ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 1/15 ojú ìwé 29-31
  • Fílémónì àti Ónẹ́símù—Ẹ̀mí Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Kristẹni So Wọ́n Pọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fílémónì àti Ónẹ́símù—Ẹ̀mí Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Kristẹni So Wọ́n Pọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìsáǹsá ní Róòmù
  • Pọ́ọ̀lù Ràn Án Lọ́wọ́
  • Ónẹ́símù—Ọkùnrin Tí Ó Ti Yí Pa Dà
  • Ìfẹ́ Ará Jẹ́ Agbékánkánṣiṣẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • ‘Gbigbani Niyanju Lori Ipilẹ Ifẹ’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Pọ́ọ̀lù Ní Róòmù
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Títù, Fílémónì àti Hébérù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 1/15 ojú ìwé 29-31

Fílémónì àti Ónẹ́símù—Ẹ̀mí Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Kristẹni So Wọ́n Pọ̀

Ọ̀KAN nínú àwọn lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ, tí Ọlọ́run mí sí, ní í ṣe pẹ̀lú ìṣòro ẹlẹgẹ́ tí ó wà láàárín àwọn ọkùnrin méjì kan. Ọ̀kan ni Fílémónì, èkejì sì ni Ónẹ́símù. Ta ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí? Kí ni ó mú kí Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ nínú ọ̀ràn wọn?

Kólósè, ní Éṣíà Kékeré, ni Fílémónì tí a kọ lẹ́tà náà sí ń gbé. Láìdàbí àwọn Kristẹni mìíràn ní àgbègbè kan náà, Fílémónì mọ Pọ́ọ̀lù dáradára, níwọ̀n bí ó ti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere nítorí ìgbòkègbodò ìwàásù àpọ́sítélì náà. (Kólósè 1:1; 2:1) Pọ́ọ̀lù mọ̀ ọ́n pé ó jẹ́ ‘olùfẹ́ òun ọ̀wọ́n àti alábàáṣiṣẹ́pọ̀.’ Fílémónì jẹ́ àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́. Ó ní ẹ̀mí aájò àlejò, ó sì jẹ́ orísun ìtura fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Ó hàn gbangba pé Fílémónì tún jẹ́ ẹnì kan tí ó rí já jẹ, níwọ̀n bí ilé rẹ̀ ti tóbi tó láti gba àwọn ìpàdé ìjọ àdúgbò. Àwọn kan sọ pé Ápífíà àti Ákípọ́sì, àwọn méjì míràn tí a sọ̀rọ̀ wọn nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù, lè jẹ́ aya àti ọmọkùnrin rẹ̀. Ó kéré tán, Fílémónì ní ẹrú kan, Ónẹ́símù.—Fílémónì 1, 2, 5, 7, 19b, 22.

Ìsáǹsá ní Róòmù

Ìwé Mímọ́ kò sọ ìdí rẹ̀ fún wa tí Ónẹ́símù fi wà ní ibi tí ó lé ní 1,400 kìlómítà sí ilé rẹ̀, tí ó fi wà lọ́dọ̀ Pọ́ọ̀lù ní Róòmù, níbi tí a ti kọ lẹ́tà tí a kọ sí Fílémónì ní nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù sọ fún Fílémónì pé: “Bí [Ónẹ́símù] bá ti ṣe àìtọ́ èyíkéyìí sí ọ tabi jẹ ọ́ ní gbèsè ohunkóhun, ka èyí sí mi lọ́rùn.” (Fílémónì 18) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí mú un ṣe kedere pé ìṣòro ń bẹ láàárín Ónẹ́símù àti Fílémónì, ọ̀gá rẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ pẹ̀lú ète àtimú kí àwọn ọkùnrin méjèèjì pa dà bá ara wọn rẹ́.

Àwọn kan sọ pé Ónẹ́símù di ìsáǹsá lẹ́yìn tí ó ti jí owó Fílémónì láti baà lè rí owó ná lórí ìrìn àjò sísá tí ó fẹ́ sá lọ sí Róòmù. Ó fẹ́ fara pa mọ́ sáàárín àwọn tí ń gbé níbẹ̀.a Nínú ayé Gíríìkì òun Róòmù, kì í ṣe àwọn tí ó ni ẹrú nìkan ni àwọn ìsáǹsá jẹ́ ìṣòro ńlá fún, ṣùgbọ́n wọ́n tún jẹ́ ìṣòro ńlá fún àwọn alákòóso ìlú. Róòmù fúnra rẹ̀ ni a sọ pé “ó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí ibi ìsádi” fún àwọn ẹrú tí ó ti di ìsáǹsá.

Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe wá bá Ónẹ́símù pàdé? Bíbélì kò sọ fún wa. Ṣùgbọ́n, nígbà tí òmìnira náà tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ tán, tí ojú rẹ̀ sì wálẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Ónẹ́símù mọ̀ pé òun ti kó ara òun sínú ewu. Nínú ìlú Róòmù, àwọn ọlọ́pàá àkànṣe wà tí ń dọdẹ àwọn ẹrú tí ó ti di ìsáǹsá, ẹ̀ṣẹ̀ wọn sì jẹ́ èyí tí ó burú jù lọ nínú òfin ìgbàanì. Gẹ́gẹ́ bí Gerhard Friedrich ti sọ, “a sábà máa ń fi irin gbígbóná jó àwọn ẹrú tí ó di ìsáǹsá tí a bá gbá mú níwájú orí. Lọ́pọ̀ ìgbà a máa ń dá wọn lóró . . . , a máa ń jù wọ́n sí àwọn ẹranko ẹhànnà nínú ìran àpéwò ìta gbangba, tàbí kí a kàn wọ́n mọ́ àgbélébùú láti lè kọ́ àwọn ẹrú yòó kù lọ́gbọ́n láti má ṣe fara wé àpẹẹrẹ wọn.” Friedrich sọ pé ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé, lẹ́yìn tí Ónẹ́símù ti ná owó tí ó jí tán, tí kò sì rí ibi tí yóò fara pamọ́ sí láti gbé tàbí iṣẹ́ tí yóò máa ṣe, ni ó rọ Pọ́ọ̀lù, tí ó ti gbọ́ nípa rẹ̀ nílé Fílémónì, láti ran òun lọ́wọ́, kí ó sì bá òun dá sí ọ̀ràn náà.

Àwọn mìíràn gbà gbọ́ pé ṣe ni Ónẹ́símù dìídì lọ sá bá ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ ọ̀gá rẹ̀, ní ríretí pé nípasẹ̀ agbára onítọ̀hún, òun lè pa dà ní ipò ìbátan tí ó dán mọ́rán pẹ̀lú ọ̀gá tí ó ń bínú sí òun lọ́nà tí ó tọ́ fún àwọn ìdí kan. Àwọn orísun ìtàn fi hàn pé irú ohun bẹ́ẹ̀ “jẹ́ ohun tí àwọn ẹrú tí ó bá wọ ìjàngbọ̀n sábà máa ń ṣe, ó sì jẹ́ àṣà tí ó tàn kálẹ̀.” Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, nígbà náà, olè tí Ónẹ́símù jà “kúkú lè jẹ́ nítorí àtirówó rìnrìn àjò láti lọ pe Pọ́ọ̀lù láti bá òun bẹ̀bẹ̀ dípò tí yóò fi jẹ́ nítorí ọgbọ́n àtisálọ,” ni ohun tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Brian Rapske sọ.

Pọ́ọ̀lù Ràn Án Lọ́wọ́

Ohun yòó wù tí ì báà jẹ́ ìdí tí ó fi sá lọ, ó hàn gbangba pé Ónẹ́símù wá ìrànwọ́ Pọ́ọ̀lù láti lè pa dà mú òun bá ọ̀gá òun tí inú ń bí rẹ́. Ìyẹn gbé ìṣòro kan ka Pọ́ọ̀lù láyà. Ẹnì kan rèé tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́ ẹrú tẹ́lẹ̀, tí ó sì ti di ìsáǹsá ọ̀daràn báyìí. Ó ha yẹ kí àpọ́sítélì náà ràn án lọ́wọ́ nípa yíyí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ Kristẹni lérò pa dà láti má ṣe lo ẹ̀tọ́ rẹ̀ lábẹ́ òfin láti fìyà jẹ ẹ́ bí? Kí ni Pọ́ọ̀lù yóò ṣe báyìí?

