Ìgárá Arúfin Ni Mí Tẹ́lẹ̀
MAY 1, 1947 ni, ní Sicily. Nǹkan bí 3,000 ènìyàn, tí ó ní àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ nínú, kóra jọ pọ̀ sí ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ àárín àwọn òkè ńláńlá kan fún ayẹyẹ Ọjọ́ Àwọn Òṣìṣẹ́ ọlọ́dọọdún. Wọn kò fura pé ewu kankan fara sin sínú àwọn òkè tí ń bẹ nítòsí. Bóyá o ti kà nípa ọ̀ràn ìbànújẹ́ tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà, tàbí kí o ti wo sinimá rẹ̀. Ìpakúpa náà ni a ń pè ní Ìpànìyan Portella della Ginestra, nínú èyí tí ènìyàn 11 kú, tí àwọn 56 sì fara pa yánnayànna.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò kópa nínú ọ̀ràn ìbànújẹ́ yẹn, mo wà nínú ẹgbẹ́ ajàjàgbara tí ó ṣe é. Salvatore Giuliano, tí èmi pẹ̀lú rẹ̀ jọ dàgbà ní abúlé Montelepre, ni aṣáájú wọn. Ọdún kan péré ló fi jù mí lọ. Ní 1942, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 19, a fipá mú mi wọ iṣẹ́ ológun, nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ṣáájú lọ́dún yẹn, mo gbé Vita Motisi tí ìfẹ rẹ̀ ràdọ̀ bò mí níyàwó. Níkẹyìn, a bí ọmọkùnrin mẹ́ta; a bí àkọ́bí ní 1943.
Ìdí Tí Mo Fi Di Ìgárá Arúfin
Ní 1945, ọdún tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, mo dara pọ̀ mọ́ Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni fún Òmìnira Sicily (EVIS), ẹ̀ka ti ìhà ìwọ̀ oòrùn. Èyí ni ẹ̀ka ológun nínú ẹgbẹ́ òṣèlú ajàjàgbara tí a mọ̀ sí Àjọ Ìlépa Òmìnira Sicily (MIS). Àwọn lọ́gàálọ́gàá ẹgbẹ́ EVIS àti àjọ MIS ti yan Salvatore Giuliano, tí ó ti di alárìnkiri nígbà náà, láti máa bójú tó ẹ̀ka tiwa.
A jọ wà ní ìṣọ̀kan nípasẹ̀ ìfẹ́ wa fún erékùṣù Sicily àti àwọn ènìyan wa. Àìsí ìdájọ́ òdodo tí a ń fojú winá rẹ̀ sì ń mú wa bínú. Nítorí náà, mo fara mọ́ ìlépa àwùjọ Giuliano, tí ń fẹ́ láti sọ Sicily di apá kan United States of America gẹ́gẹ́ bí ìpínlẹ̀ rẹ̀ kọkàndínláàádọ́ta. A ha nídìí láti gbà gbọ́ pé èyí ṣeé ṣe bí? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ ni, nítorí pé àwọn aláṣẹ àjọ MIS ti fi dá wa lójú pé wọ́n ní àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ìjọba United States ní Washington, D.C., àti pé ààrẹ United States, Harry S. Truman, dunnú sí irú ìsopọ̀ bẹ́ẹ̀.
Ìgbòkègbodò Ìgárá Arúfin
Lájorí iṣẹ́ àwùjọ tèmi ni láti máa jí àwọn olókìkí gbé, kí a sì máa gba owó ìràpadà wọn. Ní ọ̀nà yìí ni a fi ń rí owó ra àwọn ohun tí a bá nílò. Kò sí èyí tí a pa lára nínú àwọn tí a jí gbé, tí a máa ń pè ní “àwọn àlejò wa.” Nígbà tí a bá ń dá wọn sílẹ̀, a ń fún wọn ní ìwé ẹ̀rí tí wọn yóò lò fún ìsanpadà owó ìràpadà tí a gbà náà. A ń sọ fún wọn pé wọ́n lè gba owó náà padà lẹ́yìn tí a bá ti borí.
