ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kọ́ríńtì 7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kọ́ríńtì

      • Ká wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀gbin (1)

      • Inú Pọ́ọ̀lù dùn sí àwọn ará Kọ́ríńtì (2-4)

      • Títù mú ìròyìn rere wá (5-7)

      • Ìbànújẹ́ ní ọ̀nà Ọlọ́run àti ìrònúpìwàdà (8-16)

2 Kọ́ríńtì 7:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 6:16
  • +Ro 12:1; 1Ti 1:5; 3:9; 1Jo 3:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 40

    Jí!,

    No. 3 2019 ojú ìwé 4-5

    ‘Ìfẹ́ Ọlọ́run’, ojú ìwé 93-95

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 26

    8/1/1997, ojú ìwé 5-7

    Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 45-48

    Ayọ, ojú ìwé 98

2 Kọ́ríńtì 7:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 12:10; 2Kọ 6:12, 13
  • +Iṣe 20:33, 34; 2Kọ 12:17

2 Kọ́ríńtì 7:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Flp 2:17; Flm 7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2006, ojú ìwé 15

2 Kọ́ríńtì 7:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “ẹran ara.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 20:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2014, ojú ìwé 23

    11/15/1998, ojú ìwé 30

    11/1/1996, ojú ìwé 11-12

    7/15/1992, ojú ìwé 19

2 Kọ́ríńtì 7:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 1:3, 4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná, ojú ìwé 166

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/1998, ojú ìwé 30

    11/1/1996, ojú ìwé 11-12

2 Kọ́ríńtì 7:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “ìtara yín fún mi.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná, ojú ìwé 166

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/1998, ojú ìwé 30

2 Kọ́ríńtì 7:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 2:4

2 Kọ́ríńtì 7:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 32:5; 1Jo 1:9

2 Kọ́ríńtì 7:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pé ìwà yín mọ́; pé ọwọ́ yín mọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 3:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/1997, ojú ìwé 14

2 Kọ́ríńtì 7:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 5:5

2 Kọ́ríńtì 7:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 2:9; Heb 13:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/1998, ojú ìwé 30

2 Kọ́ríńtì 7:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ní ìgboyà nítorí yín.”

Àwọn míì

2 Kọ́r. 7:12Kọ 6:16
2 Kọ́r. 7:1Ro 12:1; 1Ti 1:5; 3:9; 1Jo 3:3
2 Kọ́r. 7:2Ro 12:10; 2Kọ 6:12, 13
2 Kọ́r. 7:2Iṣe 20:33, 34; 2Kọ 12:17
2 Kọ́r. 7:4Flp 2:17; Flm 7
2 Kọ́r. 7:5Iṣe 20:1
2 Kọ́r. 7:62Kọ 1:3, 4
2 Kọ́r. 7:82Kọ 2:4
2 Kọ́r. 7:10Sm 32:5; 1Jo 1:9
2 Kọ́r. 7:11Mt 3:8
2 Kọ́r. 7:121Kọ 5:5
2 Kọ́r. 7:152Kọ 2:9; Heb 13:17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kọ́ríńtì 7:1-16

Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì

7 Nítorí náà, ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, nígbà tí a ti gba àwọn ìlérí yìí,+ ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí,+ kí a jẹ́ mímọ́ pátápátá nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

2 Ẹ fàyè gbà wá nínú ọkàn yín.+ A kò ṣe àìtọ́ sí ẹnì kankan, a kò sọ ẹnì kankan dìbàjẹ́, a kò sì yan ẹnì kankan jẹ.+ 3 Mi ò sọ èyí láti dá yín lẹ́bi. Nítorí mo ti sọ ṣáájú pé ẹ wà lọ́kàn wa, bóyá a kú àbí a wà láàyè. 4 Mo lè bá yín sọ̀rọ̀ fàlàlà. Mò ń fi yín yangàn púpọ̀. Ara tù mí gan-an, kódà ayọ̀ mi kún nínú gbogbo ìpọ́njú wa.+

