ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóṣúà 14
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jóṣúà

      • Wọ́n pín ilẹ̀ tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì (1-5)

      • Kélẹ́bù jogún Hébúrónì (6-15)

Jóṣúà 14:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 34:17; Joṣ 19:51

Jóṣúà 14:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 26:55; 33:54; Owe 16:33; Iṣe 13:19
  • +Nọ 34:13

Jóṣúà 14:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, apá ìlà oòrùn.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 32:29
  • +Di 10:9; Joṣ 13:14

Jóṣúà 14:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 48:5; 1Kr 5:2
  • +Jẹ 48:19, 20
  • +Nọ 35:7; Joṣ 21:1, 2
  • +Nọ 35:2, 5

Jóṣúà 14:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 4:19; 10:43
  • +Nọ 32:11, 12
  • +Di 1:35, 36
  • +Nọ 12:7, 8
  • +Nọ 13:26

Jóṣúà 14:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gẹ́lẹ́ lọ́kàn mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 13:2, 6
  • +Nọ 13:30; 14:6, 7

Jóṣúà 14:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kó ìpayà bá àwọn èèyàn wa.”

  • *

    Ní Héb., “tọ Jèhófà Ọlọ́run mi lẹ́yìn délẹ̀délẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 14:24; 32:11, 12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    5/15/1993, ojú ìwé 26-29

Jóṣúà 14:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 1:36

Jóṣúà 14:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 21:45
  • +Nọ 14:29, 30
  • +Nọ 14:33

Jóṣúà 14:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “bóyá.”

  • *

    Tàbí “mú wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 13:33
  • +Nọ 13:22, 28
  • +Nọ 14:8; Ro 8:31
  • +Joṣ 15:14; Ond 1:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2004, ojú ìwé 12

    5/15/1993, ojú ìwé 28-29

Jóṣúà 14:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 10:36, 37; 15:13; 21:11, 12; 1Kr 6:55, 56

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    5/15/1993, ojú ìwé 28-29

Jóṣúà 14:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 14:24; Di 1:35, 36; Joṣ 14:8

Jóṣúà 14:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 23:2
  • +Le 26:6; Joṣ 11:23

Àwọn míì

Jóṣ. 14:1Nọ 34:17; Joṣ 19:51
Jóṣ. 14:2Nọ 26:55; 33:54; Owe 16:33; Iṣe 13:19
Jóṣ. 14:2Nọ 34:13
Jóṣ. 14:3Nọ 32:29
Jóṣ. 14:3Di 10:9; Joṣ 13:14
Jóṣ. 14:4Jẹ 48:5; 1Kr 5:2
Jóṣ. 14:4Jẹ 48:19, 20
Jóṣ. 14:4Nọ 35:7; Joṣ 21:1, 2
Jóṣ. 14:4Nọ 35:2, 5
Jóṣ. 14:6Joṣ 4:19; 10:43
Jóṣ. 14:6Nọ 32:11, 12
Jóṣ. 14:6Di 1:35, 36
Jóṣ. 14:6Nọ 12:7, 8
Jóṣ. 14:6Nọ 13:26
Jóṣ. 14:7Nọ 13:2, 6
Jóṣ. 14:7Nọ 13:30; 14:6, 7
Jóṣ. 14:8Nọ 14:24; 32:11, 12
Jóṣ. 14:9Di 1:36
Jóṣ. 14:10Joṣ 21:45
Jóṣ. 14:10Nọ 14:29, 30
Jóṣ. 14:10Nọ 14:33
Jóṣ. 14:12Nọ 13:33
Jóṣ. 14:12Nọ 13:22, 28
Jóṣ. 14:12Nọ 14:8; Ro 8:31
Jóṣ. 14:12Joṣ 15:14; Ond 1:20
Jóṣ. 14:13Joṣ 10:36, 37; 15:13; 21:11, 12; 1Kr 6:55, 56
Jóṣ. 14:14Nọ 14:24; Di 1:35, 36; Joṣ 14:8
Jóṣ. 14:15Jẹ 23:2
Jóṣ. 14:15Le 26:6; Joṣ 11:23
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jóṣúà 14:1-15