Mo kópa nínú nǹkan bí 20 ìjínigbé, àti nínú ìkọlù oníhàámọ́ra ní àwọn bárékè àwọn Carabinieri, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá àpapọ̀ tí a sọ di ológun. Bí ó ti wù kí ó rí, mo láyọ̀ láti sọ pé n kò pa ẹnikẹ́ni. Àwọn ìkọlù ìjàjàgbara wa ni ó yọrí sí ìwà òmùgọ̀ yẹn ní abúlé Portella della Ginestra. Nǹkan bí ọmọ ogun 12 lára àwùjọ Giuliano ló ṣètò fún un, wọ́n sì darí rẹ̀ sí Ẹgbẹ́ Òṣèlú Kọ́múníìsì.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, pípa àwọn aráàlú lásán—tí ó ní àwọn aládùúgbò àti alátìlẹ́yìn nínú—kì í ṣe ohun àmọ̀ọ́mọ̀ṣe, àwọn ènìyàn tí wọ́n ti ń tì wá lẹ́yìn, tí wọ́n sì kà á sí pé a ń dáàbò bo àwọ́n wá gbà gbọ́ pé a ti da àwọn. Láti ìgbà náà lọ, wọ́n ń dọdẹ ẹgbẹ́ ìgárá arúfin ti Giuliano, láìdẹwọ́. Lẹ́yìn ìsọfúnni tí ó tó àwọn ọlọ́pàá létí, ọwọ́ tẹ ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹlẹgbẹ́ mi. Èmi náà lùgbàdì ní March 19, 1950, wọ́n sì fòfin mú mi. Wọ́n sì pa Giuliano alára ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn.
Ìfisẹ́wọ̀n àti Ìdálẹ́jọ́
Ní ọgbà ẹ̀wọ̀n kan ní Palermo, níbi tí a fi mí pa mọ́ sí de ìgbẹ́jọ́, mo kẹ́dùn pé a yà mí nípa kúrò lọ́dọ̀ aya mi àti àwọn ọmọkùnrin mi mẹ́ta. Síbẹ̀, ìfẹ́ ọkàn mi láti jà fún ohun tí mo gbà pé ó tọ́ dáàbò bò mí lọ́wọ́ àìnírètí pátápátá. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kàwé kí ọwọ́ mi má baà dilẹ̀. Ìwé kan ta ìfẹ́ ọkàn mi láti ka Bíbélì jí. Ó jẹ́ ìtàn ìgbésí ayé ara ẹni Silvio Pellico, ará Ítálì kan, tí ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí ọ̀ràn ìṣèlú ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún.
Pellico kọ̀wé pé nínú ẹ̀wọ̀n, òún máa ń ní ìwé atúmọ̀ èdè kan àti Bíbélì kan pẹ̀lú òun nígbà gbogbo. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onísìn Roman Kátólíìkì ni èmi àti ìdílé mi, ní gidi, n kò tí ì gbọ́ ohunkóhun nípa Bíbélì rí. Nítorí náà, mo bẹ àwọn aláṣẹ láti fún mi ní ẹ̀dà kan. Wọ́n sọ fún mi pé òfin kò fàyè gbà á, ṣùgbọ́n wọ́n fún mi ní ẹ̀dà kan àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere ti Mátíù, Máàkù, Lúùkù, àti Jòhánù. Nígbà díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo rí ẹ̀dà odindi Bíbélì kan gbà, tí mo ṣì ń tọ́jú bí ìṣúra ìrántí mánigbàgbé.
