ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Fílémónì
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Fílémónì

    • Ìkíni (1-3)

    • Ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ Fílémónì (4-7)

    • Pọ́ọ̀lù bá Ónísímù bẹ̀bẹ̀ (8-22)

    • Ìkíni tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ (23-25)

Fílémónì 1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 4:1
  • +Iṣe 16:1, 2; Heb 13:23

Fílémónì 2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Kol 4:17
  • +Ro 16:5; 1Kọ 16:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2008, ojú ìwé 31

Fílémónì 4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 1:15, 16; 1Tẹ 1:2

Fílémónì 7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “o ti mú kí ara tu ọkàn àwọn ẹni mímọ́.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    4/15/1992, ojú ìwé 25

Fílémónì 9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/1999, ojú ìwé 29

    4/15/1992, ojú ìwé 23-25

Fílémónì 10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “wà nínú ìdè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Kol 4:9
  • +1Kọ 4:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/1998, ojú ìwé 30

Fílémónì 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2008, ojú ìwé 31

    1/15/1998, ojú ìwé 30

Fílémónì 12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹni tí mo fẹ́ràn gan-an.”

Fílémónì 13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 6:19, 20; Flp 1:7

Fílémónì 14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 9:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    10/1/1994, ojú ìwé 20

Fílémónì 15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “wákàtí kan.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2008, ojú ìwé 31

    2/15/1991, ojú ìwé 23

Fílémónì 16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 7:22
  • +1Ti 6:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2008, ojú ìwé 31

    2/15/1991, ojú ìwé 23

Fílémónì 17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “alájọpín.”

Fílémónì 18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/1998, ojú ìwé 29-30

    4/15/1992, ojú ìwé 23

Fílémónì 20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tu ọkàn mi.”

Fílémónì 21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2008, ojú ìwé 31

    1/15/1998, ojú ìwé 31

Fílémónì 22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tú mi sílẹ̀ fún yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Flp 2:24

Fílémónì 23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Kol 1:7; 4:12, 13

Fílémónì 24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 19:29; 27:2; Kol 4:10
  • +2Ti 4:10
  • +Kol 4:14

Fílémónì 25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2012, ojú ìwé 12-13

Àwọn míì

Fílém. 1Ef 4:1
Fílém. 1Iṣe 16:1, 2; Heb 13:23
Fílém. 2Kol 4:17
Fílém. 2Ro 16:5; 1Kọ 16:19
Fílém. 4Ef 1:15, 16; 1Tẹ 1:2
Fílém. 10Kol 4:9
Fílém. 101Kọ 4:15
Fílém. 13Ef 6:19, 20; Flp 1:7
Fílém. 142Kọ 9:7
Fílém. 161Ti 6:2
Fílém. 161Kọ 7:22
Fílém. 22Flp 2:24
Fílém. 23Kol 1:7; 4:12, 13
Fílém. 24Iṣe 19:29; 27:2; Kol 4:10
Fílém. 242Ti 4:10
Fílém. 24Kol 4:14
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Fílémónì 1-25

Sí Fílémónì

1 Pọ́ọ̀lù, tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n+ nítorí Kristi Jésù, àti Tímótì+ arákùnrin wa, sí Fílémónì, ẹni ọ̀wọ́n tí a jọ ń ṣiṣẹ́, 2 àti sí Áfíà arábìnrin wa àti Ákípọ́sì+ tí a jọ jẹ́ ọmọ ogun àti sí ìjọ tó wà ní ilé rẹ:+

3 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà Ọlọ́run tó jẹ́ Baba wa àti ti Jésù Kristi Olúwa máa wà pẹ̀lú rẹ.

