Bíbọ́ Lọ́wọ́ Ìwà Ọ̀daràn Tí Ẹgbẹ́ Ń Ṣètò “Yakuza Kan Ni Mí Tẹ́lẹ̀”
“BÀBÁ, nígbà tí ẹ bá pa dà délé, ẹ jẹ́ kí á jọ máa lọ sí àwọn ìpàdé. Ẹ ṣèlérí fún mi, àbí ẹ kò ní ṣe bẹ́ẹ̀?” Mo gba lẹ́tà yí láti ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin mi kejì nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n fún ìgbà kẹta. Òun àti ìyàwó mi ń lọ sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà déédéé. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn lẹ́tà tí ìdílé mi ń kọ sí mi nìkan ni orísun ìtùnú tí mo ní, mo ṣèlérí fún un pé n óò ṣe ohun tí ó wí.
Mo rò nínú ara mi pé, ‘Èé ṣe tí mo fi ń gbé ìgbésí ayé ọ̀daràn tí ń mú kí n fi ìdílé mi sílẹ̀?’ Mo rántí ìgbà tí mo ṣì kéré gan-an. Bàbá mi kú nígbà tí mo jẹ́ ọmọ oṣù 18 péré, nítorí náà, n kò tilẹ̀ rántí bí ojú rẹ̀ ṣe rí gan-an. Lẹ́yìn ìyẹn, Màmá tún lọ́kọ nígbà méjì. Irú ipò ìdílé bẹ́ẹ̀ nípa lórí mi gidigidi, nígbà tí mo sì wà nílé ẹ̀kọ́ gíga, mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọ̀dọ́ oníwà ọ̀daràn kẹ́gbẹ́. Mo di oníjàgídíjàgan, mo sì sábà máa ń jà lẹ́yìn òde ilé ẹ̀kọ́. Nígbà tí mo wà ní ọdún kejì nílé ẹ̀kọ́ gíga, mo kó àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan jọ láti bá àwùjọ mìíràn jà. Nítorí èyí, wọ́n fòfin mú mi, wọ́n sì sọ mí sí ibùdó ìtúnwàṣe kan fúngbà díẹ̀.
Ńṣe ni mo dà bíi bọ́ọ̀lù kan tí ń tòkè yí lọ sílẹ̀ síhà ìgbésí ayé oníwà ipá. Láìpẹ́, mo dá ẹgbẹ́ àwọn olùyapòkíì kan sílẹ̀, a sì ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri nítòsí ọ́fíìsì àwùjọ yakuza kan. Nígbà tí mo di ọmọ ọdún 18, mo di mẹ́ńbà àwùjọ yẹn ní kíkún. Nígbà tí mo di ọmọ 20 ọdún, wọ́n fòfin mú mi fún onírúurú ìwà ipá, wọ́n sì sọ mí sẹ́wọ̀n fún ọdún mẹ́ta. Wọ́n kọ́kọ́ fi mí sí Ẹ̀wọ̀n Àwọn Aláìtójúúbọ́ ní Nara, ṣùgbọ́n ìwà mi kò sunwọ̀n sí i. Nítorí náà, wọ́n mú mi lọ sí ẹ̀wọ̀n míràn, ọ̀kan tí ó wà fún àwọn àgbàlagbà. Ṣùgbọ́n ńṣe ni mo túbọ̀ ń burú sí i, wọ́n sì mú mi lọ sí ẹ̀wọ̀n àwọn ọ̀daràn paraku ní Kyoto níkẹyìn.
Mo bi ara mi pé, ‘Èé ṣe tí mo fi ń dá irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ nìṣó?’ Ní bíbojúwẹ̀yìn, mo rí i pé ó jẹ́ nítorí ìrònú tí kò bọ́gbọ́n mu tí mo ní. Ní àkókò náà, mo rò pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ jẹ́ ti akin, tí ń fi hàn pé mo jẹ́ ọkùnrin. Nígbà tí wọ́n dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní ọmọ ọdún 25, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ọ̀daràn tó kù ń bọ̀wọ̀ fún mi bí ẹni pàtàkì kan. Ní báyìí, ọ̀nà ti ṣí fún mi láti gòkè nínú agbo ẹgbẹ́ ọ̀daràn.
