ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 28
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọba Tírè (1-10)

        • Ó ń sọ pé “ọlọ́run ni mí” (2, 9)

      • Orin arò nípa ọba Tírè (11-19)

        • “O wà ní Édẹ́nì” (13)

        • “Kérúbù aláàbò tí mo fòróró yàn” (14)

        • ‘O di aláìṣòdodo’ (15)

      • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Sídónì (20-24)

      • Ọlọ́run yóò tún kó Ísírẹ́lì jọ (25, 26)

Ìsíkíẹ́lì 28:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 28:5
  • +Isk 27:4

Ìsíkíẹ́lì 28:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 2:48

Ìsíkíẹ́lì 28:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sek 9:3

Ìsíkíẹ́lì 28:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 23:1, 3; Isk 27:12

Ìsíkíẹ́lì 28:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 30:10, 11
  • +Ais 23:9

Ìsíkíẹ́lì 28:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sàréè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 27:26

Ìsíkíẹ́lì 28:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aláìkọlà.”

Ìsíkíẹ́lì 28:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”

  • *

    Ní Héb., “O fi èdìdì di àwòṣe kan.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 28:3
  • +Isk 27:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2005, ojú ìwé 23-24

Ìsíkíẹ́lì 28:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 27:16

Ìsíkíẹ́lì 28:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 14:13

Ìsíkíẹ́lì 28:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joẹ 3:4; Emọ 1:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 8/2017, ojú ìwé 1

Ìsíkíẹ́lì 28:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 10:11; 2Kr 9:21; Isk 27:12
  • +Joẹ 3:6
  • +Ais 23:9; Jer 25:17, 22; 47:4; Joẹ 3:8

Ìsíkíẹ́lì 28:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 27:3
  • +Ais 14:14
  • +Ais 14:15

Ìsíkíẹ́lì 28:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Emọ 1:9, 10

Ìsíkíẹ́lì 28:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 27:35
  • +Isk 27:36

Ìsíkíẹ́lì 28:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 23:4; Jer 25:17, 22; Isk 32:30

Ìsíkíẹ́lì 28:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 26:6

Ìsíkíẹ́lì 28:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 33:55; Joṣ 23:12, 13

Ìsíkíẹ́lì 28:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 30:3; Ais 11:12; Jer 30:18; Ho 1:11
  • +Ais 5:16
  • +Jer 23:8
  • +Jẹ 28:13

Ìsíkíẹ́lì 28:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 32:18; Jer 23:6; Ho 2:18
  • +Ais 65:21, 22; Jer 31:5; Emọ 9:14
  • +Jer 30:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 110

Àwọn míì

Ìsík. 28:2Isk 28:5
Ìsík. 28:2Isk 27:4
Ìsík. 28:3Da 2:48
Ìsík. 28:4Sek 9:3
Ìsík. 28:5Ais 23:1, 3; Isk 27:12
Ìsík. 28:7Isk 30:10, 11
Ìsík. 28:7Ais 23:9
Ìsík. 28:8Isk 27:26
Ìsík. 28:12Isk 28:3
Ìsík. 28:12Isk 27:3
Ìsík. 28:13Isk 27:16
Ìsík. 28:14Ais 14:13
Ìsík. 28:15Joẹ 3:4; Emọ 1:9
Ìsík. 28:161Ọb 10:11; 2Kr 9:21; Isk 27:12
Ìsík. 28:16Joẹ 3:6
Ìsík. 28:16Ais 23:9; Jer 25:17, 22; 47:4; Joẹ 3:8
Ìsík. 28:17Isk 27:3
Ìsík. 28:17Ais 14:14
Ìsík. 28:17Ais 14:15
Ìsík. 28:18Emọ 1:9, 10
Ìsík. 28:19Isk 27:35
Ìsík. 28:19Isk 27:36
Ìsík. 28:21Ais 23:4; Jer 25:17, 22; Isk 32:30
Ìsík. 28:23Isk 26:6
Ìsík. 28:24Nọ 33:55; Joṣ 23:12, 13
Ìsík. 28:25Di 30:3; Ais 11:12; Jer 30:18; Ho 1:11
Ìsík. 28:25Ais 5:16
Ìsík. 28:25Jer 23:8
Ìsík. 28:25Jẹ 28:13
Ìsík. 28:26Ais 32:18; Jer 23:6; Ho 2:18
Ìsík. 28:26Ais 65:21, 22; Jer 31:5; Emọ 9:14
Ìsík. 28:26Jer 30:16
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 28:1-26

Ìsíkíẹ́lì

28 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, sọ fún aṣáájú Tírè pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:

“Torí pé ò ń gbéra ga nínú ọkàn rẹ,+ tí o sì ń sọ pé, ‘ọlọ́run ni mí.

Orí ìtẹ́ ọlọ́run ni mo jókòó sí láàárín òkun.’+

Àmọ́ èèyàn lásán ni ọ́, o kì í ṣe ọlọ́run,

Bí o tiẹ̀ ń pe ara rẹ ní ọlọ́run nínú ọkàn rẹ.

 3 Wò ó! O gbọ́n ju Dáníẹ́lì lọ.+

Kò sí àṣírí tó pa mọ́ fún ọ.

 4 O ti fi ọgbọ́n àti òye rẹ sọ ara rẹ di ọlọ́rọ̀,

O sì ń kó wúrà àti fàdákà jọ síbi ìṣúra rẹ.+

 5 Bí o ṣe já fáfá nídìí òwò rẹ ti mú kí ọrọ̀ rẹ pọ̀ rẹpẹtẹ,+

O sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga nínú ọkàn rẹ nítorí ọrọ̀ rẹ.”’

