ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Sámúẹ́lì 9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Sámúẹ́lì

      • Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Dáfídì ní sí Méfíbóṣétì (1-13)

2 Sámúẹ́lì 9:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:1, 3; 20:15, 42

2 Sámúẹ́lì 9:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 16:1; 19:17

2 Sámúẹ́lì 9:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ó yarọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 4:4; 9:13; 19:26

2 Sámúẹ́lì 9:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 17:27-29

2 Sámúẹ́lì 9:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “jẹ búrẹ́dì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 11:17
  • +2Sa 19:28; Owe 11:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2002, ojú ìwé 19

2 Sámúẹ́lì 9:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àfiyèsí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 24:14

2 Sámúẹ́lì 9:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìránṣẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 9:1; 16:4; 19:29

2 Sámúẹ́lì 9:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 19:28
  • +2Sa 19:17

2 Sámúẹ́lì 9:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “mi.”

2 Sámúẹ́lì 9:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 8:34; 9:40

2 Sámúẹ́lì 9:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 9:7; 19:28
  • +2Sa 4:4

Àwọn míì

2 Sám. 9:11Sa 18:1, 3; 20:15, 42
2 Sám. 9:22Sa 16:1; 19:17
2 Sám. 9:32Sa 4:4; 9:13; 19:26
2 Sám. 9:42Sa 17:27-29
2 Sám. 9:7Owe 11:17
2 Sám. 9:72Sa 19:28; Owe 11:25
2 Sám. 9:81Sa 24:14
2 Sám. 9:92Sa 9:1; 16:4; 19:29
2 Sám. 9:102Sa 19:28
2 Sám. 9:102Sa 19:17
2 Sám. 9:121Kr 8:34; 9:40
2 Sám. 9:132Sa 9:7; 19:28
2 Sám. 9:132Sa 4:4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Sámúẹ́lì 9:1-13

Sámúẹ́lì Kejì

9 Nígbà náà, Dáfídì sọ pé: “Ṣé ẹnì kankan ṣì kù ní ilé Sọ́ọ̀lù tí mo lè fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí nítorí Jónátánì?”+ 2 Ìránṣẹ́ ilé Sọ́ọ̀lù kan wà tó ń jẹ́ Síbà.+ Torí náà, wọ́n pè é wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé ìwọ ni Síbà?” Ó dáhùn pé: “Èmi ìránṣẹ́ rẹ ni.” 3 Ọba ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ṣé ẹnì kankan ṣì kù ní ilé Sọ́ọ̀lù tí mo lè nawọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ sí?” Síbà dá ọba lóhùn pé: “Ọmọkùnrin Jónátánì kan ṣì wà; ó rọ ní ẹsẹ̀ méjèèjì.”*+ 4 Ọba wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ibo ló wà?” Síbà dá ọba lóhùn pé: “Ó wà ní ilé Mákírù+ ọmọkùnrin Ámíélì ní Lo-débà.”

5 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Ọba Dáfídì ní kí wọ́n lọ mú un wá láti ilé Mákírù ọmọ Ámíélì ní Lo-débà. 6 Nígbà tí Méfíbóṣétì ọmọ Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù wọlé sọ́dọ̀ Dáfídì, ní kíá, ó tẹrí ba, ó sì wólẹ̀. Dáfídì bá sọ pé: “Méfíbóṣétì!” Ó sì dáhùn pé: “Ìránṣẹ́ rẹ nìyí.” 7 Dáfídì sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, màá rí i dájú pé mo fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀+ hàn sí ọ nítorí Jónátánì bàbá rẹ, màá dá gbogbo ilẹ̀ Sọ́ọ̀lù bàbá rẹ àgbà pa dà fún ọ, orí tábìlì mi + ni wàá sì ti máa jẹun* nígbà gbogbo.”

8 Ni ó bá wólẹ̀, ó sì sọ pé: “Kí ni èmi ìránṣẹ́ rẹ já mọ́, tí o fi yí ojú* rẹ sí òkú ajá+ bíi tèmi?” 9 Ọba wá ránṣẹ́ pe Síbà, ẹmẹ̀wà* Sọ́ọ̀lù, ó sì sọ fún un pé: “Gbogbo ohun tí Sọ́ọ̀lù àti gbogbo ilé rẹ̀ ní ni mo fún ọmọ ọmọ ọ̀gá rẹ.+ 10 Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni á máa bá a dá oko, wàá máa kó irè oko jọ láti pèsè oúnjẹ tí àwọn ará ilé ọmọ ọmọ ọ̀gá rẹ á máa jẹ. Àmọ́ orí tábìlì mi+ ni Méfíbóṣétì, ọmọ ọmọ ọ̀gá rẹ, á ti máa jẹun nígbà gbogbo.”

Síbà ní ọmọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) àti ogún (20) ìránṣẹ́.+ 11 Nígbà náà, Síbà sọ fún ọba pé: “Gbogbo ohun tí olúwa mi ọba pa láṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ ni ìránṣẹ́ rẹ máa ṣe.” Torí náà, Méfíbóṣétì máa ń jẹun lórí tábìlì Dáfídì* bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọba. 12 Méfíbóṣétì tún ní ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Máíkà;+ gbogbo àwọn tó ń gbé ní ilé Síbà sì di ìránṣẹ́ Méfíbóṣétì. 13 Méfíbóṣétì ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, nítorí ó ń jẹun nígbà gbogbo lórí tábìlì ọba;+ ó sì rọ ní ẹsẹ̀ méjèèjì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́