ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 3/8 ojú ìwé 9-10
  • Ayé kan Láìsí Ìwà Ọ̀daràn—Báwo?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayé kan Láìsí Ìwà Ọ̀daràn—Báwo?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkúrò Nínú Àjọ Ọ̀daràn
  • Jàjàbọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀mí Ayé
  • Èé Ṣe Tí Ìwà Ọ̀daràn Tí Ẹgbẹ́ Ń Ṣètò Fi Ń Gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀?
    Jí!—1997
  • Bí Ìwà Ọ̀daràn Tí Ẹgbẹ́ Ń ṣètò Ṣe Ń nípa Lórí Rẹ
    Jí!—1997
  • Bíbọ́ Lọ́wọ́ Ìwà Ọ̀daràn Tí Ẹgbẹ́ Ń Ṣètò “Yakuza Kan Ni Mí Tẹ́lẹ̀”
    Jí!—1997
  • Ìgbà Kan Tí Ìwà Ọ̀daràn Kò Sí
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 3/8 ojú ìwé 9-10

Ayé kan Láìsí Ìwà Ọ̀daràn—Báwo?

GBÍGBÓGUN ti ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò ń bá a lọ jákèjádò ayé. Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report polongo pé: “Ìgbógunti Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn ti tẹ̀ síwájú lọ́nà tó lápẹẹrẹ láàárín àkókò kúkúrú, ní pàtàkì, nítorí òfin kan, Òfin Àwọn Àjọ Apurọ́gbowó àti Àwọn Tí Àwọn Alujìbìtì-Gbowó Ń Tì Lẹ́yìn, tàbí RICO.” Ó fàyè gba dídá àwọn àjọ ọ̀daràn lẹ́bi lórí ìpìlẹ̀ oríṣi ọ̀nà ìpurọ́gbowó kan, kì í ṣe lórí ìpìlẹ̀ kìkì ìwà jìbìtì kọ̀ọ̀kan. Èyí pa pọ̀ pẹ̀lú ìsọfúnni tí a ń rí gbà nípa yíyọ́kẹ́lẹ́ tẹ́tí sí ìjíròrò orí tẹlifóònù àti láti ọwọ́ àwọn afinisùn, tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà àjọ ìpàǹpá, tí wọ́n ń wá ìjìyà tí ó rọjú, ti kó ipa pàtàkì nínú gbígbógun ti Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn ní United States.

Ní Ítálì pẹ̀lú, àwọn aláṣẹ ń gbógun ti àwọn àjọ ìpàǹpá. Ní àwọn àgbègbè bíi Sísílì, Sardinia, àti Calabria, níbi tí ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò ti lágbára gan-an, wọ́n ti kó àwọn jagunjagun lọ síbẹ̀ láti máa lọ máa bọ̀ ní àwọn ilé ìjọba àti àwọn àdúgbò pàtàkìpàtàkì, láti dènà ìgbéjàkò láti ọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ńbà àjọ ọ̀daràn. Ìjọba ń wo èyí bí ogun abẹ́lé kan. Ítálì ń ṣe àṣeyọrí mélòó kan, bí ó ti rí àwọn gbajúmọ̀ olókìkí burúkú, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn àjọ ìpàǹpá ọ̀daràn, kó sí àtìmọ́lé, tí ó sì fẹ̀sùn kan ẹnì kan tí ó jẹ́ olórí ìjọba nígbà kan rí pé ó bá Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn ṣe.

Ní Japan, ìjọba gbógun ti yakuza nígbà tí ó ṣe Òfin Ìgbógunti Ìwà Ọ̀daràn Tí Ẹgbẹ́ Ń Ṣètò ní March 1, 1992. Lábẹ́ òfin yìí, bí a bá ti ka ẹgbẹ́ àjọ ìpàǹpá kan sí bẹ́ẹ̀, òfin dè é láti má ṣe hùwà ipá 11, títí kan bíbéèrè fún owó ìmẹ́numọ́, kíkópa nínú pípurọ́gbowó pé wọ́n jẹ́ àjọ aláàbò, àti dídá sí ọ̀ràn ìpẹ̀tùsíjà tí wọn á gbowó lé lórí. Nípa rírí sí i pé òfin yìí gbéṣẹ́, ète ìjọba ni láti bẹ́gi dínà gbogbo owó tí ń wọlé fún àwọn akọluni. Òfin náà ti gbógun ti àwọn àjọ ọ̀daràn lọ́nà líle koko. Àwọn àwùjọ kan ti tú ká, olórí ìwà ọ̀daràn kan sì ti para rẹ̀—ní kedere, nítorí ọwọ́ èle tí a fi mú ìgbéró òfin náà.