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù yóò fi kọ lẹ́tà sí Fílémónì, ó hàn gbangba pé ìsáǹsá náà ti wà pẹ̀lú àpọ́sítélì náà fún ìgbà díẹ̀. Àkókò tí ó ti lò pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù ti tó fún un láti sọ pé Ónẹ́símù ti di “arákùnrin . . . olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Kólósè 4:9) Pọ́ọ̀lù sọ nípa ipò ìbátan rẹ̀ nípa tẹ̀mí pẹ̀lú Ónẹ́símù pé: “Mo ń gbà ọ́ níyànjú nípa ọmọ mi, . . . ẹni tí mo di bàbá fún nígbà tí mo wà nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi.” Nínú gbogbo ohun tí ó lè jẹ́ àbájáde dídá tí ó dá sí ọ̀ràn náà, èyí ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tí Fílémónì kò retí rárá. Àpọ́sítélì náà sọ pé ẹrú tí ó jẹ́ “aláìwúlò” tẹ́lẹ̀ rí ń pa dà gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni arákùnrin. Nísinsìnyí, Ónẹ́símù lè “mú èrè wá,” tàbí “wúlò,” kí ó sì tipa báyìí gbé ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ rẹ̀.—Fílémónì 1:10-12.

Ónẹ́símù ti wá wúlò gidigidi fún àpọ́sítélì náà tí ó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ní tòótọ́, Pọ́ọ̀lù ì bá ti jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ òun, ṣùgbọ́n yàtọ̀ sí pé ó lòdì sí òfin, èyí yóò jẹ́ títẹ ẹ̀tọ́ Fílémónì lójú. (Fílémónì 13, 14) Nínú lẹ́tà míràn tí ó kọ ní àkókò kan náà sí ìjọ tí ó pàdé nílé Fílémónì, Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí Ónẹ́símù gẹ́gẹ́ bí “arákùnrin mi olùṣòtítọ́ àti olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí ó ti àárín yín wá.” Èyí fi hàn pé Ónẹ́símù ti fi ẹ̀rí hàn pé òun ṣeé gbára lé.—Kólósè 4:7-9.b

Pọ́ọ̀lù rọ Fílémónì láti fi inú rere gba Ónẹ́símù, ṣùgbọ́n kò lo ọlá àṣẹ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì láti pàṣẹ fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí láti tú ẹrú rẹ̀ sílẹ̀. Nítorí ọ̀rẹ́ tí wọ́n jẹ́ àti ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ara wọn, ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Fílémónì yóò “ṣe ju” ohun tí òun ní kí ó ṣe lọ. (Fílémónì 21) Ohun tí ‘jù’ lè túmọ̀ sí kò ṣe kedere nítorí Fílémónì nìkan ni ó lẹ́tọ̀ọ́ àtipinnu ohun tí yóò ṣe nípa Ónẹ́símù. Àwọn kan ti lóye ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sí fífọgbọ́n béèrè pé kí a ‘rán ìsáǹsá náà pa dà kí ó baà lè máa ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe.’

Fílémónì ha tẹ́wọ́ gba ẹ̀bẹ̀ Pọ́ọ̀lù fún Ónẹ́símù bí? Ó dà bíi pé kò sí iyè méjì kankan lórí pé ó ṣe bẹ́ẹ̀, bí èyí tilẹ̀ ti lè bí àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ ará Kólósè tí wọ́n ní ẹrú nínú, tí wọ́n sì ti lè fẹ́ láti rí i pé ìyà tí ó tọ́ jẹ Ónẹ́símù kí ó baà lè jẹ́ àríkọ́gbọ́n fún àwọn ẹrú tiwọn láti má ṣe fara wé àpẹẹrẹ rẹ̀.

Ónẹ́símù—Ọkùnrin Tí Ó Ti Yí Pa Dà

Bí ó ti wù kí ó rí, Ónẹ́símù pa dà sí Kólósè pẹ̀lú àkópọ̀ ìwà tuntun. Agbára ìhìn rere ti yí ìrònú rẹ̀ pa dà, kò sí iyè méjì pé ó di mẹ́ńbà olùṣòtítọ́ ti ìjọ Kristẹni nínú ìlú náà. Ìwé Mímọ́ kò fi hàn bóyá Fílémónì dá Ónẹ́símù sílẹ̀ lómìnira lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ṣùgbọ́n, ní ojú ìwòye tẹ̀mí, ìsáǹsá tẹ́lẹ̀ náà ti di òmìnira. (Fi wé Kọ́ríńtì Kíní 7:22.) Irú ìyípadà kan náà ń ṣẹlẹ̀ lónìí. Nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wọn, ipò àti àkópọ̀ ìwà wọn ń yí pa dà. A ń ran àwọn tí a ti kà sí aláìwúlò láwùjọ tẹ́lẹ̀ rí lọ́wọ́ láti di aráàlú tí ó ṣeé wò fi ṣàpẹẹrẹ.c