Ìhùwàpadà Ìdílé Mi
Ní nǹkan bí àkókò yẹn ni mo gbéyàwó, kò sì pẹ́ tí èmi àti ìyàwó mi fi bí àwọn ọmọbìnrin méjì. Síbẹ̀, ìgbésí ayé mi kò yí pa dà. Mo ń pààrà ọgbà ọlọ́pàá ṣáá ni—mo ń lu àwọn ènìyàn, mo sì ń lu jìbìtì. Ìṣẹ̀lẹ̀ kọ̀ọ̀kan ń mú kí n jèrè ọ̀wọ̀ àwọn mẹ́ńbà àjọ ìpàǹpá ẹlẹgbẹ́ mi àti ìgbẹ́kẹ̀lé ọ̀gá wa pátápátá. Níkẹyìn, “alayé tó ṣáájú” mi nínú ẹgbẹ́ yakuza dépò àgbà nínú àjọ ìpàǹpá náà, ó sì di ọ̀gá pátápátá. Inú mi dùn pé mo di igbákejì ọ̀gá pátápátá.
Mo ronú pé, ‘Kí ni èrò ìyàwó mi àti àwọn ọmọbìnrin mi nípa ọ̀nà ìgbésí ayé mi?’ Ó gbọ́dọ̀ ti máa kótìjú bá wọn pé ọ̀daràn ni ọkọ tàbí bàbá wọn. Mo tún wẹ̀wọ̀n ní ọmọ 30 ọdún, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí mo di ọmọ ọdún 32. Lọ́tẹ̀ yí, ọdún mẹ́ta lẹ́wọ̀n náà ni mí lára gan-an. Wọn kò gba àwọn ọmọbìnrin mi láyè láti wá bẹ̀ mí wò. Aáyun yun mí láti bá wọn sọ̀rọ̀ àti láti gbá wọn mọ́ra.
Ní nǹkan bí àkókò tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ̀wọ̀n tó kẹ́yìn yí ni ìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ sí í bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Léraléra ni ó ń kọ̀wé sí mi nípa ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí ó ń kọ́. Mo ṣe kàyéfì pé, ‘Òtítọ́ wo ni ìyàwó mi ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yí?’ Mo ka Bíbélì lódindi nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n. Mo ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí ìyàwó mi ń sọ nínú àwọn lẹ́tà rẹ̀ nípa ìrètí kan fún ọjọ́ ọ̀la àti nípa ète Ọlọ́run.
Ìrètí ìwàláàyè ayérayé fún ẹ̀dá ènìyàn nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé wọ̀ mí lọ́kàn, nítorí mo bẹ̀rù ikú. Mo ti sábà máa ń ronú pé, ‘Bí o bá kú, ìwọ lo pàdánù.’ Bí mo ti ń ronú sẹ́yìn, mo rí i pé ìbẹ̀rù ikú ló ń sún mi láti ṣe àwọn ẹlòmíràn léṣe kí wọ́n tó ṣe mí léṣe. Àwọn lẹ́tà tí ìyàwó mi kọ tún mú kí n rí i pé òmúlẹ̀mófo ni ìlépa mi láti gòkè àgbà nínú agbo àjọ ìpàǹpá.
Síbẹ̀, ọkàn mi kò kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ìyàwó mi ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ tí ó ti ṣèrìbọmi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, nínú lẹ́tà mi, mo ti gbà láti lọ sí àwọn ìpàdé wọn, n kò ronú láti di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo rò pé, ńṣe ni ìyàwó mi àti àwọn ọmọbìnrin mi ti lọ jìnnà sí mi, tí wọ́n sì ti já mi sílẹ̀ lẹ́yìn.