Láìṣe àníàní, àwọn ìjọba àti àwọn agbófinró ń gbógun kíkankíkan ti ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò. Síbẹ̀, nígbà tí ìwé agbéròyìnjáde Mainichi Daily News ń ròyìn nípa ìpàdé àpérò kan tí àwọn adájọ́ àti lọ́gàálọ́gàá ọlọ́pàá láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé ṣe ní 1994, ó wí pé: “Ó ṣe kedere pé ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò ń lágbára sí i, ó sì ń lọ́lá sí i ní gbogbo apá ilẹ̀ ayé, ó sì ń pa iye tí ó tó tírílíọ̀nù kan dọ́là lọ́dọọdún.” Ó bani nínú jẹ́ pé, ó ní ibi tí ìsapá ẹ̀dá ènìyàn láti fòpin sí àjọ ìpàǹpá ọ̀daràn lórí ilẹ̀ ayé mọ. Ìdí kan tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé, nínú ọ̀pọ̀ ọ̀ràn, ìdájọ́ kì í yá kánkán, kò sì dáni lójú. Ọ̀pọ̀ ènìyàn rí i pé, òfin sábà máa ń gbe ọ̀daràn náà, kì í gbe ẹni tí ó pa lára. Ní nǹkan bí 3,000 ọdún sẹ́yìn, Bíbélì sọ pé: “Nítorí tí a kò mú ìdájọ́ ṣẹ kánkán sí iṣẹ́ búburú, nítorí náà, àyà àwọn ọmọ ènìyàn múra pàápàá láti hùwà ibi.”—Oníwàásù 8:11.

Kíkúrò Nínú Àjọ Ọ̀daràn

Ní àfikún sí títi ìta gbógun ti ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò, àwọn ìjọba tún ti gbìyànjú láti ran àwọn tí ń bẹ nínú àjọ ìpàǹpá ọ̀daràn lọ́wọ́ láti jáde. Irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò rọrùn. Ní ìbámu pẹ̀lú òwe àtijọ́ náà pé, “ọ̀nà kan ṣoṣo láti fi Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn sílẹ̀ ń bẹ nínú pósí.” Láti kúrò nínú ẹgbẹ́ yakuza kan, ọmọ ẹgbẹ́ ọ̀daràn náà yóò san iye owó gọbọi kan, tàbí kí wọ́n gé ìka ọmọńdinrín rẹ̀ lódindi tàbí láàbọ̀. Láti fi kún ẹ̀rù tí ó rọ̀ mọ́ kíkúrò nínú ẹgbẹ́ àwọn ẹlẹ́gírí náà, ọmọ ẹgbẹ́ àjọ ìpàǹpá ọ̀daràn látijọ́ náà gbọ́dọ̀ kojú òtítọ́ gidi tí gbígbé ìgbésí ayé rere lọ́nà ẹ̀tọ́ ní nínú. Nígbà púpọ̀ ni wọn kò ní tẹ́wọ́ gba ìwé ìwáṣẹ́ rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àkànṣe tẹlifóònù àkànlò wà, láti ṣèrànwọ́ fún àwọn mẹ́ńbà àjọ ìpàǹpá tí ń fẹ́ kúrò lẹ́gbẹ́, ṣùgbọ́n tí ó nira fún láti rí iṣẹ́ yíyẹ.

Láti kojú pákáǹleke láti ọ̀dọ̀ ìdílé àjọ ìpàǹpá, kí ó sì kojú ẹ̀tanú ẹgbẹ́ àwùjọ, ọmọ ẹgbẹ́ ọ̀daràn kan nílò ìsúnniṣe lílágbára láti ṣíwọ́ ìgbòkègbodò ìwà ọ̀daràn rẹ̀. Kí ni ó lè sún un gbéṣẹ́? Ó lè jẹ́ ìfẹ́ fún ìdílé rẹ̀, ìfẹ́ láti gbé ìgbésí ayé alálàáfíà, tàbí ìfẹ́ ọkàn láti ṣe ohun tí ó tọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, a ṣàpèjúwe ìsúnniṣe lílágbára jù lọ dáradára nínú ìtàn Yasuo Kataoka, nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé èyí.

