ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Àwọn Ọba

      • Ọlọ́run fi ìjì gbé Èlíjà lọ sókè (1-18)

        • Èlíṣà rí ẹ̀wù Èlíjà gbà (13, 14)

      • Èlíṣà wo omi Jẹ́ríkò sàn (19-22)

      • Àwọn bíárì pa àwọn ọmọdékùnrin tó jáde wá láti Bẹ́tẹ́lì (23-25)

2 Àwọn Ọba 2:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sánmà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 2:11
  • +1Ọb 17:1
  • +1Ọb 19:16
  • +2Ọb 4:38

2 Àwọn Ọba 2:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:18, 19; 1Ọb 12:28, 29; 2Ọb 2:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2015, ojú ìwé 12-13

    8/15/2013, ojú ìwé 29

2 Àwọn Ọba 2:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    “Àwọn ọmọ wòlíì” ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí ilé ẹ̀kọ́ tí àwọn wòlíì ti ń gba ìtọ́ni tàbí ẹgbẹ́ àwọn wòlíì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 9/2022,

2 Àwọn Ọba 2:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 6:26; 1Ọb 16:34

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2015, ojú ìwé 12-13

    8/15/2013, ojú ìwé 29

2 Àwọn Ọba 2:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn rẹ.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2015, ojú ìwé 12-13

2 Àwọn Ọba 2:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:19
  • +Ẹk 14:21, 22; Joṣ 3:17; 2Ọb 2:13, 14

2 Àwọn Ọba 2:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “apá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 21:17
  • +Di 34:9; 1Ọb 19:16; Lk 1:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2013, ojú ìwé 29

    8/1/2005, ojú ìwé 8-9

    11/1/2003, ojú ìwé 31

    11/1/1997, ojú ìwé 30

2 Àwọn Ọba 2:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2013, ojú ìwé 29

2 Àwọn Ọba 2:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sánmà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 6:17; Sm 68:17
  • +2Kr 21:5, 12; Jo 3:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2015, ojú ìwé 13

    8/15/2013, ojú ìwé 29

    8/1/2005, ojú ìwé 9

    9/1/2003, ojú ìwé 30

    9/15/1997, ojú ìwé 15

2 Àwọn Ọba 2:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 13:14
  • +2Sa 1:11, 12; Job 1:19, 20

2 Àwọn Ọba 2:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:19; 2Ọb 1:8; Sek 13:4; Mt 3:4

2 Àwọn Ọba 2:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 3:13; 2Ọb 2:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2015, ojú ìwé 13

2 Àwọn Ọba 2:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 11:24, 25; 27:18, 20; 2Ọb 2:9

2 Àwọn Ọba 2:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìjì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 18:11, 12

2 Àwọn Ọba 2:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 6:26; 1Ọb 16:34

2 Àwọn Ọba 2:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ń ba oyún jẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 34:1-3

2 Àwọn Ọba 2:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “kò sì ní ba oyún jẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:23-25; 2Ọb 4:38-41

2 Àwọn Ọba 2:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:15, 16; Lk 10:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2005, ojú ìwé 9

2 Àwọn Ọba 2:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 17:12
  • +2Ọb 1:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    11/1/1992, ojú ìwé 9

2 Àwọn Ọba 2:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 4:25

Àwọn míì

2 Ọba 2:12Ọb 2:11
2 Ọba 2:11Ọb 17:1
2 Ọba 2:11Ọb 19:16
2 Ọba 2:12Ọb 4:38
2 Ọba 2:2Jẹ 28:18, 19; 1Ọb 12:28, 29; 2Ọb 2:23
2 Ọba 2:31Ọb 19:16
2 Ọba 2:4Joṣ 6:26; 1Ọb 16:34
2 Ọba 2:81Ọb 19:19
2 Ọba 2:8Ẹk 14:21, 22; Joṣ 3:17; 2Ọb 2:13, 14
2 Ọba 2:9Di 21:17
2 Ọba 2:9Di 34:9; 1Ọb 19:16; Lk 1:17
2 Ọba 2:112Ọb 6:17; Sm 68:17
2 Ọba 2:112Kr 21:5, 12; Jo 3:13
2 Ọba 2:122Ọb 13:14
2 Ọba 2:122Sa 1:11, 12; Job 1:19, 20
2 Ọba 2:131Ọb 19:19; 2Ọb 1:8; Sek 13:4; Mt 3:4
2 Ọba 2:14Joṣ 3:13; 2Ọb 2:8
2 Ọba 2:15Nọ 11:24, 25; 27:18, 20; 2Ọb 2:9
2 Ọba 2:161Ọb 18:11, 12
2 Ọba 2:18Joṣ 6:26; 1Ọb 16:34
2 Ọba 2:19Di 34:1-3
2 Ọba 2:21Ẹk 15:23-25; 2Ọb 4:38-41
2 Ọba 2:232Kr 36:15, 16; Lk 10:16
2 Ọba 2:24Owe 17:12
2 Ọba 2:242Ọb 1:10
2 Ọba 2:252Ọb 4:25
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Àwọn Ọba 2:1-25