Níkẹyìn, ní 1951, ìgbẹ́jọ́ mi bẹ̀rẹ̀ ní Viterbo, nítòsí Róòmù. Ó gba oṣù 13. A dájọ́ ẹ̀wọn gbére méjì àti ẹ̀wọ̀n ọdún 302 fún mi! Ìyẹ́n túmọ̀ sí pé ẹwọ̀n ni n óò kú sí.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Bíbélì
Nígbà tí a dá mi padà si ẹ̀wọ̀n ní Palermo, a fi mí sí apá ibi tí mẹ́ḿbà àwùjọ wa kan tí ó jẹ́ ìbátan Giuliano, ti ń ṣẹ̀wọ̀n. Wọ́n ti fòfin mú un lọ́dún mẹ́ta ṣáájú tèmi. Ṣáájú, ó ti bá ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti Switzerland pàdé lẹ́wọ̀n, ìyẹ́n sì ti bá a sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlérí àgbàyanu tí ń bẹ nínú Bíbélì. Wọ́n ti mú ọkùnrin náà pẹ̀lú Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan láti Palermo nígbà tí wọ́n ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) A sọ fún mi lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé àwọn mẹ́ḿbà àwùjọ àlùfáà ló súnná sí fífi àṣẹ ọba mú un.
Láìka àwọn ìgbòkègbodò àìbófinmu mi sí, mo gba Ọlọ́run àti àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì gbọ́. Nítorí náà, mo gbọ̀nrìrì láti gbọ́ pé ìbuyì fún àwọn tí a fẹnu lásán pè ní ẹni mímọ́ kò bá Ìwé Mímọ́ mu, àti pé ọ̀kan lára àwọn Òfin Mẹ́wàá ka ìlò ère nínú ìjọsìn léèwọ̀. (Ẹ́kísódù 20:3, 4) Mo san àsansílẹ̀ owó fún àwọn ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!, tí ó wá di ohun iyebíye fún mi. N kò lóye gbogbo ohun tí mo ń kà, ṣùgbọ́n bí mo ti ń kà sí i tó ni mo ń fẹ́ láti sá là, kì í ṣe kúrò lẹ́wọ̀n, ṣùgbọ́n kúrò nínú àhámọ́ ìsìn èké àti ìfọ́jú nípa tẹ̀mí.
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, mo wá mọ̀ pé, láti wu Ọlọ́run, mo ní láti bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà mi sílẹ̀, kí n sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀—èyí tí ó ní inú tútù, tí ó sì jọra pẹ̀lú ti Kristi Jésù. (Éfésù 4:20-24) Ìyípadà mi jẹ́ díẹ̀díẹ̀. Síbẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ojú ẹsẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe nǹkan fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ mi, tí mo sì ń sapá láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun kíkọ yọyọ tí mo ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, sáà aláyọ̀ kan bẹ̀rẹ̀ fún mi ní 1953. Ṣùgbọ́n kò ṣàìsí àwọn ohun ìdènà.
Àtakò Láti Ọ̀dọ̀ Àlùfáà
Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tí mo san àsansílẹ̀ owó fún Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!, ìdíwọ́ kan ṣẹlẹ̀ láti mú kí wọ́n má ṣe tẹ̀ mí lọ́wọ́. Mo lọ bá olùṣàyẹ̀wò àwọn lẹ́tà àwọn ẹlẹ́wọ̀n, mo sì pe ọ̀rọ̀ náà sí àfiyèsí rẹ̀. Ó sọ fún mi pé àlùfáà ọgbà ẹ̀wọ̀n ló dá ìpínfúnni náà dúró.
Mo béèrè àyè láti rí àlùfáà náà. Nígbà ìjíròrò wa, mo fi ìwọ̀nba ohun tí mo mọ̀ láti inú Bíbélì hàn án, títí kan àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ bí Ẹ́kísódù 20:3, 4 àti Aísáyà 44:14-17 nípa ìlò ère nínú ìjọsìn. Mo ka àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ Jésù fún un nínú Mátíù 23:8, 9, pé kí a má ṣe ‘pe ẹnikẹ́ni ní baba wa lórí ilẹ̀ ayé.’ Bí inú ti bí i, ó fèsì pé n kò lè lóye Bíbélì nítorí pé mo jẹ́ aláìmọ̀kan.