5 Ní tòótọ́, nígbà tí a dé Makedóníà,+ ara* ò tù wá rárá, ṣe ni wọ́n ń fìyà jẹ wá ní gbogbo ọ̀nà—ìjà wà lóde, ìbẹ̀rù wà nínú. 6 Àmọ́ Ọlọ́run tó ń tu àwọn tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá nínú,+ ti tù wá nínú bí Títù ṣe wà pẹ̀lú wa; 7 síbẹ̀, kì í ṣe bó ṣe wà pẹ̀lú wa nìkan, àmọ́ bó ṣe rí ìtùnú gbà nítorí yín, tó sọ fún wa pé ó ń wù yín láti rí mi, bí ẹ ṣe ń kẹ́dùn púpọ̀ àti bí ọ̀rọ̀ mi ṣe jẹ yín lọ́kàn;* torí náà, ṣe ni ayọ̀ mi pọ̀ sí i.

8 Nítorí ká ní mo tiẹ̀ fi lẹ́tà mi bà yín nínú jẹ́,+ mi ò kábàámọ̀ rẹ̀. Ká tiẹ̀ ní mo kọ́kọ́ kábàámọ̀ rẹ̀, (bí mo ṣe rí i pé lẹ́tà yẹn bà yín nínú jẹ́, bó tiẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀,) 9 ní báyìí, inú mi ń dùn, kì í kàn ṣe torí pé a bà yín nínú jẹ́, àmọ́ torí pé ìbànújẹ́ yìí mú kí ẹ ronú pìwà dà. A bà yín nínú jẹ́ ní ọ̀nà Ọlọ́run, kí ẹ má bàa fara pa nítorí wa. 10 Nítorí ìbànújẹ́ ní ọ̀nà Ọlọ́run ń múni ronú pìwà dà, ó sì ń yọrí sí ìgbàlà láìfi àbámọ̀ kún un;+ àmọ́ ìbànújẹ́ ti ayé ń mú ikú wá. 11 Ẹ wo bí ìbànújẹ́ tó bá yín ní ọ̀nà Ọlọ́run ṣe mú kí ẹ túbọ̀ máa fìtara ṣe nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni, ó mú kí ẹ wẹ ara yín mọ́, ó múnú bí yín sí àìtọ́ tó wáyé, ó mú kí ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ó mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run wà lọ́kàn yín, ó mú kí ẹ nítara, ó sì mú kí ẹ ṣe àtúnṣe sí àìtọ́ náà!+ Ní gbogbo ọ̀nà, ẹ ti fi hàn pé ẹ jẹ́ mímọ́* nínú ọ̀ràn yìí. 12 Òótọ́ ni pé mo kọ̀wé sí yín, àmọ́ kì í ṣe torí ẹni tó ṣe àìtọ́ ni mo ṣe kọ ọ́+ tàbí torí ẹni tí wọ́n ṣe àìtọ́ sí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nítorí kó lè hàn kedere láàárín yín pé ẹ̀ ń fìtara ṣe nǹkan tí a sọ fún yín níwájú Ọlọ́run. 13 Ìdí nìyẹn tí a fi rí ìtùnú gbà.

Àmọ́ yàtọ̀ sí ìtùnú tí a rí gbà, ìdùnnú wa tún pọ̀ sí i lórí ayọ̀ tí Títù ní, nítorí gbogbo yín mára tu ẹ̀mí rẹ̀. 14 Mo ti fi yín yangàn lójú rẹ̀, ojú ò sì tì mí; bí gbogbo ohun tí a sọ fún yín ṣe jẹ́ òótọ́, bẹ́ẹ̀ ni bí a ṣe fi yín yangàn níwájú Títù ṣe jẹ́ òótọ́. 15 Bákan náà, ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó ní sí yín ń pọ̀ sí i bó ṣe ń rántí ìgbọràn gbogbo yín,+ bí ẹ ṣe gbà á pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì. 16 Inú mi dùn pé ní gbogbo ọ̀nà, mo lè fọkàn tán yín.*

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́