Yasuo Kataoka jẹ́ àpẹẹrẹ ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn tí wọ́n ti yí ìgbésí ayé wọn pa dà pátápátá. Wọ́n ti fi àwọn àkópọ̀ ìwà tuntun “tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin” rọ́pò àwọn àkópọ̀ ìwà bí ẹranko tí wọ́n ti ń fi hàn tẹ́lẹ̀. (Éfésù 4:24) Ní báyìí, àwọn ènìyàn tí wọ́n ti jẹ́ oníwà ìkookò tẹ́lẹ̀ ń gbé lálàáfíà láàárín àwọn ènìyàn onínú tútù, ẹni bí àgùntàn, wọ́n sì tilẹ̀ tún ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́!—Aísáyà 11:6.

Jàjàbọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀mí Ayé

Bí a ṣe mẹ́nu bà á nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, kì í ṣe gbogbo àjọ ìpàǹpá ọ̀daràn nìkan ló wà lábẹ́ agbára àìrí ti Sátánì Èṣù, ṣùgbọ́n gbogbo ayé ló wà níbẹ̀. Àwọn ènìyàn kò tilẹ̀ mọ̀, ṣùgbọ́n, Sátánì ti ṣètò gbogbo ayé láti mú ìwà ọ̀daràn rẹ̀ ṣẹ. Lọ́nà kan náà tí àwọn àjọ ìpàǹpá ọ̀daràn gbà ń pèsè ọlà àti ìgbékalẹ̀ ìdílé aláfijọ ni òun náà ń gbà kó ipa ọ̀gá onínúure kan nípa fífún àwọn ènìyàn ní ọrọ̀, afẹ́, àti ìmọ̀lára ìṣọ̀kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, o lè má mọ̀, àwọn ọgbọ́n búburú rẹ̀ lè ti tàn ọ́ jẹ. (Róòmù 1:28-32) Bíbélì sọ fún wa pé, “ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 4:4) Kò ṣàǹfààní láti ní àjọṣe pẹ̀lú ayé tí ó wà lábẹ́ agbára ìdarí Sátánì yí. Ẹlẹ́dàá àgbáyé ní ẹgbẹ́ ogun àwọn áńgẹ́lì kan lábẹ́ Jésù Kristi, tí wọ́n ti múra tán láti gbé Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ dè, kí a lè fọ ilẹ̀ ayé mọ́ lọ́wọ́ ipá búburú tí wọ́n ní.—Ìṣípayá 11:18; 16:14, 16; 20:1-3.

Nígbà náà, báwo ni o ṣe lè jáde kúrò lábẹ́ ipá ayé Sátánì? Kì í ṣe nípa gbígbé ìgbésí ayé àṣo, ṣùgbọ́n nípa jíjàjàbọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀nà ìhùwàsí àti ọ̀nà ìrònú tó gbòde kan nínú ayé òde òní. Láti ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò ní láti gbógun ti àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ìdẹ́rùbani tí Sátánì ń lò, kí o sì dúró tiiri lòdì sí àwọn ohun ìṣírí tí ó ń fún àwọn ènìyàn, kí wọ́n má baà bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. (Éfésù 6:11, 12) Èyí yóò mú kí o fi àwọn nǹkan kan rúbọ, ṣùgbọ́n o lè jàjàbọ́ lọ́nà kan náà tí àwọn mìíràn ti gbà ṣe bẹ́ẹ̀, bí o bá pinnu rẹ̀, tí o sì gba àǹfààní tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi fúnni fúnra rẹ.

Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé fífọ̀ tí Ọlọ́run yóò fọ ayé onírúkèrúdò yí mọ́ lọ́wọ́ ìwà ọ̀daràn? Bíbélì wí pé: “Irú ọmọ àwọn ènìyàn búburú ni a óò ké kúrò,” ó sì ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.” (Orin Dáfídì 37:28, 29) Nígbà náà, kì yóò sí ìdí láti máa fòyà nítorí àwọn tí wọ́n ní ànímọ́ ẹranko, nítorí tí “ìmọ̀ Olúwa,” tí yóò kún inú ayé, yóò ti yí wọn pa dà.—Aísáyà 11:9; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 34:28.

Lónìí, irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ ti di òtítọ́ gidi, gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìgbésí ayé ẹnì kan tí ó jẹ́ mẹ́ńbà yakuza tẹ́lẹ̀ rí ní Japan ṣe fi hàn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, gbogbo ènìyàn yóò jìfà iṣẹ́ ọwọ́ wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́