Àǹfààní gidi ni ó jẹ́ pé mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í yí ànímọ́ ìwà mi padà—bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n kò mọ ohun tí ǹ bá ti ṣe. Pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn, mo dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, òtítọ́ ni; aláìmọ̀kan ni mí. Ṣùgbọ́n ìwọ́ ti kẹ́kọ̀ọ́, o kò sì tí ì ṣe ohun kankan láti kọ́ni ní òtítọ́ Bíbélì.” Àlùfáà náà fèsì pé bí n óò bá máa gba ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo ní láti kọ̀wé ẹ̀bẹ̀ kan sí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ pé n kì í ṣe Kátólíìkì mọ́. Mo ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́wọ́ gba ẹ̀bẹ̀ náà. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo lè fi orúkọ mi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì lè máa gba àwọn ìwé ìròyìn náà lẹ́ẹ̀kan sí i. Ṣùgbọ́n mo ní láti rin kinkin gan-an.
Gbọ̀ngàn Ìjọba Kan Nínú Ọgbà Ẹ̀wọ̀n
Mo ti fìgbà kan béèrè pé kí olùdarí ọgbà ẹ̀wọ̀n fún mi ní iṣẹ́ kan tí mo lè máa ṣe, kí n lè máa rí owó fi ránṣẹ́ sí ìdílé mi. Ó sábà máa ń sọ pé, bí òún bá fún mi níṣẹ́ kan, ó di dandan kí òún fún àwọn yòókù pẹ̀lú, ìyẹn kò sì lè ṣeé ṣe. Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ August 5, 1955, olùdarí náà fún mi ní ìròyìn rere kan—mo ní láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ akọ̀wé nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà.
Iṣẹ́ mi jẹ́ kí n jèrè ọ̀wọ̀ olùdarí ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, ó sì finú rere yọ̀ǹda fún mi láti máa lo iyàrá ìkẹ́rùsí kan fún ìpàdé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nípa bẹ́ẹ̀, ní 1956, mo fi àwọn pákó ohun èlò ìkówèépamọ́ tí a kò lò mọ́ ṣe bẹ́ǹṣì ìjókòó fún ohun tí a lè kà sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe ibi ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èmi àti àwọn ẹlẹ́wọ̀n míràn ń pàdé níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ Sunday, a sì pọ̀ dé orí góńgó ènìyàn 25 tí ń wá fún ìjíròrò Bíbélì.
Bí àkókò ti ń lọ, àlùfáà náà mọ̀ nípa àwọn ìpàdé tí mo ń ṣe, ó sì bínú. Àbájáde rẹ̀ ni pé, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn 1957, a gbé mi kúrò ní Palermo lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ńlá ti Porto Azzurro ní erékùṣù kékeré ti Elba. Ibí yìí ní òkìkí burúkú.
Mo Ṣe Batisí Lẹ́wọ̀n
Nígbà tí mo débẹ̀, a fi mí sí àhámọ́ àdáwà fún ọjọ́ 18. A kò tilẹ̀ gbà mí láyè láti mú Bíbélì mi sọ́dọ̀. Lẹ́yìn náà, mo tún kọ̀wé ẹ̀bẹ̀ sí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ láti gbà mí láyè, láti fi ìsìn Kátólíìkì sílẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, lọ́tẹ̀ yìí, mo béèrè fún ìrànlọ́wọ́ ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Róòmù. Lẹ́yìn oṣù mẹ́wàá, èsì tí a ti ń dúró dè tipẹ́ náà dé. Ilé Iṣẹ́ ìjọba náà gba ìyísìnpadà mi! Èyí kò túmọ̀ sí pé mo lè ní Bíbélì kan, àwọn ìwé ìròyìn, àti àwọn ìwé àlàyé Bíbélì míràn nìkan, ṣùgbọ́n ó tún túmọ̀ sí pé òjíṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan lè máa bẹ̀ mí wò déédéé.