Jóṣúà

14 Èyí ni ogún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà ní ilẹ̀ Kénáánì, èyí tí àlùfáà Élíásárì àti Jóṣúà ọmọ Núnì àtàwọn olórí agbo ilé àwọn ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún wọn pé kí wọ́n jogún.+ 2 Kèké ni wọ́n fi pín ogún+ fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án àtààbọ̀ náà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+ 3 Mósè ti pín ogún fún ẹ̀yà méjì àtààbọ̀ yòókù ní òdìkejì* Jọ́dánì,+ àmọ́ kò pín ogún kankan fún àwọn ọmọ Léfì láàárín wọn.+ 4 Ẹ̀yà méjì ni wọ́n ka àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù sí,+ ìyẹn Mánásè àti Éfúrémù;+ wọn ò pín lára ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Léfì, àfi àwọn ìlú+ tí wọ́n á máa gbé àti ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn wọn á ti máa jẹko, tí ohun ìní wọn sì máa wà.+ 5 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá pín ilẹ̀ náà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́.

6 Àwọn ọkùnrin Júdà wá bá Jóṣúà ní Gílígálì,+ Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè, ọmọ Kénásì sì sọ fún un pé: “O mọ ohun tí Jèhófà sọ+ dáadáa, ohun tó sọ fún Mósè èèyàn Ọlọ́run tòótọ́+ nípa èmi àti ìwọ ní Kadeṣi-báníà.+ 7 Ẹni ogójì (40) ọdún ni mí nígbà tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà rán mi láti Kadeṣi-báníà lọ ṣe amí ilẹ̀ náà,+ bọ́rọ̀ sì ṣe rí gẹ́lẹ́* ni mo sọ ọ́ nígbà tí mo dé.+ 8 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn arákùnrin mi tí a jọ lọ mú kí ọkàn àwọn èèyàn wa domi,* mo fi gbogbo ọkàn mi tẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run mi.*+ 9 Mósè búra ní ọjọ́ yẹn pé: ‘Ilẹ̀ tí o fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ̀ máa di ogún ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ títí lọ, torí pé o ti fi gbogbo ọkàn rẹ tẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run mi.’+ 10 Bí Jèhófà ṣe ṣèlérí,+ ó dá ẹ̀mí mi sí+ jálẹ̀ ọdún márùndínláàádọ́ta (45) yìí, látìgbà tí Jèhófà ti ṣe ìlérí yìí fún Mósè, nígbà tí Ísírẹ́lì rìn nínú aginjù;+ èmi náà rèé lónìí, lẹ́ni ọdún márùndínláàádọ́rùn-ún (85). 11 Mo ṣì lágbára lónìí bíi ti ọjọ́ tí Mósè rán mi jáde. Agbára mi ò dín kù sí tìgbà yẹn, mo lè jagun, mo sì lè ṣe àwọn nǹkan míì. 12 Torí náà, fún mi ní agbègbè olókè yìí, tí Jèhófà ṣèlérí ní ọjọ́ yẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o gbọ́ lọ́jọ́ yẹn pé àwọn Ánákímù+ wà níbẹ̀, wọ́n sì ní àwọn ìlú olódi tó tóbi,+ ó dájú pé* Jèhófà máa wà pẹ̀lú mi,+ màá sì lé wọn kúrò,* bí Jèhófà ṣe ṣèlérí.”+

13 Jóṣúà wá súre fún un, ó sì fún Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ní Hébúrónì pé kó jẹ́ ogún rẹ̀.+ 14 Ìdí nìyẹn tí Hébúrónì fi jẹ́ ogún Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ọmọ Kénásì títí dòní, torí ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 15 Kiriati-ábà+ ni Hébúrónì ń jẹ́ tẹ́lẹ̀ (Ábà jẹ́ ẹni ńlá láàárín àwọn Ánákímù). Ogun sì dáwọ́ dúró ní ilẹ̀ náà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́