Jíjáde Lẹ́wọ̀n
Níkẹyìn, ọjọ́ náà dé tí a óò dá mi sílẹ̀. Ní ẹnu ọ̀nà ọgbà Ẹ̀wọ̀n Nagoya, ọ̀pọ̀ àwọn mẹ́ńbà àjọ ìpàǹpá tò láti kí mi káàbọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, láàárín ògìdìgbó ènìyàn náà, ìyàwó mi àti àwọn ọmọbìnrin mi nìkan ni mo ń fojú wá. Nígbà tí mo rí àwọn ọmọbìnrin mi, tí wọ́n ti dàgbà lọ́nà jíjọnilójú láàárín ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà náà, omijé bọ́ lójú mi.
Ní ọjọ́ méjì lẹ́yìn tí mo pa dà sílé, mo mú ìlérí mi fún ọmọbìnrin mi kejì ṣẹ, mo sì lọ sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó yà mí lẹ́nu láti rí ìhùwàsí ọlọ́yàyà tí gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀ ní. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà kí mi káàbọ̀ tọ̀yàyàtọ̀yàyà, ṣùgbọ́n mo rò pé mo yàtọ̀ láàárín wọn. Nígbà tí mo wá mọ̀ níkẹyìn pé àwọn tí ó ti kí mi wọ̀nyẹn mọ̀ nípa ìwà ọ̀daràn mi àtẹ̀yìnwá, mo ṣe kàyéfì. Bí ó ti wù kí ó rí, mo nímọ̀lára ọ̀yàyà wọn, ọ̀rọ̀ tí a gbé karí Bíbélì tí mo gbọ́ sì fà mí mọ́ra. Ó jẹ́ nípa gbígbé tí àwọn ènìyàn yóò gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé títí láé.
Èrò nípa pé kí ìyàwó mi àti àwọn ọmọbìnrin mi là á já sínú Párádísè, kí èmi sì ṣègbé, dà mí lọ́kàn rú gan-an. Mo ṣàṣàrò jinlẹ̀jinlẹ̀ lórí ohun tí mo ní láti ṣe láti wà láàyè títí láé pẹ̀lú ìdílé mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú jíjàjàbọ́ kúrò nínú ìgbésí ayé mi gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà àjọ ìpàǹpá, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Jíjàjàbọ́ Kúrò Nínú Ìgbésí Ayé Ìwà Ọ̀daràn Mi
N kò lọ sí ìpàdé àjọ ìpàǹpá mọ́, n kò sì bá yakuza kẹ́gbẹ́ mọ́. Kò rọrùn láti yí ọ̀nà ìrònú mi pa dà. Mo ń gun ọkọ̀ tòkunbọ̀ olówó ńlá kiri, kìkì nítorí ìgbádùn rẹ̀—ó jẹ́ ohun kan tí ń fi bí mo ṣe tó hàn. Ó gbà mí lọ́dún mẹ́ta kí n tó lè pààrọ̀ ọkọ̀ mi sí alábọ́ọ́dé kan. Mo tún ní ìtẹ̀sí láti máa wá ọ̀nà tí ó rọrùn jù lọ láti fi yanjú nǹkan. Bí ó ti wù kí ó rí, bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, mo lè rí i pé mo gbọ́dọ̀ yí pa dà. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Jeremáyà 17:9 ṣe sọ, “ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, ó sì burú jáyì.” Mo mọ ohun tí ó tọ́, ṣùgbọ́n ó ṣòro fún mi láti lo àwọn ohun tí mo ń kọ́. Ìṣòro tí mo dojú kọ dà bí òkè ńlá kan. Ìdààmú bá mi, lọ́pọ̀ ìgbà ni mo sì ń ronú láti ṣíwọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́, kí n má sì ronú mọ́ nípa dídi ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Nígbà náà ni olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi ké sí alábòójútó arìnrìn-àjò kan, tí ipò rẹ̀ àtẹ̀yìnwá jọ tèmi, láti wá sọ àwíyé kan nínú ìjọ wa. Láti Akita, 640 kìlómítà, ó wá sí Suzuka, kí ó lè fún mi níṣìírí. Lẹ́yìn ìyẹn, nígbàkigbà ti mo bá fẹ́ káàárẹ̀, tí mo sì ronú ṣíṣíwọ́ ni mo máa ń rí lẹ́tà gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, tí ó ń bi mí bóyá mo ń rìn láìyẹsẹ̀ ní ọ̀nà Olúwa.