Ayọ̀ mi kò láàlà nígbà tí Giuseppe Romano, tí ó wá láti ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ítálì nígbà náà, kọ́kọ́ bẹ̀ mí wò. Pẹ̀lú ìyọ̀ǹda àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n, a ṣètò fún mi láti fẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi sí Jèhófà hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi níkẹyìn. Ní October 4, 1958, níṣojú olùdarí ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, alábòójútó ìbáwí, àti àwọn aláṣẹ mìíràn, Arákùnrin Romano batisí èmi àti ẹlẹ́wọ̀n mìíràn kan nínú agbada ìwẹ̀ ńlá tí a ń fi omi rẹ̀ fọ́n ọgbà ẹ̀wọ̀n náà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo fẹ́rẹ̀ẹ́ lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n míràn nígbà gbogbo, mo ní láti dá ṣe Ìṣe Ìrántí ọdọọdún ikú Kristi nínú iyàrá ẹ̀wọ̀n mi, nítorí ayẹyẹ náà wáyé lẹ́yìn tí oòrùn ti wọ̀. N óò di ojú mi, n óò sì gbàdúrà, ní fífi ojú inú wo ara mi pé mo pé jọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ mi.
Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Lẹ́wọ̀n
Ní 1968, a gbé mi lọ sí ẹ̀wọ̀n ní Fossombrone, ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Pesaro. Mo gbádùn àwọn àbájáde rere láti inú bíbá àwọn mìíràn sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ Bíbélì níbẹ̀. Mo ń ṣiṣẹ́ níbi ìtọ́jú ìlera, níbi tí ó ti ṣeé ṣe láti rí àǹfààní ìjẹ́rìí. Ó jẹ́ ohun ayọ̀ ní pàtàkì láti rí ìtẹ̀síwájú ẹlẹ́wọ̀n kan, Emanuele Altavilla. Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ oṣù méjì, ó rí i pé òún ní láti fi ìmọ̀ràn Ìṣe 19:19 sílò, ó sì dáná sun ìwé iṣẹ́ idán pípa rẹ̀. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Emanuele di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, a gbé mi lọ sí ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní erékùṣù Procida, gẹ́rẹ́ lódì kejì ìyawọlẹ̀ omi òkun láti Naples. Nítorí ìwà rere, a tún fún mi níṣẹ́ ní ibi ìtọ́jú ìlera. Níbẹ̀ ni mo ti pàdé Mario Moreno, ẹlẹ́wọ̀n kan tí ó jẹ́ ògbóǹkangí Kátólíìkì. Òun pẹ̀lú ní ipò ẹrù iṣẹ́ kan, ó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìṣirò owó.
Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, Mario bèèrè pé kí n fún òun ní ohun kan láti kà, mo sì fún un ní ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye.a Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ó ti mọ ìjẹ́pàtàkì ohun tí ó ń kà, a sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mario ṣíwọ́ páálí sìgá mẹ́ta tí ń mu lóòjọ́. Láfikún, ó mọ̀ pé òún gbọ́dọ̀ máa hùwà àìlábòsí, àní nínú iṣẹ́ ìṣirò owó tí ó ń ṣe lẹ́wọ̀n. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fún obìnrin àfẹ́sọ́nà rẹ̀, ìyẹn pẹ̀lú sì tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Bíbélì. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, wọ́n ṣègbeyàwó lẹ́wọ̀n níbẹ̀. Ní àpéjọpọ̀ kan ní Naples, ní 1975, ìyàwo Mario ṣe batisí. Inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tí ó gbọ́ pé ọkọ òún ti ṣe batisí lẹ́wọ̀n lọ́jọ́ kan náà!
