ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 24
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Sámúẹ́lì

      • Dáfídì dá ẹ̀mí Sọ́ọ̀lù sí (1-22)

        • Dáfídì bọ̀wọ̀ fún ẹni àmì òróró Jèhófà (6)

1 Sámúẹ́lì 24:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 23:28, 29

1 Sámúẹ́lì 24:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “bo ẹsẹ̀ rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 57:àkọlé; 142:àkọlé

1 Sámúẹ́lì 24:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 26:8, 23

1 Sámúẹ́lì 24:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹ̀rí ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 24:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2007, ojú ìwé 22

1 Sámúẹ́lì 24:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:28; 1Sa 26:11; 2Sa 1:14; 1Kr 16:22

1 Sámúẹ́lì 24:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “tú àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ká.”

1 Sámúẹ́lì 24:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 26:17

1 Sámúẹ́lì 24:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 26:19

1 Sámúẹ́lì 24:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 24:4
  • +1Sa 9:16; 10:1; 26:9; Sm 105:15

1 Sámúẹ́lì 24:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 26:18; Sm 35:7
  • +1Sa 23:14

1 Sámúẹ́lì 24:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 26:23
  • +Di 32:35
  • +1Sa 26:11

1 Sámúẹ́lì 24:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 26:20

1 Sámúẹ́lì 24:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 25:39; Sm 35:1

1 Sámúẹ́lì 24:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 26:17

1 Sámúẹ́lì 24:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 26:21

1 Sámúẹ́lì 24:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 24:4, 10

1 Sámúẹ́lì 24:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 26:25; Sm 18:20

1 Sámúẹ́lì 24:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 13:14; 15:28; 18:8; 20:31; 23:17

1 Sámúẹ́lì 24:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:12; Di 6:13
  • +2Sa 9:1; 21:7

1 Sámúẹ́lì 24:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 15:34
  • +1Sa 23:29

Àwọn míì

1 Sám. 24:11Sa 23:28, 29
1 Sám. 24:3Sm 57:àkọlé; 142:àkọlé
1 Sám. 24:41Sa 26:8, 23
1 Sám. 24:52Sa 24:10
1 Sám. 24:6Ẹk 22:28; 1Sa 26:11; 2Sa 1:14; 1Kr 16:22
1 Sám. 24:81Sa 26:17
1 Sám. 24:91Sa 26:19
1 Sám. 24:101Sa 24:4
1 Sám. 24:101Sa 9:16; 10:1; 26:9; Sm 105:15
1 Sám. 24:111Sa 26:18; Sm 35:7
1 Sám. 24:111Sa 23:14
1 Sám. 24:121Sa 26:23
1 Sám. 24:12Di 32:35
1 Sám. 24:121Sa 26:11
1 Sám. 24:141Sa 26:20
1 Sám. 24:151Sa 25:39; Sm 35:1
1 Sám. 24:161Sa 26:17
1 Sám. 24:171Sa 26:21
1 Sám. 24:181Sa 24:4, 10
1 Sám. 24:191Sa 26:25; Sm 18:20
1 Sám. 24:201Sa 13:14; 15:28; 18:8; 20:31; 23:17
1 Sám. 24:21Le 19:12; Di 6:13
1 Sám. 24:212Sa 9:1; 21:7
1 Sám. 24:221Sa 15:34
1 Sám. 24:221Sa 23:29
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Sámúẹ́lì 24:1-22

Sámúẹ́lì Kìíní

24 Gbàrà tí Sọ́ọ̀lù pa dà lẹ́yìn àwọn Filísínì tó lé lọ, wọ́n sọ fún un pé: “Wò ó! Dáfídì wà ní aginjù Ẹ́ń-gédì.”+

2 Torí náà, Sọ́ọ̀lù kó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin tí ó yàn látinú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì wá Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ lọ sórí àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àpáta tí àwọn ewúrẹ́ orí òkè máa ń wà. 3 Sọ́ọ̀lù dé ibi àwọn ọgbà àgùntàn tí wọ́n fi òkúta ṣe lójú ọ̀nà, níbi tí ihò kan wà, ó sì wọlé lọ láti tura,* àmọ́ Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ jókòó sí inú ihò náà ní apá ẹ̀yìn.+ 4 Àwọn ọkùnrin Dáfídì sọ fún un pé: “Ọjọ́ yìí ni Jèhófà sọ fún ọ nípa rẹ̀ pé, ‘Wò ó! Màá fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́,+ o lè ṣe ohunkóhun tó bá dára ní ojú rẹ sí i.’” Torí náà, Dáfídì dìde, ó sì rọra gé etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí Sọ́ọ̀lù wọ̀. 5 Àmọ́ lẹ́yìn náà, ọkàn* Dáfídì ń dá a lẹ́bi ṣáá,+ torí pé ó gé etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí Sọ́ọ̀lù wọ̀. 6 Ó sọ fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ pé: “Jèhófà ò ní fẹ́ gbọ́ rárá pé mo ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí olúwa mi, ẹni àmì òróró Jèhófà, pé mo gbé ọwọ́ mi sókè sí i, torí ẹni àmì òróró Jèhófà ni.”+ 7 Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ yìí ló fi dá àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dúró,* kò sì gbà wọ́n láyè láti kọ lu Sọ́ọ̀lù. Àmọ́, Sọ́ọ̀lù dìde, ó kúrò nínú ihò náà, ó sì bá tiẹ̀ lọ.

