Wíwéwèé Ṣáájú—Fún Àwọn Olólùfẹ́ Wa
ÌTÀN bíbaninínújẹ́ ti Annie fara hàn láìpẹ́ yìí nínú ìwé agbéròyìnjáde kan ní Áfíríkà. Oníṣòwò ni ọkọ Annie. Ó kú ní ọdún 1995, ó fi ọkọ̀ 15; owó rẹpẹtẹ ní onírúurú báǹkì; nǹkan bí 4,000 owó dọ́là (U.S.); ṣọ́ọ̀bù kan; ilé ọtí kan; àti ilé oníyàrá mẹ́ta sílẹ̀. Ṣùgbọ́n kò fi ìwé ìhágún sílẹ̀.
Ìròyìn náà sọ pé, ẹ̀gbọ́n ọkọ Annie tí ó jẹ́ ọkùnrin gbẹ́sẹ̀ lé ohun ìní àti owó náà, ó sì fi ipá lé obìnrin náà àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́fà kúrò nínú ilé wọn. Láìní ohunkóhun, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ ń gbé nísinsìnyí pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin. Mẹ́rin nínú àwọn ọmọ náà ní láti fi ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀, níwọ̀n bí kò ti sí owó láti fi san owó ilé ẹ̀kọ́ tàbí láti fi ra ẹ̀wù ilé ẹ̀kọ́ fún wọn.
Annie mú ọ̀ràn náà lọ sí ilé ẹjọ́ gíga, tí ó dájọ́ pé kí a dá díẹ̀ nínú ohun ìní náà pa dà fún un, títí kan ọkọ̀ kan. Ṣùgbọ́n, wọn kò dá ohunkóhun pa dà fún un. Ó ní láti pa dà lọ sí ilé ẹjọ́, láti gba àṣẹ tí yóò fipá mú ẹ̀gbọ́n ọkọ rẹ̀ láti ṣe ohun tí ilé ẹjọ́ sọ.
Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí O Ronú Nípa Ikú?
Ìtàn Annie lani lóye nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ nígbà tí olórí ìdílé bá kùnà láti wéwèé fún ṣíṣeé ṣe rẹ̀ láti kú. Nígbà ikú, gbogbo ènìyàn “ń fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.” (Orin Dáfídì 49:10) Síwájú sí i, àwọn òkú kò lágbára lórí ohun tí a fi ohun ìní wọn ṣe. (Oníwàásù 9:5, 10) Láti lè láṣẹ lórí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ohun ìní rẹ̀, ẹnì kan ní láti ṣètò dáradára kí ó tó kú.
Bí gbogbo wá tilẹ̀ mọ̀ pé a lè kú láìròtẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń kùnà láti ṣe ìpèsè sílẹ̀ fún àwọn olólùfẹ̀ẹ́ wọn tí wọ́n fi sílẹ̀. Bí ìjíròrò wa yóò tilẹ̀ darí àfiyèsí sórí àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ kan ní Áfíríkà, àwọn ìṣòro tí ó jọ ọ́ ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn apá yòó kù lórí ilẹ̀ ayé.
Yálà o gbégbèésẹ̀ nípa bí a óò ṣe pín ohun ìní rẹ, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o kú tàbí o kò ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni. (Gálátíà 6:5) Síbẹ̀, ẹnì kan lè béèrè pé, ‘Èé ṣe tí ọkùnrin kan yóò ṣìkẹ́, tí yóò sì tọ́jú aya rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí ó wà láàyè, ṣùgbọ́n tí kò ní ṣe ìpèsè kankan fún àbójútó wọn, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó kú?’ Ìdí pàtàkì kan ni pé, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa kì í fẹ́ láti ronú nípa ṣíṣeé ṣe pé a lè kú, kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ wíwéwèé fún ikú. Ní tòótọ́, a kò lè mọ ọjọ́ ikú wa, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí pé: “Ẹyin kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la. Nítorí ìkùukùu ni yín tí ń fara hàn fún ìgbà díẹ̀ àti lẹ́yìn náà tí ń dàwátì.”—Jákọ́bù 4:14.