A gbà mí láyè láti ní ìjíròrò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń bẹ̀ mí wò ní Procida. A tún gbà mí láyè láti gbọ́únjẹ tí a óò jọ jẹ pẹ̀lú wọn ní gbọ̀ngàn ìgbàlejò. Iye tí ó pọ̀ tó mẹ́wàá lè wà níbẹ̀ lẹ́ẹ̀kan. Nígbà tí àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ṣèbẹ̀wò, mo máa ń gba àṣẹ láti fi ọ̀rọ̀ onísinimá wọn hàn. Lẹ́ẹ̀kan, mo ní àǹfààní láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí 14 ṣèbẹ̀wò. Ó jọ pé àwọn aláṣẹ fọkàn tán mi pátápátá. Ní àwọn ọjọ́ tí wọ́n yàn fún mi, nírọ̀lẹ́, mo máa ń lọ wàásù láti iyàrá ẹ̀wọ̀n dé iyàrá ẹ̀wọ̀n.
Ní 1974, lẹ́yìn tí mo ti lo ọdún 24 ní onírúurú ọgbà ẹ̀wọ̀n, mo gba ìbẹ̀wò adájọ́ kan tí ó fún mi níṣìírí láti kọ̀wé ẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì. N kò ka ṣíṣe bẹ́ẹ̀ sí ohun yíyẹ nítorí yóò ti túmọ̀ sí gbígbà pé mo lọ́wọ́ sí ìpànìyàn Portella della Ginestra, bẹ́ẹ̀ n kò kópa nínú rẹ̀.
Àwọn Àkókò Ayọ̀ Kíkàmàmà
Ní 1975, òfin tuntun kan yọ̀ǹda fún fífàyè gba ẹlẹ́wọ̀n láti jáde fún àkókò díẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, mo ní àǹfààní láti lọ sí àpéjọpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ìgbà àkọ́kọ́, ní ìlú Naples. Mo jẹ̀gbádùn àwọn ọjọ́ mánigbàgbé márùn-ún, nínú èyí tí mo bá àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin púpọ̀ ju èyí tí mo tí ì rí rí lọ pàdé.
Ohun tí ó fún mi láyọ̀ lákànṣe ni pé, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, mo tún wà pọ̀ pẹ̀lú ìdílé mi. Ìyàwó mi, Vita, ti dúró ṣinṣin tì mí, àwọn ọmọkùnrin mi sì ti di ọ̀dọ́kùnrin tí ó wà ní ọjọ́ orí tí ó lé ní 20 àti 30 ọdún.
Ní ọdún tí o tẹ̀ lé e—nínú èyí tí mo gbádùn àkókò ìjáde kúrò lẹ́wọ̀n lọ́pọ̀ ìgbà—a dábàá pé kí n kọ̀wé béèrè ìtúsílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n. Nínú ìròyìn tí òṣìṣẹ́ tí ń kíyè sí ìhùwà mi láàárín àkókò ìyọ̀ǹda àyẹ̀wò kọ, ó dámọ̀ràn pé kí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìwé ìbéèrè mi. Ó kọ̀wé pé: “Dájúdájú, láìbẹ̀rù bóyá ohun kankan lè tẹ̀yìn rẹ̀ jẹ yọ, a lè sọ pé—lónìí, Mannino jẹ́ irú ènìyàn míràn, ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èwe tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ tí ń mú àṣẹ Giuliano ṣẹ; ó ti yí padà pátápátá láìkù síbì kan.”
Láìpẹ́, àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n Procida tọrọ ìdáríjì fún mi. Níkẹyìn, wọ́n dárí jì mí, wọ́n sì dá mi sílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n ní December 28, 1978. Ẹ wo bí ìdùnnú náà ti pọ̀ tó, láti di òmìnira, lẹ́yìn àhámọ́ ọlọ́dún 28!