8 Lẹ́yìn náà, Dáfídì dìde, ó jáde kúrò nínú ihò náà, ó sì nahùn pe Sọ́ọ̀lù, o ní: “Olúwa mi ọba!”+ Nígbà tí Sọ́ọ̀lù bojú wẹ̀yìn, Dáfídì tẹrí ba, ó sì dọ̀bálẹ̀. 9 Dáfídì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Kí nìdí tí o fi fetí sí àwọn tó ń sọ pé, ‘Wò ó! Dáfídì fẹ́ ṣe ọ́ ní jàǹbá’?+ 10 O ti fojú ara rẹ rí i lónìí bí Jèhófà ṣe fi ọ́ lé mi lọ́wọ́ nínú ihò. Àmọ́ nígbà tí ẹnì kan ní kí n pa ọ́,+ àánú rẹ ṣe mí, mo sì sọ pé, ‘Mi ò ní gbé ọwọ́ mi sókè sí olúwa mi, torí pé ẹni àmì òróró Jèhófà ni.’+ 11 Bàbá mi, wò ó, etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ tí kò lápá rèé lọ́wọ́ mi; nígbà tí mo gé etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ tí kò lápá, mi ò pa ọ́. Ṣé ìwọ náà rí i, ṣé o sì ti wá mọ̀ báyìí pé mi ò gbèrò láti ṣe ọ́ ní jàǹbá tàbí kí n dìtẹ̀ sí ọ? Mi ò ṣẹ̀ ọ́,+ àmọ́ ńṣe ni ò ń dọdẹ mi kiri láti gba ẹ̀mí* mi.+ 12 Kí Jèhófà ṣe ìdájọ́ láàárín èmi àti ìwọ,+ kí Jèhófà sì bá mi gbẹ̀san lára rẹ,+ àmọ́ mi ò ní jẹ́ gbé ọwọ́ mi sókè sí ọ.+ 13 Bí òwe àtijọ́ kan tó sọ pé, ‘Ẹni burúkú ló ń hùwà burúkú,’ àmọ́ ní tèmi, mi ò ní gbé ọwọ́ mi sókè sí ọ. 14 Ta tiẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì ń lé kiri? Ta ni ò ń lépa? Ṣé òkú ajá bíi tèmi yìí ni? Àbí ẹyọ eégbọn kan ṣoṣo?+ 15 Kí Jèhófà jẹ́ onídàájọ́, kí ó sì dájọ́ láàárín èmi àti ìwọ. Yóò rí i, yóò gba ẹjọ́ mi rò,+ yóò dá ẹjọ́ mi, yóò sì gbà mí lọ́wọ́ rẹ.”

16 Bí Dáfídì ṣe parí ọ̀rọ̀ tó sọ fún Sọ́ọ̀lù yìí, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Ṣé ohùn rẹ nìyí, Dáfídì ọmọ mi?”+ Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún kíkankíkan. 17 Ó sọ fún Dáfídì pé: “Òdodo rẹ ju tèmi lọ, torí o ti ṣe dáadáa sí mi, àmọ́ mo ti fi ibi san án fún ọ.+ 18 Bẹ́ẹ̀ ni, o ti sọ ohun rere tí o ṣe lónìí fún mi bí o kò ṣe pa mí nígbà tí Jèhófà fi mí lé ọ lọ́wọ́.+ 19 Ta ló máa rí ọ̀tá rẹ̀ tí á sì jẹ́ kó faraare lọ? Jèhófà yóò fi ire san án fún ọ,+ nítorí ohun tí o ṣé fún mi lónìí. 20 Wò ó! Mo mọ̀ pé kò sí bí o kò ṣe ní di ọba tó máa ṣàkóso+ àti pé ìjọba Ísírẹ́lì máa pẹ́ lọ́wọ́ rẹ. 21 Ní báyìí, fi Jèhófà búra+ fún mi pé o ò ní pa àtọmọdọ́mọ* mi run àti pé o ò ní pa orúkọ mi rẹ́ kúrò nílé bàbá mi.”+ 22 Torí náà, Dáfídì búra fún Sọ́ọ̀lù, lẹ́yìn náà Sọ́ọ̀lù lọ sí ilé rẹ̀.+ Àmọ́ Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ lọ sí ibi ààbò.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́