Àwọn Ọba Kejì

2 Nígbà tó kù díẹ̀ tí Jèhófà máa fi ìjì+ gbé Èlíjà+ lọ sí ọ̀run,* Èlíjà àti Èlíṣà+ jáde kúrò ní Gílígálì.+ 2 Èlíjà sọ fún Èlíṣà pé: “Jọ̀ọ́, dúró sí ibí yìí, nítorí pé Jèhófà ti rán mi lọ sí Bẹ́tẹ́lì.” Àmọ́ Èlíṣà sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ náà* sì wà láàyè, mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n lọ sí Bẹ́tẹ́lì.+ 3 Ìgbà náà ni àwọn ọmọ wòlíì* ní Bẹ́tẹ́lì jáde wá bá Èlíṣà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ṣé o mọ̀ pé òní ni Jèhófà máa mú ọ̀gá rẹ lọ, tí kò sì ní ṣe olórí rẹ mọ́?”+ Ó dá wọn lóhùn pé: “Mo mọ̀. Ẹ dákẹ́.”

4 Èlíjà wá sọ fún un pé: “Èlíṣà, jọ̀ọ́ dúró sí ibí yìí, nítorí pé, Jèhófà ti rán mi lọ sí Jẹ́ríkò.”+ Àmọ́ ó sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ náà* sì wà láàyè, mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n lọ sí Jẹ́ríkò. 5 Àwọn ọmọ wòlíì tó wà ní Jẹ́ríkò wá bá Èlíṣà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ṣé o mọ̀ pé òní ni Jèhófà máa mú ọ̀gá rẹ lọ, tí kò sì ní ṣe olórí rẹ mọ́?” Ó dá wọn lóhùn pé: “Mo mọ̀. Ẹ dákẹ́.”

6 Èlíjà wá sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, dúró sí ibí yìí, nítorí pé Jèhófà ti rán mi lọ sí Jọ́dánì.” Àmọ́ ó sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ náà* sì wà láàyè, mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà, àwọn méjèèjì jọ ń lọ. 7 Bákan náà, àádọ́ta (50) lára àwọn ọmọ wòlíì jáde lọ, wọ́n dúró lọ́ọ̀ọ́kán, wọ́n sì ń wo àwọn méjèèjì bí wọ́n ṣe dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì. 8 Nígbà náà, Èlíjà mú ẹ̀wù oyè rẹ̀,+ ó ká a, ó sì lu omi náà, ó pín sápá ọ̀tún àti sápá òsì, tó fi jẹ́ pé àwọn méjèèjì gba orí ilẹ̀ gbígbẹ sọdá.+

9 Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n sọdá, Èlíjà sọ fún Èlíṣà pé: “Béèrè ohun tí o bá fẹ́ kí n ṣe fún ọ kí Ọlọ́run tó mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” Torí náà, Èlíṣà sọ pé: “Jọ̀ọ́, fún mi ní ìpín*+ méjì nínú ẹ̀mí rẹ.”+ 10 Ó fèsì pé: “Ohun tí o béèrè yìí kò rọrùn. Tí o bá rí mi nígbà tí Ọlọ́run bá mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ, á rí bẹ́ẹ̀ fún ọ; àmọ́ tí o ò bá rí mi, kò ní rí bẹ́ẹ̀.”

