 sí 1 Kọ́ríńtì 3]
No. 1: w85-YR 5/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 1
No. 2: 1 Àwọn Ọba 2:1-11
No. 3: td-YR 27A Ìwàláàyè Jésù bí Ènìyàn Ni A Fi San Ìràpadà fún Gbogbo Ènìyàn
No. 4: td-YR 27B Ìdí Tí Jésù Fi Lè San Ìràpadà Náà
Oct. 9 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 3 sí 6
Orin 106 [*1 Kọ́ríńtì 4 sí 13]
No. 1: Fi Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Ṣáájú (w98-YR 9/1 ojú ìwé 19 sí 21)
No. 2: 1 Àwọn Ọba 4:21-34
No. 3: td-YR 14A Bí A Ṣe Lè Mọ Ẹ̀sìn Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
No. 4: td-YR 14B Ǹjẹ́ Ó Lòdì Láti Wọ́gi Lé Àwọn Ẹ̀kọ́ Èké?
Oct. 16 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 7 sí 8
Orin 76 [*1 Kọ́ríńtì 14 sí 2 Kọ́ríńtì 7]
No. 1: Jíjẹ́rìí Níwájú Àwọn Lóókọ-Lóókọ (w98-YR 9/1 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: 1 Àwọn Ọba 7:1-14
No. 3: td-YR 14D Ìgbà Tí Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gba Yíyí Ẹ̀sìn Ẹni Padà
No. 4: td-YR 14E Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Rí ‘Rere Nínú Gbogbo Ẹ̀sìn’?
Oct. 23 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 9 sí 11
Orin 97 [*2 Kọ́ríńtì 8 sí Gálátíà 4]
No. 1: Ojú Ìwòye Kristẹni Nípa Owó Orí Ìyàwó (w98-YR 9/15 ojú ìwé 24 sí 27)
No. 2: 1 Àwọn Ọba 11:1-13
No. 3: td-YR 3A Àwọn Wo Ni A Óò Jí Dìde Kúrò Nínú Ikú?
No. 4: td-YR 3B Ibo Ni A Óò Jí Àwọn Òkú Dìde Sí?
Oct. 30 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 12 sí 14
Orin 113 [*Gálátíà 5 sí Fílípì 2]
No. 1: Ọlọ́run Ha Jẹ́ Ẹni Gidi sí Ọ Bí? (w98-YR 9/15 ojú ìwé 21 sí 23)
No. 2: 1 Àwọn Ọba 13:1-10
No. 3: td-YR 26A Ìpadàbọ̀ Kristi Kò Ṣeé Fojú Rí
No. 4: td-YR 26B A Fi Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Tí A Lè Fojú Rí Mọ Ìpadàbọ̀ Kristi
Nov. 6 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 15 sí 17
Orin 123 [*Fílípì 3 sí 1 Tẹsalóníkà 5]
No. 1: Máa Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí! (w98-YR 10/1 ojú ìwé 28 sí 31)
No. 2: 1 Àwọn Ọba 15:9-24
No. 3: td-YR 42A Àwọn Kristẹni Kò Sí Lábẹ́ Àìgbọdọ̀máṣe Láti Pa Sábáàtì Mọ́
No. 4: td-YR 42B A Kò Fún Àwọn Kristẹni Ní Òfin Sábáàtì
Nov. 13 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 18 sí 20
Orin 159 [*2 Tẹsalóníkà 1 sí 2 Tímótì 3]
No. 1: Yanjú Àwọn Ìṣòro Ní Ìtùnbí-Ìnùbí (w98-YR 11/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: 1 Àwọn Ọba 20:1, 13-22
No. 3: td-YR 42D Ìgbà Tí Ìsinmi Sábáàtì ti Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ àti Ìgbà Tó Parí
No. 4: td-YR 18A Ọlọ́run Ń Fúnni Ní Ìgbàlà Kìkì Nípasẹ̀ Kristi
Nov. 20 Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 21 àti 22
Orin 179 [*2 Tímótì 4 sí Hébérù 7]
No. 1: w85-YR 5/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 5
No. 2: 1 Àwọn Ọba 22:29-40
No. 3: td-YR 18B “Ìgbàlà Lẹ́ẹ̀kan, Ìgbàlà Gbogbo Ìgbà” Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu
No. 4: td-YR 18D “Ìgbàlà Gbogbo Ayé” Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu
Nov. 27 Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 1 sí 3
Orin 148 [*Hébérù 8 sí Jákọ́bù 2]
No. 1: w85-YR 5/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 1
No. 2: 2 Àwọn Ọba 2:15-25
No. 3: td-YR 15A Ohun Tí Ẹ̀ṣẹ̀ Jẹ́
No. 4: td-YR 15B Ìdí Tí Gbogbo Ènìyàn Fi Ń Jìyà Nípa Ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù
Dec. 4 Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 4 sí 6
Orin 109 [*Jákọ́bù 3 sí 2 Pétérù 3]
No. 1: Ṣọ́ra fún Ríra Ipò (w98-YR 11/15 ojú ìwé 28)
No. 2: 2 Àwọn Ọba 5:20-27
No. 3: td-YR 15D Kí Ni Èso Tí A Kà Léèwọ̀ Jẹ́?
No. 4: td-YR 15E Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀ sí Ẹ̀mí Mímọ́ Jẹ́?
Dec. 11 Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 7 sí 9
Orin 117 [*1 Jòhánù 1 sí Ìṣípayá 1]
No. 1: Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Yẹ Láti Tẹ̀ Lé Nígbà Tí A Ba Ń Yáni Lówó Tàbí Nígbà Tí A Bá Ń Yáwó (w98-YR 11/15 ojú ìwé 24 sí 27)
No. 2: 2 Àwọn Ọba 7:1, 2, 6, 7, 16-20
No. 3: td-YR 40A Kí Ni Ọkàn Jẹ́?
No. 4: td-YR 40B Kí Ni Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Ọkàn àti Ẹ̀mí?
Dec. 18 Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 10 sí 12
Orin 181 [*Ìṣípayá 2 sí 12]
No. 1: Òkodoro Ìtàn Ìbí Jésù (w98-YR 12/15 ojú ìwé 5 sí 9)
No. 2: 2 Àwọn Ọba 11:1-3, 9-16
No. 3: td-YR 13A Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́ Jẹ́?
No. 4: td-YR 13B Ipá Ìwàláàyè Ènìyàn àti Ẹranko Ni A Ń Pè Ní Ẹ̀mí
Dec. 25 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Parí 2 Sámúẹ́lì 13 sí 2 Àwọn Ọba 12
Orin 217 [*Ìṣípayá 13 sí 22]