Wíwéwèé fún ṣíṣeé ṣe pé a óò kú jẹ́ ohun tí ó bọ́gbọ́n mu. Ó tún ń fi àníyàn onífẹ̀ẹ́ tí a ní fún àwọn tí a fi sílẹ̀ hàn. Bí a kò bá ṣètò àlámọ̀rí wa, àwọn ẹlòmíràn yóò ṣe é fún wa. Bóyá àwọn ènìyàn tí a kò rìnnà kò rí ni yóò ṣe ìpinnu nípa àwọn ohun ìní wa àti nípa ìṣètò ìsìnkú wa. Lábẹ́ irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ìjọba ni yóò pinnu ẹni tí yóò jogún owó àti ohun ìní wa. Ní àwọn ibòmíràn, àwọn ìbátan ní ń ṣe ìpinnu náà, ìkùnsínú, tí ń fa ìyannilọ́tàá láàárín ìdílé sì sábà máa ń bá àwọn ìpinnu wọ̀nyí rìn. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ohun tí a pinnu lè yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ìwọ yóò fẹ́.
Dídu Ohun Ìní
Opó ni ó ń jìyà jù lọ nígbà tí ọkọ rẹ̀ bá kú. Yàtọ̀ sí ẹ̀dùn pípàdánù alábàá-ṣègbéyàwó rẹ̀, àwọn ènìyàn sábà máa ń bá a du ohun ìní. A ṣàpèjúwe èyí lókè nínú ọ̀ràn Annie. Ara ìdí fún dídu ohun ìní ní í ṣe pẹ̀lú ojú tí a fi ń wo aya. Ní àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan, a kò ka aya ọkùnrin kan sí apá kan ìdílé rẹ̀. Ó jẹ́ àjèjì, tí ó lè pa dà sí ilé bàbá rẹ̀ tàbí kí a fẹ́ ẹ sínú ìdílé mìíràn nígbàkigbà. Ní ìyàtọ̀ pátápátá, ìrònú náà ni pé, ẹ̀gbọ́n, àbúrò, àti àwọn òbí ọkùnrin kan kò ní í fi í sílẹ̀ láé. Bí ó bá kú, àwọn ìdílé rẹ̀ gbà gbọ́ pé tiwọn ni ohun ìní rẹ̀, kì í ṣe ti aya àti àwọn ọmọ rẹ̀.
Àwọn ọkọ tí kì í fọkàn tán àwọn aya wọn ń gbé irú ìrònú bẹ́ẹ̀ lárugẹ. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ nìkan ṣoṣo ni Mike máa ń bá jíròrò okòwò rẹ̀. Wọ́n mọ ohun tí ó ní, ṣùgbọ́n ìwọ̀nba ni ohun tí aya rẹ̀ mọ̀. Nígbà tí ó kú, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wá sọ́dọ̀ aya rẹ̀, wọ́n sì ní kí ó fún wọn ní owó tí ọkọ rẹ̀ ti ń retí lọ́dọ̀ onígbèsè rẹ̀. Obìnrin náà kò tilẹ̀ mọ ohunkóhun nípa rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ẹ̀rọ̀ ìdàwékọ àti ìtẹ̀wé tí ọkọ rẹ̀ rà fún un. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ gba ilé rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀. Wọ́n fipá lé opó yìí àti ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré jáde, pẹ̀lú kìkì aṣọ wọn lọ́wọ́.
“Àwọn Méjèèjì Yóò sì Di Ẹran Ara Kan”
Àwọn Kristẹni ọkọ nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn, wọ́n sì kà wọ́n sí ẹni tí ó ṣeé fọkàn tán. Irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ń fi ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ náà sọ́kàn pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn.” Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tún gbà pẹ̀lú gbólóhùn tí Ọlọ́run mí sí náà pé: “Ọkùnrin yóò fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ òun yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ẹran ara kan.”—Éfésù 5:28, 31.
Àwọn ọkọ oníwà-bí-Ọlọ́run tún gbà pẹ̀lú Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí ó kọ̀wé pé: “Dájúdájú bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, òun ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (Tímótì Kíní 5:8) Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà yí, bí Kristẹni ọkọ kan bá wéwèé láti rìnrìn àjò lọ sí ọ̀nà jíjìn, yóò rí sí i pé ìyà kò jẹ ìdílé rẹ̀ nígbà tí ó bá lọ. Bákan náà, kò ha bọ́gbọ́n mu pé kí ó pèsè fún aya rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó kú? Kì í ṣe pé ó bọ́gbọ́n mu nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ ìwà onífẹ̀ẹ́ láti ṣètò fún ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ òjijì.