Ìrètí Kan Ṣoṣo fún Ìdájọ́ Òdodo
Gẹ́gẹ́ bí ajínigbé lábẹ́ ìdarí Salvatore Giuliano, mo ti jà fún ohun tí mo gbà gbọ́ pé yóò mú òmìnira tòótọ́ wá fún ìdílé mi àti àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mi. Síbẹ̀, mo wá kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Bíbélì pé, láìka irú òtítọ́ inú yòówù kí ènìyàn ní sí, wọn ko lè mú ìdájọ́ òdodo tí mo nífẹ̀ẹ́ ọkàn sí gan-an gẹ́gẹ́ bí èwe wá láé. Mo ṣọpẹ́ pé ìmọ̀ Bíbélì ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé, Ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi, nìkan ni ó lè mú ìtura tí a nílò lójú méjèèjì náà wá kúrò lọ́wọ́ àìṣèdájọ́ òdodo.—Aísáyà 9:6, 7; Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10; Ìṣípayá 21:3, 4.
Ọ̀pọ̀ ìwé agbéròyìnjáde ṣàkọsílẹ̀ ìyípadà nínú àkópọ̀ ìwà mi, tí irú ìmọ̀ Bíbélì bẹ́ẹ̀ ṣokùnfà rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ìwé agbéròyìnjáde Paese Sera fa ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣọ́ ẹ̀wọ̀n Procida yọ pé: “Bí gbogbo ẹlẹ́wọ̀n bá rí bíi Franck ni, kì yóò sí ọgbà ẹ̀wọ̀n mọ́; ìhùwàsí rẹ̀ kò lẹ́gàn, kò fàjàngbọ̀n rí, a kò sì fún un ní ìbáwí tí ó kéré jù lọ pàápàá wò.” Ìwé agbéròyìnjáde mìíràn, Avvenire, sọ pé: “Ẹlẹ́wọ̀n àwòfiṣàpẹẹrẹ ni, irú rẹ̀ kò wọ́pọ̀. Ìmúbáwùjọmu rẹ̀ ré kọjá ohun tí a fojú sọ́nà fún. Ó ní ọ̀wọ̀ fún ìṣètò ọgbà ẹ̀wọ̀n àti àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n, ó sì ní àrà ọ̀tọ̀ ipò jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí.”
Ìgbésí Ayé Ṣíṣàǹfààní
Láti 1984, mo ti ń sìn bí alàgbà àti aṣáájú ọ̀nà, bí a ṣe ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, nínú ọ̀kan lára ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní 1990, ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tí mo ti bá ṣàjọpín ìmọ̀ Bíbélì ní ọdún 15 ṣáájú tẹ̀ mí láago láti sọ fún mi pé òun àti gbogbo ìdílé òún ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ìrírí mi tí ó mú mi láyọ̀ jù lọ ṣẹlẹ̀ ní July 1995. Lọ́dún yẹn, mo ní ìdùnnú ńlá ti wíwà níbi batisí aya mi olùfẹ́, Vita. Lẹ́yìn ọdún púpọ̀ bẹ́ẹ̀, ó ti sọ ẹ̀kọ́ Bíbélì di tirẹ̀. Bóyá àwọn ọmọkùnrin mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, tí kò ì ṣàjọpín ìgbàgbọ́ mi báyìí pẹ̀lú, yóò tẹ́wọ́ gba ohun tí mo ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́jọ́ kan.
Àwọn ìrírí mi ní ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì ti fún mi ní ìmọ̀lára ìtẹ́lọ́rùn aláìláfiwé. Ẹ wo bí ó ti ṣàǹfààní tó láti ní ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun, kí a sì lè ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn olóòótọ́ ọkàn!—Jòhánù 17:3.—Gẹ́gẹ́ bí Franck Mannino ṣe sọ ọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ àárín àwọn òkè ńláńlá níbi tí ìpànìyàn náà ti ṣẹlẹ̀ ní Sicily
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Nígbà tí a ṣègbéyàwó, ní 1942
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Mo sábà máa ń ṣàjọpín òtítọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Pẹ̀lú ìyàwó mi