ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Onídàájọ́ 17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àwọn Onídàájọ́

      • Àwọn ère Míkà àti àlùfáà rẹ̀ (1-13)

Àwọn Onídàájọ́ 17:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 17:14, 15

Àwọn Onídàájọ́ 17:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ère dídà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:4; Le 26:1; Di 27:15

Àwọn Onídàájọ́ 17:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ère dídà.”

Àwọn Onídàájọ́ 17:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”

  • *

    Ní Héb., “fi kún ọwọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 28:6; Ond 8:27
  • +Jẹ 31:19
  • +Nọ 3:10; Di 12:11, 13; 2Kr 13:8, 9

Àwọn Onídàájọ́ 17:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ohun tó rò pé ó tọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 8:4, 5
  • +Ond 21:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2005, ojú ìwé 27

Àwọn Onídàájọ́ 17:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 5:2
  • +Nọ 3:45; Joṣ 14:3; 18:7

Àwọn Onídàájọ́ 17:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 17:1, 5

Àwọn Onídàájọ́ 17:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “agbani-nímọ̀ràn.”

Àwọn Onídàájọ́ 17:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “fi kún ọwọ́ ọmọ Léfì náà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:10; Ond 17:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 1/2022, ojú ìwé 1

Àwọn míì

Oníd. 17:1Joṣ 17:14, 15
Oníd. 17:3Ẹk 20:4; Le 26:1; Di 27:15
Oníd. 17:5Ẹk 28:6; Ond 8:27
Oníd. 17:5Jẹ 31:19
Oníd. 17:5Nọ 3:10; Di 12:11, 13; 2Kr 13:8, 9
Oníd. 17:61Sa 8:4, 5
Oníd. 17:6Ond 21:25
Oníd. 17:7Mik 5:2
Oníd. 17:7Nọ 3:45; Joṣ 14:3; 18:7
Oníd. 17:8Ond 17:1, 5
Oníd. 17:12Nọ 3:10; Ond 17:5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àwọn Onídàájọ́ 17:1-13

Àwọn Onídàájọ́

17 Ọkùnrin kan wà ní agbègbè olókè Éfúrémù+ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Míkà. 2 Ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún (1,100) ẹyọ fàdákà tí wọ́n kó lọ́dọ̀ rẹ, tí mo gbọ́ tí o gégùn-ún nípa rẹ̀, wò ó! fàdákà náà wà lọ́wọ́ mi. Èmi ni mo kó o.” Ni ìyá rẹ̀ bá sọ pé: “Kí Jèhófà bù kún ọ, ọmọ mi.” 3 Ó wá kó ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún (1,100) ẹyọ fàdákà náà pa dà fún ìyá rẹ̀, àmọ́ ìyá rẹ̀ sọ pé: “Ó dájú pé màá ya fàdákà náà sí mímọ́ fún Jèhófà látọwọ́ mi, kí ọmọ mi lè fi ṣe ère gbígbẹ́ àti ère onírin.*+ Mo fún ọ pa dà báyìí.”

4 Lẹ́yìn tó dá fàdákà náà pa dà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ mú igba (200) ẹyọ fàdákà, ó sì fún alágbẹ̀dẹ fàdákà. Ó ṣe ère gbígbẹ́ àti ère onírin;* wọ́n sì gbé e sínú ilé Míkà. 5 Ọkùnrin tó ń jẹ́ Míkà yìí ní ilé kan tó kó àwọn ọlọ́run rẹ̀ sí, ó ṣe éfódì kan+ àti àwọn ère tẹ́ráfímù,*+ ó sì yan* ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ pé kó jẹ́ àlùfáà rẹ̀.+ 6 Nígbà yẹn, kò sí ọba ní Ísírẹ́lì.+ Kálukú ń ṣe ohun tó tọ́ lójú ara rẹ̀.*+

7 Ọ̀dọ́kùnrin kan wà tó jẹ́ ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ní Júdà, látinú ìdílé Júdà. Ọmọ Léfì+ ni, ó sì ti ń gbé níbẹ̀ fúngbà díẹ̀. 8 Ọkùnrin náà kúrò nílùú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà, ó ń wá ibi tó máa gbé. Bó ṣe ń rìnrìn àjò lọ, ó dé agbègbè olókè Éfúrémù, ní ilé Míkà.+ 9 Míkà wá bi í pé: “Ibo lo ti wá?” Ó fèsì pé: “Ọmọ Léfì ni mí, láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà, mò ń wá ibi tí mo lè máa gbé.” 10 Míkà wá sọ fún un pé: “Dúró sọ́dọ̀ mi, kí o di bàbá* àti àlùfáà fún mi. Màá máa fún ọ ní ẹyọ fàdákà mẹ́wàá lọ́dún, pẹ̀lú àwọn aṣọ àti oúnjẹ tí wàá máa jẹ.” Ọmọ Léfì náà sì wọlé. 11 Bí ọmọ Léfì náà ṣe gbà láti máa gbé lọ́dọ̀ ọkùnrin náà nìyẹn, ọ̀dọ́kùnrin náà sì wá dà bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀. 12 Yàtọ̀ síyẹn, Míkà fiṣẹ́ lé ọmọ Léfì náà lọ́wọ́* pé kó di àlùfáà rẹ̀,+ ó sì ń gbé ní ilé Míkà. 13 Míkà wá sọ pé: “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé Jèhófà máa ṣe rere sí mi, torí pé ọmọ Léfì ti di àlùfáà mi.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́