Àwọn Àṣà Ìsìnkú
Fún àwọn Kristẹni ọkọ, apá mìíràn tún wà sí ọ̀ràn yí tí ó yẹ kí wọ́n gbé yẹ̀ wò. Láti dá kún ẹ̀dùn ọkàn opó nítorí pípàdánù alábàá-ṣègbéyàwó rẹ̀, ohun ìní rẹ̀, àti bóyá àwọn ọmọ rẹ̀ pàápàá, àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ kan fi dandan lé e pé kí ó ṣe àwọn ààtò ọ̀fọ̀ ìṣẹ̀dálẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde The Guardian ti Nàìjíríà kédàárò pé, ní àwọn àgbègbè kan, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ń béèrè pé kí opó kan sùn sínú yàrá tí ó ṣókùnkùn tí a gbé òkú ọkọ rẹ̀ sí. Ní àwọn ibòmíràn, a kì í yọ̀ǹda fún àwọn opó láti fi ilé wọn sílẹ̀ ní àkókò ọ̀fọ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó oṣù mẹ́fà. Ní àkókò yẹn, wọn kò gbọ́dọ̀ wẹ̀, a tilẹ̀ kà á léèwọ̀ fún wọn láti wẹ ọwọ́ wọn ṣáájú tàbí lẹ́yìn oúnjẹ.
Irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ máa ń mú ìṣòro wá, pàápàá fún àwọn opó Kristẹni. Ìfẹ́ ọkàn wọn láti wu Ọlọ́run ń sún wọn láti yẹra fún àwọn àṣà tí kò bá ẹ̀kọ́ Bíbélì mu. (Kọ́ríńtì Kejì 6:14, 17) Ṣùgbọ́n, nítorí tí kò lọ́wọ́ sí àwọn àṣà wọ̀nyí, a lè ṣenúnibíni sí opó kan. Ó tilẹ̀ lè pọn dandan fún un láti sá lọ kí wọ́n má baà pa á.
Fífẹsẹ̀ Òfin Tọ̀ Ọ́
Pẹ̀lú ọgbọ́n, Bíbélì sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” (Òwe 21:5, NW) Irú ìwéwèé wo ni olórí ìdílé kan lè ṣe? Nínú ọ̀pọ̀ jù lọ àwùjọ, ó ṣeé ṣe láti ṣe ìwé ìhágún tàbí láti kọ ìwé kan tí ń sọ bí ẹnì kan ṣe fẹ́ kí a pín ohun ìní òun bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé òun kú. Ó lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ètò ìsìnkú rẹ̀ nínú. Ìwé náà lè tún sọ ní kedere nípa ohun tí alábàá-ṣègbéyàwó gbọ́dọ̀ ṣe (tàbí kò gbọ́dọ̀ ṣe) ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìsìnkú àti àṣà ìṣọ̀fọ̀.
Obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Leah pàdánù ọkọ rẹ̀ nínú ikú ní 1992. Ó sọ pé: “Ọmọ márùn-ún ni mo bí—obìnrin mẹ́rin àti ọkùnrin kan. Ọkọ mí ṣàìsàn fún àkókò gígùn kí ó tó kú. Ṣùgbọ́n, kí ó tilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ àìsàn rẹ̀ pàápàá, ó ṣe ìwé ìhágún rẹ̀, tí ó sọ pé òun ń fẹ́ kí gbogbo ohun ìní òun di tèmi àti ti àwọn ọmọ wa. Èyí ní owó ìbánigbófò, ilẹ̀ oko, àwọn ẹran ọ̀sìn, àti ilé nínú. Ó fọwọ́ sí ìwé ìhágún náà, ó sì fi lé mi lọ́wọ́. . . . Lẹ́yìn ikú ọkọ mi, àwọn ìbátan rẹ̀ ń fẹ́ ogún tiwọn. Mo jẹ́ kí ó yé wọn pé, owó ọkọ mi ni ó fi ra ilẹ̀ oko náà, wọn kò sì ní ẹ̀tọ́ láti sọ pé ohunkóhun jẹ́ tiwọn. Nígbà tí wọ́n rí ìwé ìhágún náà, wọ́n tẹ́wọ́ gbà á.”
Jíjíròrò Ọ̀ràn Pẹ̀lú Ìdílé Rẹ
Ìṣòro lè dìde bí ẹnì kan kò bá bá ìdílé rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti àwọn ohun tí ó ń fẹ́. Gbé ọ̀ràn ọkùnrin kan tí àwọn ìbátan rẹ̀ fàáké kọ́rí pé abúlé ni wọ́n yóò ti sín in ní ìbámu pẹ̀lú àṣà ìbílẹ̀ yẹ̀ wò. Nígbà tí a fi ẹ̀mí wọn sínú ewu, a fipá mú opó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti fi òkú náà sílẹ̀ fún àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀. Opó náà kédàárò pé: “Ká ní ọkọ mi ti sọ fún ẹ̀gbọ́n bàbá rẹ̀ tàbí ọmọ ẹ̀gbọ́n bàbá rẹ̀ kan nípa bí ó ti fẹ́ kí a sin òun, ìdílé náà kò bá tí fàáké kọ́rí láti sin ín lọ́nà àṣà ìsìnkú ìbílẹ̀ wọn.”
