16 “Ní ìwòyí ọ̀la, màá rán ọkùnrin kan láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì sí ọ.+ Kí o fòróró yàn án ṣe aṣáájú lórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì,+ yóò sì gba àwọn èèyàn mi lọ́wọ́ àwọn Filísínì. Nítorí mo ti rí ìpọ́njú àwọn èèyàn mi, igbe ẹkún wọn sì ti dé ọ̀dọ̀ mi.”+
10Ìgbà náà ni Sámúẹ́lì mú ṣágo* òróró, ó sì da òróró inú rẹ̀ sórí Sọ́ọ̀lù.+ Ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì sọ pé: “Ǹjẹ́ Jèhófà kò ti fòróró yàn ọ́ ṣe aṣáájú+ lórí ogún rẹ̀?+