Ẹ wo irú ìyàtọ̀ tí ìyípadà sí ìgbàgbọ́ tòótọ́ mú wá! Nígbà tí ó jẹ́ pé Ónẹ́símù àtijọ́ ti lè jẹ́ “aláìwúlò” fún Fílémónì, kò sí iyè méjì pé Ónẹ́símù tuntun gbé ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó “mú èrè wá.” Dájúdájú, ó jẹ́ ìbùkún pé ẹ̀mí ẹgbẹ́ àwọn ará Kristẹni so Fílémónì àti Ónẹ́símù pọ̀.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Òfin Róòmù túmọ̀ servus fugitivus (ẹrú tí ó di ìsáǹsá) sí ‘ẹnì kan tí ó sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀, pẹ̀lú ète àtimá pa dà mọ́.’

b Nínú ìrìn àjò wọn pa dà sí Kólósè, ó hàn gbangba pé a fún Ónẹ́símù àti Tíkíkọ́sì ní mẹ́ta nínú àwọn lẹ́tà Pọ́ọ̀lù, tí ó jẹ́ apá kan ìwé Bíbélì nísinsìnyí. Ní àfikún sí lẹ́tà tí ó kọ sí Fílémónì, wọ́n jẹ́ lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Éfésù àti àwọn ará Kólósè.

c Fún àpẹẹrẹ, jọ̀wọ́ wo Jí!, June 22, 1996, ojú ìwé 18 sí 23; March 8, 1997, ojú ìwé 11 sí 13; Ilé Ìṣọ́, August 1, 1989, ojú ìwé 30, 31; February 15, 1997, ojú ìwé 21 sí 24.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]

Àwọn Ẹrú Lábẹ́ Òfin Róòmù

Lábẹ́ òfin Róòmù tí ó múlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, ẹrú wà lábẹ́ agbára ìfẹ́ ọkàn, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àti àkóso ọ̀gá rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí alálàyé Gerhard Friedrich ti sọ, “ní ìpìlẹ̀ àti lábẹ́ òfin, ẹrú kì í ṣe ènìyàn, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìní tí olówó rẹ̀ lè lò bí ó bá ṣe fẹ́. . . . [Ó] wà ní ipò kan náà pẹ̀lú ẹran ọ̀sìn àti irin iṣẹ́, a kò sì kà á sí lábẹ́ òfin ti ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn.” Ẹrú kan kò lè pẹjọ́ nítorí pé a kò fi ẹ̀tọ́ bá a lò. Ní ti gidi, ó ní láti pa àṣẹ ọ̀gá rẹ̀ mọ́ ṣáá ni. Ìyà tí ọ̀gá kan ti inú ń bí lè fi jẹ ẹrú rẹ̀ kò níwọ̀n. Àní fún láìfí tí kò tó nǹkan pàápàá, yóò lo agbára tí ó ní láti dá a sí tàbí láti pa á.*

Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ọlọ́rọ̀ lè ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹrú, agboolé kan tí ó jẹ́ kòlà-kòṣagbe pàápàá lè ní méjì tàbí mẹ́ta. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ John Barclay sọ pé: “Onírúurú iṣẹ́ ni àwọn ẹrú ilé ń ṣe. A rí àwọn ẹrú tí wọ́n jẹ́ aṣọ́gbà, alásè, agbóúnjẹfúnni, afọṣọ, abánijíṣẹ́, naní, alágbàtọ́, àti ọmọ ọ̀dọ̀, kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan onírúurú iṣẹ́ tí ó lè wà ní agboolé tí ó tóbi àti ti àwọn ọlọ́rọ̀. . . . Ní ti gidi, irú ìgbésí ayé tí ẹrú ilé kan yóò gbé sinmi púpọ̀ lórí ìwà ọ̀gá rẹ̀, tí ó lè pín sí ọ̀nà méjì: níní ọ̀gá òǹrorò lè yọrí sí jíjìyà lílékenkà, ṣùgbọ́n ọ̀gá onínúure àti ọ̀làwọ́ lè mú ìgbésí ayé rọrùn, kí ó sì kún fún ìrètí. A kọ ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ lílókìkí ti ọ̀nà rírorò tí àwọn ọ̀gá ẹrú ń gbà bá àwọn ẹrú wọn lò sínú ìwé ìtàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ jẹ́rìí sí ìfẹ́ tí ó wà láàárín àwọn olówó ẹrú kan àti àwọn ẹrú wọn.”

*Nípa ipò ẹrú láàárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́, wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde, Ìdìpọ̀ Kejì, ojú ìwé 977 sí 979.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́