Ní àwọn àwùjọ kan, wọ́n ka àdéhùn ọ̀rọ̀ ẹnu lásán sí pàtàkì bíi èyí tí a kọ sílẹ̀. Bí ipò nǹkan ti rí nìyí ní apá kan Swaziland, níbi tí ọ̀pọ̀ ti ní ìgbàgbọ́ tí ó fún ìgbésẹ̀ ayẹyẹ ìsìnkú àti ìṣọ̀fọ̀ níṣìírí. Ní mímọ èyí, Kristẹni ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Isaac pe ìpàdé mọ̀lẹ́bí, tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì jíròrò ohun tí ó fẹ́ kí wọ́n ṣe lẹ́yìn ikú òun. Ó sọ fún wọn ohun tí ó fẹ́ kí olúkúlùkù wọ́n jogún, ó sì ṣàlàyé ní kedere bí ó ṣe fẹ́ kí wọ́n ṣe ìsìnkú òun. Lẹ́yìn ikú rẹ̀, ohun gbogbo ṣẹlẹ̀ bí ó ti fẹ́. Wọ́n sin Isaac bí a ti ń sin Kristẹni, a sì tọ́jú aya rẹ̀ dáradára.
Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ
Ohun tí ìwọ yóò ṣe láti dáàbò bo ìdílé rẹ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o kú jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni, ṣùgbọ́n Kristẹni kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Edward sọ pé: “Mo ṣe ìwé ìbánigbófò ẹ̀mí kí gbogbo mẹ́ńbà ìdílé mi mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ lè jàǹfààní nínú rẹ̀. Orúkọ aya mi wà nínú àkáǹtì mi ní báǹkì. Nítorí náà, bí n bá kú, ó lè lọ gba owó nínú àkáǹtì mi. . . . Mo ṣe ìwé ìhágún láti ṣe ìdílé mi láǹfààní. Bí n bá kú, ohunkóhun tí mo bá fi sílẹ̀ yóò jẹ́ fún aya mi àti àwọn ọmọ mi. Mo ti kọ ìwé ìhágún mi láti ọdún márùn-ún sẹ́yìn. Amòfin kan ni ó ṣètò rẹ̀, aya mi àti ọmọkùnrin mi sì ní ẹ̀dà kan lọ́wọ́. Nínú ìwé ìhágún mi, mo sọ ọ́ ní kedere pé àwọn ìbátan mi kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ nínú ètò ìsìnkú mi. Ètò àjọ Jèhófà ni ó ni mí. Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí kan tàbí méjì ni ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣètò ìsìnkú mi, ìyẹn ti tó. Mo ti jíròrò èyí pẹ̀lú àwọn ìbátan mi.”
Ní ọ̀nà kan, ṣíṣe irú ètò bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn kan fún ìdílé rẹ. Dájúdájú, wíwéwèé fún ṣíṣeé ṣe láti kú kì í ṣe irú ẹ̀bùn ṣokoléètì tàbí ti ìdìpọ̀ òdòdó. Síbẹ̀, ó fi ìfẹ́ rẹ hàn. Ó fẹ̀rí hàn pé o fẹ́ ‘pèsè fún àwọn tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà agbo ilé rẹ’ àní nígbà tí o kò sí pẹ̀lú wọn mọ́ pàápàá.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Jésù Pèsè fún Ìyá Rẹ̀
“Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́bàá òpó igi oró Jésù ni ìyá rẹ̀ àti arábìnrin ìyá rẹ̀ dúró; Màríà aya Kílópà, àti Màríà Magidalénì. Nítorí náà, ní rírí ìyá rẹ̀ àti ọmọ ẹ̀yìn náà tí òun nífẹ̀ẹ́ tí ó dúró nítòsí, Jésù wí fún ìyá rẹ̀ pé: ‘Obìnrin, wò ó! Ọmọkùnrin rẹ!’ Lẹ́yìn náà ó wí fún ọmọ ẹ̀yìn náà pé: ‘Wò ó! Ìyá rẹ!’ Láti wákàtí yẹn lọ ọmọ ẹ̀yìn náà [Jòhánù] sì mú un lọ sí ilé ara rẹ̀.”—Jòhánù 19:25-27.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ọ̀pọ̀ Kristẹni fi ìrònújinlẹ̀ fẹsẹ̀ òfin tọ̀ ọ́ láti dáàbò bo ìdílé wọn