Mo ń bá gbígbàdúrà sí Jèhófà lọ láti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè já gbogbo àjọṣe mi pẹ̀lú ẹgbẹ́ yakuza. Mo ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà yóò dáhùn àdúrà mi. Ní April 1987, ó ṣeé ṣe fún mi níkẹyìn láti kúrò nínú ẹgbẹ́ yakuza. Níwọ̀n bí iṣẹ́ òwò mi ti máa ń mú kí n lọ sí òkè òkun lóṣooṣù, tí mo ń fi ìdílé mi sílẹ̀, mo pààrọ̀ iṣẹ́ sí iṣẹ́ ìtúnléṣe. Èyí mú kí n lè máa kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí ní àwọn ọ̀sán. Fún ìgbà kíní, mo gba owó oṣù. Ó kéré, ṣùgbọ́n ó mú kí n láyọ̀ gan-an.
Nígbà tí mo jẹ́ igbákejì ọ̀gá pátápátá ẹgbẹ́ yakuza, mo ní dúkìá púpọ̀, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mo ní ọrọ̀ tẹ̀mí tí kì í ṣá. Mo mọ Jèhófà. Mo mọ àwọn ète rẹ̀. Mo ní àwọn ìlànà láti tẹ̀ lé nínú ìgbésí ayé. Mo ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tí ń bìkítà. Nínú agbo ẹgbẹ́ yakuza, àwọn mẹ́ńbà àjọ ìpàǹpá náà ń bìkítà lóréfèé, ṣùgbọ́n n kò mọ yakuza kankan, kódà, ẹyọ kan, tí ó jẹ́ fi ara rẹ̀ rúbọ nítorí àwọn mìíràn.
Ní August 1988, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi fún Jèhófà hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi, láti oṣù tí ó sì tẹ̀ lé e, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo, ó kéré tán, 60 wákàtí lóṣù, ní sísọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìhìn rere tí ó ti yí ìgbésí ayé mi pa dà. Mo ti ń ṣiṣẹ́ sìn bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún láti March 1989, a sì ti fún mi láǹfààní láti sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ nísinsìnyí.
Ó ṣeé ṣe fún mi láti gba ara mi lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ ìyókù ọ̀nà ìgbésí ayé mi gẹ́gẹ́ bíi yakuza kan. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ku ọ̀kan. Ìyẹn ni ara tí mo fín, tí ń rán èmi àti ìdílé mi àti àwọn ẹlòmíràn létí ìgbésí ayé yakuza tí mo gbé látijọ́. Nígbà kan, ọmọbìnrin mi àgbà darí wálé láti ilé ẹ̀kọ́, tí ó ń sunkún pé òun kò ní lọ sí ilé ẹ̀kọ́ mọ́, nítorí pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé mo jẹ́ yakuza kan, mo sì fínra. Ó ṣeé ṣe fún mi láti ṣàlàyé ọ̀ràn náà fún àwọn ọmọbìnrin mi méjèèjì, wọ́n sì wá lóye ipò náà. Mo ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ náà tí ilẹ̀ ayé yóò jẹ́ párádísè kan, tí ẹran ara mi yóò sì “jà yọ̀yọ̀ ju ti ọmọ kékeré.” Nígbà náà, ara tí mo fín àti àwọn ìránnilétí 20 ọdún tí mo fi gbé ìgbésí ayé yakuza yóò di nǹkan àtijọ́. (Jóòbù 33:25; Ìṣípayá 21:4)—Bí Yasuo Kataoka ṣe sọ ọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Mo ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ náà tí a óò nu àwọn ara tí mo fín kúrò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba pẹ̀lú ìdílé mi