11 Bí wọ́n ṣe ń rìn lọ, wọ́n ń sọ̀rọ̀, lójijì kẹ̀kẹ́ ẹṣin oníná àti àwọn ẹṣin oníná+ ya àwọn méjèèjì sọ́tọ̀, ìjì sì gbé Èlíjà lọ sí ọ̀run.*+ 12 Bí Èlíṣà ṣe ń wò ó, ó ké jáde pé: “Bàbá mi, bàbá mi! Kẹ̀kẹ́ ẹṣin Ísírẹ́lì àti àwọn agẹṣin rẹ̀!”+ Nígbà tí kò rí i mọ́, ó di ẹ̀wù ara rẹ̀ mú, ó sì fà á ya sí méjì.+ 13 Lẹ́yìn náà, ó mú ẹ̀wù oyè+ Èlíjà tó já bọ́ lára rẹ̀, ó pa dà, ó sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ etí odò Jọ́dánì. 14 Ló bá mú ẹ̀wù oyè Èlíjà tó já bọ́ lára rẹ̀, ó fi lu omi náà, ó sì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Èlíjà dà?” Nígbà tó lu omi náà, ó pín sí apá ọ̀tún àti sí apá òsì, tí Èlíṣà fi lè sọdá.+

15 Nígbà tí àwọn ọmọ wòlíì tó wà ní Jẹ́ríkò rí i lókèèrè, wọ́n sọ pé: “Ẹ̀mí Èlíjà ti bà lé Èlíṣà.”+ Torí náà, wọ́n wá pàdé rẹ̀, wọ́n sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ níwájú rẹ̀. 16 Wọ́n sọ fún un pé: “Àádọ́ta (50) géńdé ọkùnrin wà níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Jọ̀ọ́, jẹ́ kí wọ́n lọ wá ọ̀gá rẹ. Ó lè jẹ́ pé, nígbà tí ẹ̀mí* Jèhófà gbé e, orí ọ̀kan nínú àwọn òkè tàbí àwọn àfonífojì ni ó jù ú sí.”+ Àmọ́ ó sọ pé: “Ẹ má ṣe rán wọn.” 17 Síbẹ̀, wọ́n ń rọ̀ ọ́ ṣáá títí ó fi sú u, torí náà ó ní: “Ẹ rán wọn lọ.” Wọ́n wá rán àádọ́ta (50) ọkùnrin, ọjọ́ mẹ́ta ni wọ́n sì fi wá a, ṣùgbọ́n wọn ò rí i. 18 Nígbà tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ṣì wà ní Jẹ́ríkò.+ Ó wá sọ fún wọn pé: “Ṣé mi ò sọ fún yín pé kí ẹ má lọ?”

19 Nígbà tó yá, àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún Èlíṣà pé: “Ọ̀gá wa, bí ìwọ náà ṣe mọ̀, ibi tí ìlú yìí wà dáa;+ àmọ́ omi rẹ̀ kò dáa, ilẹ̀ rẹ̀ sì ti ṣá.”* 20 Ló bá sọ pé: “Ẹ mú abọ́ kékeré tuntun kan wá, kí ẹ sì bu iyọ̀ sínú rẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n gbé e wá fún un. 21 Ó wá lọ sí orísun omi náà, ó da iyọ̀ sínú rẹ̀,+ ó sì sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Mo ti wo omi yìí sàn. Kò ní fa ikú, kò sì ní sọni di àgàn* mọ́.’” 22 Ìwòsàn sì bá omi náà títí di òní yìí, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Èlíṣà sọ.

23 Ó gòkè láti ibẹ̀ lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Bó ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọmọkùnrin kan jáde wá láti inú ìlú náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n ń sọ fún un pé: “Gòkè lọ, apárí! Gòkè lọ, apárí!” 24 Níkẹyìn, ó bojú wẹ̀yìn, ó wò wọ́n, ó sì gégùn-ún fún wọn ní orúkọ Jèhófà. Ni abo bíárì+ méjì bá jáde láti inú igbó, wọ́n sì fa méjìlélógójì (42) lára àwọn ọmọ náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.+ 25 Ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Òkè Kámẹ́lì,+ láti ibẹ̀, ó pa dà sí Samáríà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́