4 Mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi nígbà gbogbo tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi,+ 5 bí mo ṣe ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ àti ìfẹ́ tí o ní sí Jésù Olúwa àti sí gbogbo ẹni mímọ́. 6 Àdúrà mi ni pé kí ìgbàgbọ́ jẹ́ kí o mọ gbogbo ohun rere tí Kristi mú kí a ní. 7 Arákùnrin mi, nígbà tí mo gbọ́ nípa ìfẹ́ rẹ, inú mi dùn gan-an, ara sì tù mí torí pé o ti mú kí ara tu àwọn ẹni mímọ́.*

8 Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnu mi gbà á láti pàṣẹ fún ọ pé kí o ṣe ohun tó tọ́ torí bí mo ṣe jẹ́ sí Kristi, 9 mi ò ní ṣe bẹ́ẹ̀, màá rọ̀ ẹ́ torí ìfẹ́ tí o ní àti bí o ṣe mọ̀ pé àgbàlagbà ni mí tí mo sì tún wà lẹ́wọ̀n báyìí torí Kristi Jésù. 10 Mò ń bẹ̀ ọ́ nítorí Ónísímù+ ọmọ mi, tí mo di bàbá rẹ̀+ nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n.* 11 Kò wúlò fún ọ tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí, ó ti wúlò fún èmi àti ìwọ. 12 Ó ti di ẹni bí ọkàn mi,* mo sì ń rán an pa dà sọ́dọ̀ rẹ.

13 Nítorí ìwọ ò sí níbí, ó wù mí kó ṣì wà lọ́dọ̀ mi, kó lè máa ràn mí lọ́wọ́ lákòókò yìí tí mo wà lẹ́wọ̀n nítorí ìhìn rere.+ 14 Àmọ́ mi ò fẹ́ ṣe ohunkóhun láìjẹ́ pé o fọwọ́ sí i, kí ohun rere tí o fẹ́ ṣe lè ti ọkàn rẹ wá, kó má sì jẹ́ àfipáṣe.+ 15 Ó lè jẹ́ torí èyí ló fi sá kúrò fún ìgbà díẹ̀,* kó lè pa dà sọ́dọ̀ rẹ títí láé, 16 kì í ṣe bí ẹrú mọ́,+ àmọ́ bí ẹni tó ju ẹrú lọ, bí arákùnrin ọ̀wọ́n.+ Bó ṣe jẹ́ sí mi gan-an nìyẹn, kí n má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ bó ṣe jẹ́ sí ọ nípa tara àti nínú Olúwa. 17 Torí náà, tí o bá kà mí sí ọ̀rẹ́* rẹ, fi ìfẹ́ gbà á tọwọ́tẹsẹ̀ bí o ṣe máa gbà mí. 18 Yàtọ̀ síyẹn, tó bá ti ṣẹ̀ ọ́ lọ́nàkọnà tàbí tó jẹ ọ́ ní gbèsè ohunkóhun, kà á sí mi lọ́rùn. 19 Èmi Pọ́ọ̀lù ni mò ń fi ọwọ́ ara mi kọ̀wé yìí: Màá san án pa dà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ náà jẹ mí ní gbèsè ara rẹ. 20 Arákùnrin mi, mo fẹ́ kí o ṣe nǹkan yìí fún mi torí bí a ṣe jẹ́ nínú Olúwa. Jọ̀ọ́, jẹ́ kí ara tù mí* torí bí a ṣe jẹ́ sí Kristi.

21 Mò ń kọ̀wé sí ọ torí ó dá mi lójú pé o máa ṣe ohun tí mo sọ. Mo sì mọ̀ pé wàá ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. 22 Bákan náà, mo tún fẹ́ kí o bá mi ṣètò ibi tí màá dé sí, torí mo ní ìrètí pé wọ́n á jẹ́ kí n pa dà sọ́dọ̀ yín,* lọ́lá àdúrà tí ẹ̀ ń gbà fún mi.+

23 Épáfírásì+ tí a jọ wà lẹ́wọ̀n torí Kristi Jésù ń kí ọ, 24 Máàkù, Àrísítákọ́sì,+ Démà+ àti Lúùkù+ tí gbogbo wa jọ ń ṣiṣẹ́ tún kí ọ.

25 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa máa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí o fi hàn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́