6 “‘Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:

“Torí ò ń pe ara rẹ ní ọlọ́run nínú ọkàn rẹ,

 7 Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì wá bá ọ jà, àwọn tó burú jù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+

Wọn yóò fa idà yọ sí gbogbo ohun tó rẹwà tí o fi ọgbọ́n rẹ kó jọ,

Wọn yóò sì sọ ògo rẹ tó rẹwà di aláìmọ́.+

 8 Wọn yóò mú kí o lọ sínú kòtò,*

Ìwọ yóò sì kú ikú oró sáàárín òkun.+

 9 Ṣé wàá ṣì sọ fún ẹni tó fẹ́ pa ọ́ pé, ‘ọlọ́run ni mí?’

Èèyàn lásán lo máa jẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó ń sọ ọ́ di aláìmọ́, o ò ní jẹ́ ọlọ́run.”’

10 ‘Ìwọ yóò kú lọ́wọ́ àwọn àjèjì bí aláìdádọ̀dọ́,*

Torí èmi fúnra mi ti sọ̀rọ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”

11 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀ pé: 12 “Ọmọ èèyàn, kọ orin arò* nípa ọba Tírè, kí o sì sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:

“O jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tó pé,*

Ọgbọ́n kún inú rẹ,+ ẹwà rẹ ò sì lábùlà.+

13 O wà ní Édẹ́nì, ọgbà Ọlọ́run.

Gbogbo òkúta iyebíye ni mo fi ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́,

Rúbì, tópásì àti jásípérì; kírísóláítì, ónísì àti jéèdì; sàfáyà, tọ́kọ́wásì+ àti émírádì;

Wúrà sì ni mo fi ṣe ojú ibi tí wọ́n lẹ̀ wọ́n mọ́.

Ọjọ́ tí mo dá ọ ni mo ṣe wọ́n.

14 Mo fi ọ́ ṣe kérúbù aláàbò tí mo fòróró yàn.

O wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run,+ o sì rìn kiri láàárín àwọn òkúta oníná.

15 Àwọn ọ̀nà rẹ pé látọjọ́ tí mo ti dá ọ,

Títí o fi di aláìṣòdodo.+

16 Torí òwò rẹpẹtẹ tí ò ń ṣe,+

Ìwà ipá kún inú rẹ, o sì bẹ̀rẹ̀ sí í dẹ́ṣẹ̀.+

Torí náà, màá ta ọ́ nù kúrò ní òkè Ọlọ́run bí ẹni tí wọ́n kẹ́gàn, màá sì pa ọ́ run,+

Ìwọ kérúbù aláàbò, màá pa ọ́ run kúrò láàárín àwọn òkúta oníná.

17 O bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga nínú ọkàn rẹ torí ẹwà rẹ.+

Ògo rẹ tó rẹwà mú kí o ba ọgbọ́n rẹ jẹ́.+

Èmi yóò jù ọ́ sí ilẹ̀.+

Màá sì mú kí àwọn ọba fi ọ́ ṣe ìran wò.

18 O ti sọ àwọn ibi mímọ́ rẹ di aláìmọ́ nítorí pé ẹ̀bi rẹ pọ̀, o ò sì ṣòótọ́ nídìí òwò rẹ.

Màá mú kí iná sọ láàárín rẹ, yóò sì jẹ ọ́ run.+

Màá sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀ lójú gbogbo àwọn tó ń wò ọ́.

19 Gbogbo àwọn tó mọ̀ ọ́ láàárín àwọn èèyàn yóò wò ọ́ tìyanutìyanu.+

Ìparun rẹ yóò dé lójijì, yóò sì burú jáì,

O ò sì ní sí mọ́ títí láé.”’”+

20 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 21 “Ọmọ èèyàn, yíjú rẹ sọ́dọ̀ Sídónì,+ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí rẹ̀. 22 Kí o sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:

“Màá bá ọ jà, ìwọ Sídónì, wọ́n á sì yìn mí lógo láàárín rẹ;

Àwọn èèyàn á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá dá a lẹ́jọ́, tí mo sì fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ nínú rẹ̀.

23 Màá fi àjàkálẹ̀ àrùn kọ lù ú, ẹ̀jẹ̀ á sì ṣàn ní àwọn ojú ọ̀nà rẹ̀.

Àwọn tí wọ́n pa yóò ṣubú láàárín rẹ̀ nígbà tí idà bá dojú kọ ọ́ láti ibi gbogbo;

Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+

24 “‘“Ẹ̀gún tó ń ṣeni léṣe àti òṣùṣú tó ń roni lára kò ní yí ilé Ísírẹ́lì ká mọ́,+ àwọn ló ń fi ilé Ísírẹ́lì ṣe ẹlẹ́yà; àwọn èèyàn á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”’

25 “‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Nígbà tí mo bá tún kó ilé Ísírẹ́lì jọ láti àárín àwọn èèyàn tí wọ́n fọ́n ká sí,+ màá fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ láàárín wọn lójú àwọn orílẹ̀-èdè.+ Wọ́n á sì máa gbé lórí ilẹ̀ wọn+ tí mo fún Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi.+ 26 Wọn yóò máa gbé ibẹ̀, ààbò yóò sì wà lórí wọn,+ wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n á gbin ọgbà àjàrà,+ nígbà tí mo bá ṣèdájọ́ gbogbo àwọn tó yí wọn ká tó ń fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,+ ààbò yóò wà lórí wọn; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn.”’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́